Ọ̀rọ̀-orúkọ ní èdè Yorùbá
Ọ̀rọ̀-orúkọ ní ọ̀rọ̀kọrọ̀ tí a lè lò gẹ́gẹ́ bí i olùwà fún ọ̀rọ̀ ìṣe, àbọ̀ fún ọ̀rọ̀ ìṣe àti àbọ̀ fún ọ̀rọ̀ atọ́kùn.
Ọ̀rọ̀-orúkọ ni ọ̀rọ̀kọrọ̀ tí ó lè dúró gẹ́gẹ́ bí i ìdánimọ̀ fún enìyàn, ẹranko, ibìkan, tàbí nǹkan.
Bí àpẹẹrẹ:
Ènìyàn: Àánú, Ọmọladé, Pẹ̀lúmi, Ṣeun, abbl.
Ẹranko: ajá, olońgbò, ẹkùn, àmọ̀tẹ́kùn, ejò, abbl.
Ibìkan: Ìbàdàn, Ejìgbò, Oshòdì,Ìkòròdú, Ìdúmọ̀tà, abbl.
Nǹkan: abọ́, ilẹ̀kẹ̀, ẹní, àwo, bàtà, aṣọ, ìgò, abbl.
A tún le dá ọ̀rọ̀-orúkọ mọ̀ nípa ipò wọn nínú gbólóhùn, nínú àwọn gbólóhùn alábọ́dé Yorùbá, ọ̀rọ̀-orúkọ ló sáàbà máa ń jẹ́ olùwà àti àbọ̀.
Bi àpẹẹrẹ:
P.s: Nígbà míìràn, a máa ń bá àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ mìíràn pàdé ní ipò olùwà àti àbọ̀ nínú àwọn gbólóhùn alábọ́dé, tí wọn kì í bá ṣe àwọn ọ̀rọ̀ arópò-orúkọ (bí i mi, a, o, ẹ, ó, wọ́n abbl.) wọn ma jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ afarajorúkọ ( bí i èmi, àwa, ìwọ, ẹ̀yin, òun,àwọn abbl.).
Tí a bá ronú sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ àti ọ̀rọ̀ afarajorúkọ máa tóka sí a ma ri pé ọ̀rọ̀-orúkọ ni wọ́n.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ọrọ orúkọ, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.