Àsà Ilà Kíkọ Ní Ilé Yorùbá

    ÀSÀ ILÀ  KÍKỌ NÍ ILÈ YORÙBÁ

Ilà kíkọ jẹ́ n kan pàtàkì tí àwọn ọmọ Yorùbá fi ń dára wón mò ní ayé ojó. Òwe Yorùbá kan so pe títa ríro ni a n kò ilà, Sùgbọ́n bí o bá jiná tán, a di oge.

Ní ìgbà àtijọ́, àsà ilà kíkọ jẹ ohun àmúyangàn àti ara oge ṣíṣe fún tọkùnrin-tobìnrin ní ilẹ̀ Yorùbá.

Bí a bá wo ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ orílè-èdè Nàìjíríà, a o rí oríṣiríṣi ilà lójú wón. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ní kò mò ìdí re tí a fii kò ilà.

Àwọn kan gbà wí pé ẹrú ni wón kọ́kọ́ kọ nílà láyé ọjọun fún ìjìyà ẹ̀sẹ̀ ẹrú náà. Sùgbọ́n nìgbà tó jiná tán lo di wí pé, ilà ojú re n wu gbogbo ènìyàn.

Kíni Ìdí Re Tí A Fi Kò Ilà?

Nìgbà láéláé, ogun àti ọ̀tẹ̀ po ní orílè-ẹ̀dẹ̀ Nàìjíríà.

Lákọ́kọ́ yíì ní ọmọ n sọnù láírò-tẹ́lẹ̀. Àwọn alágbára ń ko àwọn ọmọ eni tí ko ní agbára bí tí wón ta. Bí n wón tí n ko ọmọ won bẹẹ ní n wón n ko aya wón paapaa. Bẹẹni ọpọ géndé ní i sọnù, tí a n fi wón se àwáàtí láwùjọ.

Bí a tí n kò wón la n tàwọn lẹ́rú fún àwọn orílẹ̀-èdè míiràn. Bí àwọn tí a tà lẹ́rú wònyí, yálà láti ìdílé kan náà tàbí ìlú kan náà bá pàdé, wón ko ní mò ara wón rara. Sùgbọ́n àwọn àgbàlagbà ronú pe o ye kí kíni kan bí àmì wà, èyí tí ń wón yóò fi máà mọ ara wón.


Tí wón o sí le so lẹ́sẹ̀kan náà nípa ìlú ti ènìyàn kan tí wà ní kété tí àbá rii. Ọgbọ́n ilà kíkọ yi kii se tí gbogbo orílẹ̀-èdè yíì ní láti ìbèrè bikose ohun tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè yíì jogún láti Ìwò-Òrùn níbi tí àsà náà tí kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀.

Ìdí kejì tí a fi ko ilà

Ìdí ní pé bóyá àwọn ènìyàn Ìwò-òrùn níbi tí àsà yíì tí bẹ̀rẹ̀ rò pé yóò bùkún ẹwà ara wón nípa ṣíṣe béè.

Bí a bá wo jù ẹ̀lòmíràn nínú àwọn Okùnrin tàbí àwọn obìnrin tí o ko ilà, a o rí pé ilà náà dára púpò lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wón. Dájúdájú, àsà láti bu sí ẹwà ara ní irú àwọn béè ka ilà kíkọ sí. “Bí a kò bá torí isu jepo, à o torí ẹpo jẹ isu”. Bí a bá wo fínnífínní, a o ri pe ila yi yátó sí ara wón láti agbẹ̀gbẹ̀ sí agbẹ̀gbẹ̀ tàbí ìlú sí ìlú níbòmíràn.

Àwon Ọ̀yọ́ nii ko oríṣiríṣi Àbàjà, Pẹ́lẹ́ àti Túré. Nwon tun n ko Àbàjà mẹ́ta-mẹ́ta, tàbí Gọ̀mbọ̀, Kẹ̀kẹ̀ àti Gọ̀mbọ̀ papọ̀. Àwọn Èkìtì a bù mẹ́ta-mẹ́ta tí o gbooro, tabi eyo kan soso ti o gbooro, tàbí mẹ́ta òró lórí mẹ́ta ibu ti o gbooro. Àwọn Ẹ̀gbá ní n ko mẹ́ta-mẹ́ta tí kò gùn ti ko si gbooro. Àwọn Ìjèbú a máà kò mẹ́ta-mẹ́ta tàbí mẹ́ta lókè, mẹ́ta ní ìsàlè re.

Àwọn Òwú náà mbu Àbàjà, ńwón si mbu Kẹ̀kẹ́ pẹ̀lú. Púpò nínú àwọn Ifẹ̀ kii kọlà, sùgbón àwọn míràn nko mẹ́ta-mẹ́ta nìgbà míràn. Àwọn Ìjẹ̀ṣà ńkọ mẹ́fà. Òndó ńko mẹ́ta-mẹ́ta. Àwọn Ìyágbà ńkọ mẹ́ta-mẹ́ta ti o fẹ ẹ papọ̀ l’eba ẹnu wón.
Ogunlọ́gọ̀ ilè la tí pa àsà yi rẹ, sùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé wa tí ko fẹ fi àsà yíì sílè rara. Lára àwọn àpẹrẹ irú àwọn ilà ti àwọn Yorùbá má n ko nìwọ̀nyí láti fi dáwalójú pẹ́ àwọn ilà wònyí yàtọ̀ si ara wón láti ìlú àti ilè sí ara wón.

