Àjàkáyé-Àrùn

Àjàkáyé-àrùn (pandemia láti inú èdè Greek tó túnmọ̀ sí gbogbo àti ènìyàn) jẹ ìbújáde àkóràn àrùn kan ti o nlọ kaa kiri orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn tí ó ju ẹyọkan lọ.

Yíyára tànkálẹ̀ àrùn laarin ọ̀pọ̀ ènìyàn ní agbegbè tàbí ẹkùn fún ìwọ̀nba ìgbà diẹ ni wọ́n npe ni "àjàkálẹ̀-àrùn" (epidemic). Ìtànkálẹ̀ àrùn tí ó jẹ́ wípé o ní iye ìwọ̀nba àwọn ènìyàn tí wọ́n ko o ni wọ́n ń pè ní "endemic" ki i se àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé. Àrùn endemic tí ó jẹ́ wípé o ní iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ko o tí kì í ṣe wípé ó tàn kaa kiri bi àjàkálẹ̀-àrùn ti o ma n ṣẹyọ ní àkókò ni a le yà sọ́tọ̀ nítorí pé àwọn àrùn bayi i ma n wáyé leekanna ni àwọn ẹkùn tí ó tóbi ní àgbáyé sùgbọ́n wọ́n ki i ràn kaa kiri àgbáyé.

Àjàkáyé-Àrùn
Àjàkálẹ̀ àrùn ní Florence, ní ọdún 1348

Àjàkáyé-Àrùn

Àjàkáyé-àrùn (pandemia láti inú èdè Greek tó túnmọ̀ sí gbogbo àti ènìyàn) jẹ ìbújáde àkóràn àrùn kan ti o nlọ kaa kiri orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn tí ó ju ẹyọkan lọ.

Àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn tí ó ń tàn kaa kiri gbogbo àgbáyé. A kò lè pe àrùn tàbì àìsàn kan ní àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé nítorí pé ó wà kaa kiri tàbí pé o n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn; àrùn yí gbọ́dọ̀ jẹ́ àkóràn. Fún àpẹrẹ, àrùn jẹjẹrẹ jẹ́ àrùn kan tí ó ń pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sùgbọ́n a kò lè pé e ní àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé nítorí pé ki i ṣe àrùn àkóràn tàbí àrùn tí ó lè ran ènìyàn.

Àwọn òṣùwọ̀n tí àjàkálẹ̀-àrùn fi ma n ràn (Nibayi àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé) ma n wá sókè wá sílẹ̀ tí a bá gbe e sí orí àwọ̀nyà láti fi hàn iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fi ara kó àrùn yi ní àkókò kan. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni lílọ sókè wá sílẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn yí ma n wáyé ní àkókò tí àjàkálẹ̀-àrùn yí ba n ràn kaa kiri. A\won àrùn àkóràn ma n sábà a tànkalẹ̀ ní ì̀pele mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú àwọ̀nyà ìsàlẹ̀ yí.

Ìpele ìkínní sẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ohun tí ó tẹ̀ yí. Tí a bá lo títànkàlẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn ẹ̀rankòrónà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, eléyì ma a jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ títànkálẹ̀ àjàkálẹ̀-àrùn yí nígbàtí wọ́n bá fi ìdí ìwọ̀nba ìsẹ̀lẹ̀ die múlẹ̀.

Ìpele kejì ohun tí ó tẹ̀ yí n sàlàyé lórí àjàkálẹ̀-àrùn "Ìpele agbègbè". Èyí ma n wáyé nígbàtí àkóràn àrùn laarin àwọn ènìyàn bá ṣe n pọ si bi àwọn ènìyàn tuntun se n kó àrùn yí.

Ìpele kẹta ohun tí ó tẹ̀ yí n ṣe àfihàn pé wọ́n ko i ti kápá ìbújáde àjàkálẹ̀-àrùn yí tàbí pé ó se é se kí àkóràn àrùn tuntun ma si rárá.

