Bí ó ti jé̟ pé s̟ís̟e àkíyèsí iyì tó jé̟ àbímó̟ fún è̟dá àti ìdó̟gba è̟tó̟ t̟̟̟̟í kò s̟eé mú kúrò tí è̟dá kò̟ò̟kan ní, ni òkúta ìpìlè̟ fún òmìnira, ìdájó̟ òdodo àti àlàáfíà lágbàáyé.
Ìkéde Akáríayé fún àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Universal Declaration of Human Rights | |
Eleanor Roosevelt with the English version of the Universal Declaration of Human Rights. | |
Created | 1948 |
Ratified | 10 December 1948 |
Location | Palais de Chaillot, Paris |
Authors | John Peters Humphrey (Canada), René Cassin (France), P. C. Chang (China), Charles Malik (Lebanon), Eleanor Roosevelt (United States), among others |
Purpose | Human rights |
Bí ó ti jé̟ pé àìka àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn sí àti ìké̟gàn àwo̟n è̟tó̟ wò̟nyí ti s̟e okùnfà fún àwo̟n ìwà búburú kan, tó mú è̟rí-o̟kàn è̟dá gbo̟gbé̟, tó sì jé̟ pé ìbè̟rè̟ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwo̟n ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrò̟ síso̟ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wó̟n gbó̟, òmìnira ló̟wó̟ è̟rù àti òmìnira ló̟wó̟ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lo̟ ló̟kàn àwo̟n o̟mo̟-èniyàn,
Bí ó ti jé̟̟ pé ó s̟e pàtàkì kí a dáàbò bo àwo̟n è̟tó o̟mo̟nìyàn lábé̟ òfin, bí a kò bá fé̟ ti àwo̟n ènìyàn láti ko̟jú ìjà sí ìjo̟ba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ò̟nà àbáyo̟ mìíràn fún wo̟n láti bèèrè è̟tó̟ wo̟n,
Bí ó ti jé̟ pé ó s̟e pàtàkì kí ìdàgbàsókè ìbás̟epò̟ ti ò̟ré̟-sí-ò̟ré̟ wà láàrin àwo̟n orílè̟-èdè,
Bí ó ti jé̟ pé gbogbo o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé tún ti te̟nu mó̟ ìpinnu tí wó̟n ti s̟e té̟lè̟ nínú ìwé àdéhùn wo̟n, pé àwo̟n ní ìgbàgbó̟ nínú è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí, ìgbàgbó̟ nínú iyì àti è̟ye̟ è̟dá ènìyàn, àti ìgbàgbó̟ nínú ìdó̟gba è̟tó̟ láàrin o̟kùnrin àti obìnrin, tó sì jé̟ pé wó̟n tún ti pinnu láti s̟e ìgbéláruge̟ ìtè̟síwájú àwùjo̟ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé-ayé rere è̟dá ti lè gbòòrò sí i,
Bí ó ti jé̟ pé àwo̟n o̟mo̟ e̟gbé̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé ti jé̟jè̟é̟ láti fo̟wó̟s̟owó̟ pò̟ pè̟lú Àjo̟ náà, kí won lè jo̟ s̟e às̟eyege nípa àmús̟e̟ àwo̟n è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn àti òmìnira è̟dá tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí àti láti rí i pé à ń bò̟wò̟ fún àwo̟n è̟tó̟ náà káríayé,
Bí ó ti jé̟ pé àfi tí àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ní àmús̟e̟ è̟jé̟ yìí ní kíkún,
Ní báyìí,
Àpapò̟̟ ìgbìmò̟ Àjo̟-ìsò̟kan orílè̟-èdè àgbáyé s̟e ìkéde káríayé ti è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, gé̟gé̟ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo è̟dá àti orílè̟-èdè jo̟ ń lépa ló̟nà tó jé̟ pé e̟nì kò̟ò̟kan àti è̟ka kò̟ò̟kan láwùjo̟ yóò fi ìkéde yìí só̟kàn, tí wo̟n yóò sì rí i pé àwo̟n lo ètò-ìkó̟ni àti ètò-è̟kó̟ láti s̟e ìgbéláruge̟ ìbò̟wò̟ fún è̟tó̟ àti òmìnira wò̟nyí. Bákan náà, a gbo̟dò̟ rí àwo̟n ìgbésè̟ tí ó lè mú ìlo̟síwájú bá orílè̟-èdè kan s̟os̟o tàbí àwo̟n orílè̟-èdè sí ara wo̟n, kí a sì rí i pé a fi ò̟wò̟ tó jo̟jú wo̟ àwo̟n òfin wò̟nyí, kí àmúlò wo̟n sì jé̟ káríayé láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè tó jé̟ o̟mo̟ Àjo̟-ìsò̟kan àgbáyé fúnra wo̟n àti láàrin àwo̟n ènìyàn orílè̟-èdè mìíràn tó wà lábé̟ às̟e̟ wo̟n.
Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti è̟tó̟ kò̟ò̟kan sì dó̟gba. Wó̟n ní è̟bùn ti làákàyè àti ti è̟rí-o̟kàn, ó sì ye̟ kí wo̟n ó máa hùwà sí ara wo̟n gé̟gé̟ bí o̟mo̟ ìyá.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní àǹfàní sí gbogbo è̟tó̟ àti òmìnira tí a ti gbé kalè̟ nínú ìkéde yìí láìfi ti ò̟rò̟ ìyàtò̟ è̟yà kankan s̟e; ìyàtò̟ bí i ti è̟yà ènìyàn, àwò̟̟̟, ako̟-n̅-bábo, èdè, è̟sìn, ètò ìs̟èlú tàbí ìyàtò̟ nípa èrò e̟ni, orílè̟-èdè e̟ni, orírun e̟ni, ohun ìní e̟ni, ìbí e̟ni tàbí ìyàtò̟̟ mìíràn yòówù kó jé̟. Síwájú sí i, a kò gbo̟dò̟ ya e̟nìké̟ni só̟tò̟ nítorí irú ìjo̟ba orílè̟-èdè rè̟ ní àwùjo̟ àwo̟n orílè̟-èdè tàbí nítorí ètò-ìs̟èlú tàbí ètò-ìdájó̟ orílè̟-èdè rè̟; orílè̟-èdè náà ìbáà wà ní òmìnira tàbí kí ó wà lábé̟ ìs̟àkóso ilè̟ mìíràn, wo̟n ìbáà má dàá ìjo̟ba ara wo̟n s̟e tàbí kí wó̟n wà lábé̟ ìkáni-lápá-kò yòówù tí ìbáà fé̟ dí òmìnira wo̟n ló̟wó̟ gé̟gé̟ bí orílè̟-èdè.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ láti wà láàyè, è̟tó̟ sí òmìnira àti è̟tó̟ sí ààbò ara rè̟.
A kò gbo̟dò̟ mú e̟niké̟ni ní e̟rú tàbí kí a mú un sìn; e̟rú níní àti ò wò e̟rú ni a gbo̟dò̟ fi òfin dè ní gbogbo ò̟nà.
A kò gbo̟dò̟ dá e̟nì ké̟ni lóró tàbí kí a lò ó ní ìlò ìkà tí kò ye̟ o̟mo̟ ènìyàn tàbí ìlò tó lè tàbùkù è̟dá ènìyàn.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a kà á sí gé̟gé̟ bí ènìyàn lábé̟ òfin ní ibi gbogbo.
Gbogbo ènìyàn ló dó̟gba lábé̟ òfin. Wó̟n sì ní è̟tó̟ sí àà bò lábé̟ òfin láìsí ìyàsó̟tò̟ kankan. Gbogbo ènìyàn ló ní è̟tó̟ sí ààbò tó dó̟gba kúrò ló̟wó̟ ìyàsó̟tò̟ yòówù tí ìbáà lòdì sí ìkéde yìí àti è̟tó̟ kúrò ló̟wó̟ gbogbo ohun tó bá lè ti ènìyàn láti s̟e irú ìyàsó̟tò̟ bé̟è̟.
E̟nì kò̟ò̟kan lórílè̟-èdè, ló ní è̟tó̟ sí àtúns̟e tó jo̟jú ní ilé-e̟jó̟ fún ìwà tó lòdì sí è̟tó̟ o̟mo̟nìyàn, tó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí gé̟gé̟ bó s̟e wà lábé̟ òfin àti bí òfin-ìpìlè̟ s̟e là á sílè̟.
A kò gbo̟dò̟ s̟àdédé fi òfin mú ènìyàn tàbí kí a kàn gbé ènìyàn tì mó̟lé, tàbí kí a lé ènìyàn jáde ní ìlú láìnídìí.