ÀBÀJÀ

Èyí ní àwọn ilà mẹta tí a fa níbu lórí ara won tàbí mẹ́fà tí a tó ní mẹ́ta-mẹ́ta níbu bakan náà.

ÀBÀJÀ MẸ́RIN

Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ẹlẹ́yí àti èyí tó ea lókè yi ní pe. A bu ilà tòkè ní mẹ́ta-mẹ́ta, sùgbón à bù ẹlẹ́yí ní mẹ́rin-mẹ́rin.

ÀBÀJÀ ALÁGBẸ́LẸ́

Irú àbàjà eleyi ní a má n bu si ojú ènìyàn tí a sí tún gbẹ́ mẹ́ta òró míràn le lórí.

PẸ́LẸ́

Ilà mẹ́ta tí a fà sẹ̀rẹ̀kẹ̀ tí o dúró looro. O máà nye àwọn tí o bá bu ilà béè. A sí máà npe àwọn ènìyàn béè ní “pẹ́lẹ́yẹjì” fún ẹwà tíí fún wón.

TÚRẸ

Ilà mẹ́ta kẹ́kẹ̀ẹ̀kẹ́ looro àti mẹ́ta míràn tí o gùn jù mẹ́ta ìsáájú lo.

KẸ́KẸ́ TÀBÍ GỌ̀MBỌ̀

Àwọn Ilà tí o gùn ti a fa láti orí wà ti o si te woroko lógángán aarin ojú àti etí sí ìsàlè ẹ̀ẹ́kẹ́.

Gbogbo àwọn ilà ojú wònyí láti ẹ̀kíní (1) títí dẹ́ ẹ̀kẹfà (6) lo wọ́pọ̀ láàrin àwọn ọmọ Ọ̀yọ́, Ìbàdàn, Ogbomoso, Ẹdẹ, Iwo àti Òsogbo.

Àwọn ilà míiràn tún wa tí o fi díèdíè yàtọ̀ sí àwọn tí o wá lókè wonyi.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wón lo dàbí àbàjà, kẹ́kẹ́, Pẹ́lẹ́ sùgbón ńwón ko gbọọrọ tó àbàjà, keke àti Pẹ́lẹ́ àwọn Ọ̀yọ́.

Àpẹẹrẹ àwọn ilà béè níwònyí:

ÀBÀJÀ OLÓWU

Ilà mẹ́ta òró àti mẹ́ta ìbù ní ìsàlè wón.

KẸ́KẸ́ OLÓWU

Ẹlẹ́yí yàtọ̀ si kẹ́kẹ́ tí àkókó. Siso ni keke olówu, bíbù ní Kẹ́kẹ́ Ọ̀yọ́.

PẸ́LẸ́ IFẸ̀

Ilà mẹ́ta òró

ILÀ ÒNDÓ

Ẹyọ̀kan soso tí o gùn tí o si jinlẹ̀ ni

PẸ́LẸ́ ÌJÈBÚ

Ilà mẹ́ta tí o gùn díè ni

ÀBÀJÀ Ẹ̀GBÁ

Mẹ́ta òró àti mẹ́ta ìbu, tí a ko lórí ara wón.

PẸ́LẸ́ ÌJẸ̀ṢÀ

Mẹ́ta looro

ÀBÀJÀ ÌJẸ̀ṢÀ

Mérin ní ìbu.

PẸ́LẸ́ ÀTI ÀBÀJÀ ÈKÌTÌ

Àwọn wònyí yàtọ̀ sí Pẹ́lẹ́ àti àbàjà ti a ti sàlàyé sóke nítorí pé nwon gbọọrọ púpò jù tí ìsájú lo.



Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

ÀrokòInternet Relay ChatInternetẸ̀lẹ́ktrọ́nùMyanmarIsiaka Adetunji AdelekeFísíksìSeattleOṣù KẹtaWeb browserÀrún èrànkòrónà ọdún 2019Julie ChristieOrílẹ̀ èdè AmericaZÀwọn Òpó Márùún ÌmàleVladimir NabokovẸ̀bùn Nobel nínú Lítíréṣọ̀Nigerian People's PartyAtlantaWolframuLinda IkejiKàsàkstánMons pubisEritreaAkanlo-edeÌran YorùbáAfghanístànÈdè Gẹ̀ẹ́sìSheik Muyideen Àjàní BelloVictor Thompson (olórin)MediaWikiWiki CommonsÀṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ YorùbáEl SalfadorAlẹksándrọ̀s OlókìkíÀríwá Amẹ́ríkàÀdírẹ́ẹ̀sì IPJapanISO 8601OlóṣèlúRio de JaneiroLudwig van BeethovenÀjẹsára Bacillus Calmette–GuérinWYul Edochie22 DecemberFrancis BaconÌpínlẹ̀ ÒgùnẸ̀sìnMathimátíkìAustrálíàDomain Name SystemIndonésíàMurtala MuhammadỌ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá)Pópù Gregory 16kKánádàYunifásítì HarvardKọ̀mpútàIÌṣeọ̀rọ̀àwùjọ🡆 More