Àjàkáyé-Àrùn

Àjàkáyé-àrùn (pandemia láti inú èdè Greek tó túnmọ̀ sí gbogbo àti ènìyàn) jẹ ìbújáde àkóràn àrùn kan ti o nlọ kaa kiri orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn tí ó ju ẹyọkan lọ.

Kò lóùnkà àwọn ìgbéṣẹ̀ ni àwọn Ìpínlẹ̀ le gbe làti dínwọ́ ìbújáde àjàkálẹ̀-àrùn tòkárí-ayé kù. Ní ọdún 2005, àjọ tí ó n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization ṣẹ àgbékalẹ̀ àwọn ìlànà ètò ìlera káríayé, èyí ti i se ìlànà òfin kan ti yio ṣe ídíwọ́, ìdarí, àti ìjígìrì sí ewu ìlera gbogbo ènìyàn ti o se e se ki o tànkálẹ̀ laarin àwọn orílẹ̀-èdè. Àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization tún ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé aláfọwọ́kọ kan láti kojú àwọn àjàkálẹ̀-àrùn. Àlàyé aláfọwọ́kọ yi ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe àtẹ̀jáde rẹ ní ọdún 1999 tí wọ́n sì ṣe àtúnwò àti ìmúdójúìwọ̀n rẹ ní ọdún 2005 àti ọdún 2009. Èyí tí ó pọ̀jù lọ nínú àwọn ìlànà tí wọ́n lò láti fi kojú àjàkálẹ̀-àrùn kòrónà ni wọ́n mú jáde láti inú àwọn ìlànà ètò ìlera ti àgbáyé ti ọdún 2005 àti àwọn ìtọ́sọ́nà ìgbaradì fún àjàkálẹ̀-àrùn tí ó jẹ́ ti àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization.

Àpérò nla kan ti wáyé lórí ìlànà "T" méta (Testing, Treatment and Tracing) èyí tí ó gba àwọn orílẹ̀-èdè láàyè láti ṣe àyẹ̀wò oríṣiríṣi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kí ó tó di wípé wọ́n yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìtọ́jú. Ìlànà yí ló ní ṣe pẹ̀lú wíwá gbogbo ènìyàn tí eni tí ó ti fi ara kó àrùn yí ti se alábàpàdé pẹ̀lú kaa kiri kí wọ́n sí yà wọ́n sọ́tọ̀. Ìlànà yí jẹ́ èyí tí wọ́n mọ̀ kaa kiri nítorí àgbékalẹ̀ rẹ ti o múnádóko ní àwọn orílẹ̀-èdè bi i South Korea àti Singapore, bíòtilẹ̀jẹ́pé àwọn orílẹ̀-èdè yí ti wà ní ìmúrasìlẹ̀ tí ó dárajùlọ pẹ̀lú àwọn oríṣiríṣi ìlànà lẹ́hìn jamba tí SARS ti fa.

Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ tàbí ní kúkúrú jíjìnà sí ara ẹni jẹ́ àgbékalẹ̀ fún ìlera gbogbo ènìyàn láti mú kí àrùn àkóràn dínkù nípa ṣíṣe ìdíwọ́ fún àwọn ènìyàn láti súnmọ́ ara wọn nítorí àrùn àkóràn àti àwọn àìsàn tí ó lè ràn wọ́n. Aláṣẹ àti olùdarí, Dokita Michael J. Ryan ti àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World health Organization sọ níbi àpérò kan ní oṣù kẹta ọdún 2019 pe ìjìnnà-síra-ẹni "jẹ́ ìlànà fún ìgbà díẹ̀ láti dín ọwọ́ títànká ẹ̀rankòrónà yí kù ni sùgbọ́n ki i ṣe láti mú ìyanjú wá sí ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀rankòrónà. Lootọ ló jẹ́ wípé ìlànà yí jẹ́ ìlànà ti o na ni lówó sùgbọ́n a gbọ́dọ̀ lo o pẹ̀lú àwọn ìlànà míràn láti wá ìyanjú sí ìṣòro yi. Dokita Riyan sọ kedere pé ìjìnnà-siŕa-ẹni ko le mu àrùn yí kúrò.