E̟nì kò̟ò̟kan tí a bá fi è̟sùn kàn ló ní è̟tó̟ tó dó̟gba, tó sì kún, láti s̟àlàyé ara rè̟ ní gban̅gba, níwájú ilé-e̟jó̟ tí kò s̟ègbè, kí wo̟n lè s̟e ìpinnu lórí è̟tó̟ àti ojús̟e rè̟ nípa irú è̟sùn ò̟ràn dídá tí a fi kàn án.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ pé kí a má s̟àdédé s̟e àyo̟júràn sí ò̟rò̟ ìgbésí ayé rè̟, tàbí sí ò̟rò̟e̟bí rè̟ tàbí sí ò̟rò̟ ìdílé rè̟ tàbí ìwé tí a ko̟ sí i; a kò sì gbo̟dò̟ ba iyì àti orúko̟ rè̟ jé̟. E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ààbò lábé̟ òfin kúrò ló̟wó̟ irú àyo̟júràn tàbí ìbanijé̟ bé̟è̟.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟̟tó̟ sí òmìnira èrò, òmìnira è̟rí-o̟kàn àti òmìnira e̟ sìn. E̟tó̟ yìí sì gbani láàyè láti pààrò̟ e̟ sìn tàbí ìgbàgbó̟ e̟ni. Ó sì fún e̟yo̟ e̟nì kan tàbí àkójo̟pò̟ ènìyàn láàyè láti s̟e è̟sìn wo̟n àti ìgbàgbó̟ wo̟n bó s̟e je̟ mó̟ ti ìkó̟ni, ìs̟esí, ìjó̟sìn àti ìmús̟e ohun tí wó̟n gbàgbó̟ yálà ní ìkò̟kò̟ tàbí ní gban̅gba.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí òmì nira láti ní ìmò̟ràn tí ó wù ú, kí ó sì so̟ irú ìmò̟ràn bé̟è̟ jáde; è̟tó̟yìí gbani láàyè láti ní ìmò̟ràn yòówù láìsí àtakò láti ò̟dò̟ e̟nìké̟ni láti wádìí ò̟rò̟, láti gba ìmò̟ràn ló̟dò̟ e̟lòmíràn tàbí láti gbani níyànjú ló̟nàkó̟nà láìka ààlà orílè̟-èdè kankan kún.
E̟nì kò̟ò̟kan gé̟gé̟̟ bí è̟yà nínú àwùjo̟ ló ní è̟tó̟ sí ìdáàbò bò láti o̟wó̟ ìjo̟ba àti láti jé̟ àn fà ní àwo̟n è̟tó̟ tí ó bá o̟rò̟-ajé, ìwà láwùjo̟ àti às̟à àbínibí mu; àwo̟n è̟tó̟ tí ó jé̟ kò-s̟eé-má-nìí fún iyì àti ìdàgbàsókè è̟dá ènìyàn, nípa akitiyan nínú orílè̟-èdè àti ìfo̟wó̟s̟owó̟ pò̟ láàrin àwo̟n orílè̟-èdè ní ìbámu pè̟lú ètò àti ohun àlùmó̟nì orílè̟-èdè kò̟ò̟kan.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ìsinmi àti fàájì pè̟lú àkókò tí kò pò̟ jù lé̟nu is̟é̟ àti àsìkò ìsinmi lé̟nu is̟é̟ láti ìgbà dé ìgbà tí a ó sanwó fún.
E̟nì kò̟ò̟kan ló ní è̟tó̟ sí ètò nínú àwùjo̟ rè̟ àti ní gbogbo àwùjo̟ àgbáyé níbi tí àwo̟n è̟tó̟ òmìnira tí a ti gbé kalè̟ nínú ìkéde yìí yóò ti jé̟ mímús̟e̟.
A kò gbọdọ̀ túmò̟ ohunkóhun nínú ìkéde yìí gé̟gé̟ bí ohun tí ó fún orílè̟-èdè kan tàbí àkójo̟pò̟ àwo̟n ènìyàn kan tàbí e̟nìké̟ni ní è̟tó̟ láti s̟e ohunkóhun tí yóò mú ìparun bá èyíkéyìí nínú àwo̟n è̟tó̟ àti òmìnira tí a kéde yìí.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ìkéde Akáríayé fún àwọn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.