Àjàkáyé-Àrùn

Àjàkáyé-àrùn (pandemia láti inú èdè Greek tó túnmọ̀ sí gbogbo àti ènìyàn) jẹ ìbújáde àkóràn àrùn kan ti o nlọ kaa kiri orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn tí ó ju ẹyọkan lọ.

HIV/AIDS

Bíòtilẹ̀jẹ́pé àjọ tí ó n rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization lo àkọlé "àjàkálẹ̀-àrùn àgbáyé" láti fi ṣe àpèjúwe HIV, àrùn yí jẹ́ àjàkálẹ̀-àrùn ti o n tẹ̀lé ìtunmọ̀ ọ̀rọ̀. Láti bí i ọdún 2018, ó tó 37.9 million àwọn éníyán tí wọ́n ti fi arakó àrùn HIV ní gbogbo àgbáyé. Àwọn ènìyàn tí ó tó 770,000 ni ó ti jẹ́ aláìsí látipasẹ̀ àrùn AIDS ní ọdún 2018. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹkùn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yí ṣẹlẹ̀ sí jù ni ìha ìsàlẹ̀ asálẹ̀ Sahara ní ilẹ̀ Africa. Ní ọdún 2018, ìfojúsùn àrùn HIV tuntun tí ó tó 61% ni ó ṣẹlẹ̀ ní ẹkùn yí.

Àwọn ẹ̀rankòrónà

Àwọn ẹ̀rankòrónà (CoV) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹbí àrùn tí ó n fa àwọn àìsàn bẹ̀rẹ̀ láti orí otútù títí tí o fí dé orí àwọn àrùn tí ó lágbára bí i Middle East Respiratory Syndroms (MERS-CoV) àti Severe Acute Respiratory Syndroms (SARS-CoV). Ẹ̀yà ẹ̀rankòrónà tuntun tí ó n jẹ́ (SARS-CoV-2) ni ó ń fa àrùn ẹ̀rankòrónà 2019 tàbí COVID-19. Diẹ nínú àwọn ẹ̀rankòrónà ni Zoonitic, èyí tí ó túnmọ̀ sí wípé wọn ma n ṣe àtagbà láàrín àwọn eranko àti àwọn ènìyàn. Àyẹ̀wò kíkún fi yé wa wípé SARS-CoV jẹ́ èyí tí ó ti ara ológbò civeti civet cats jáde wá sí ara ènìyàn, àti wípé MERS-CoV jáde wá láti ara ràkúnmí wá sí ara ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rankòrónà tí a mò ni wọ́n wa kaa kiri nínú àwọn eranko tí wọn ko i ti ràn mọ́ ẹ̀dá ènìyàn.

Ìwọn ẹ̀rankòrónà tuntun kan èyí tí ìpìlẹ̀ rẹ bẹ̀rẹ̀ ní Wuhan, ní ìgbèríko Hubei, ní orílẹ̀-èdè China, ní òpin oṣù kejìlá ọdún 2019 ti fa onírúurú ̀ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn tí atẹ́gùn n gbé kiri tí wọ́n n tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bi i àrùn ẹ̀rankòrónà 2019 (COVID-19). Gẹ́gẹ́ bi Johns Hopkins University Dashboard, o fẹ́rẹ̀ ẹ tó igba(200) àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn agbèegbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ COVID-19 ti ṣẹlẹ̀ sí, pẹ̀lú àwọn ìbújáde tí ó délédóko tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè United States, Central China, Western Europe, àti Iran. Ní ọjọ́ kọkànlà oṣù kẹta ọdún 2020, àjọ ti o n ri si ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization ṣe àpèjúwe ìtànkálẹ̀ àrùn COVID-19 gẹ́gẹ́ bi i àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé. Láti ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 2020, iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ti kó àrùn ẹ̀rankòrónà ní àgbáyé ti tó 2.63 millino, iye àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláìsí ti tó 184.249 àti iye àwọn aláìsàn tí wọ́n ti gba ìwòsàn jẹ́ 722.055.

Àjàkáyé-Àrùn

Àjàkáyé-àrùn (pandemia láti inú èdè Greek tó túnmọ̀ sí gbogbo àti ènìyàn) jẹ ìbújáde àkóràn àrùn kan ti o nlọ kaa kiri orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn tí ó ju ẹyọkan lọ.

Àrùn ibà

Àrùn ibà jẹ àrùn tí ó wà ní ibigbogbo ní ẹkùn Tropical àti Subtropical tí ó fi mọ́ àwọn apákan ní orílẹ̀-èdè America, Asia àti Africa. Ní ọdọọdún, ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ibà tí ó ma ń ṣẹlẹ̀ ma n súnmọ́ 350-500 million. Àtakò oogun jẹ́ ìṣòro ti o ń gbèrú si i nípa ìtọ́jú àrùn ibà ní orúndún kọkanlélógún (21st century) nígbàtí ó jẹ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ oogun ibà ni kò ṣiṣẹ́ mọ deede yàtọ̀ sí artemisinins.

Àrùn ibà wọ́pọ̀ ní ìgbàkan ní àwọn apá ilẹ̀ Europe àti ní Àríwá America níbití ó jẹ́ wípé kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn yí mọ bayi . Ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ wípé àrùn ibà yí lọ́wọ́ nínú ìṣubú ilẹ̀ Ọba Roomu (Roman Empire). Àrùn yí ni wọ́n mọ̀ sí "Roman fever". Plasmodium flaciparum jẹ́ ǹ kan tí ó di ìrọ́kẹ̀kẹ̀ gidi sí àwọn amúnisìn àti àwọn ènìyàn ìlú bakanna nígbàtí wọ́n ṣe àfihàn rẹ sí àárín àwọn Americas pẹ̀lú ìṣòwò ẹrú.

Àìsàn Spanish

Àìsàn Spanish (tí ó wáyé ní ọdún 1018 si ọdún 1920) jẹ́ àkóràn àrùn tí ó ran àwọn ènìyàn tí ó tó 500 million ní gbogbo àgbáyé pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó wá látọ̀nà jínjìn bi i Pacific Islands àti Arctic tí ó sì ti pà àwọn ènìyàn bi i ogún sí ọgọ́rùn ún millionu (20-200 million). Àìbíkítà sí àjàkálẹ̀ àrùn yí ṣe ikú pa púpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn arúgbó pẹ̀lú òṣùwọ̀n ìwàláàyè tí ó pọ̀ jùlọ fún àwọn tí ó wà ní àárín, sùgbọ́n àìsàn Spanish yi pa púpọ̀ nínú àwọn àgbà ọ̀dọ́. Iye ènìyàn tí àìsàn Spanish yi pa ju iye ènìyàn tí ó kú nígbà ogun àgbáyé ìkínní. Àìsàn yí pa àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ ní ọ̀sẹ̀ márùndínlọ́gbọ̀n ju àwọn ènìyàn tí àrùn AIDS pa ní ọdún márùndínlọ́gbọ̀n àkọ́kọ́. Píparapọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti ibi gbogbo tí ó súnmọ́ ara wọn nígbà ogun àgbáyé íkínní lo fa a ki ìtànkálẹ̀ àrùn yi pọ̀ nítorí àìlágbára àwọn ọmọ jagunjagun lórí àìsàn yí le jẹ o un tí ó pọ̀ nítorí áápọn, àìní ìtọ́jú, àti ìkọlù pẹ̀lú kemikali. . Ètò ìrìnnà tí ó dára si jẹ ki ó tún rọrùn fún àwọn jagunjagun, àwọn atukọ̀ àti àwọn ará ìlú tí ó ń rìnrìn àjò láti tan àrùn yí kaa kiri.

Àjàkáyé-Àrùn

Àjàkáyé-àrùn (pandemia láti inú èdè Greek tó túnmọ̀ sí gbogbo àti ènìyàn) jẹ ìbújáde àkóràn àrùn kan ti o nlọ kaa kiri orílẹ̀-èdè tàbí ẹkùn tí ó ju ẹyọkan lọ.

Òògùn apakòkòrò to n dènà àrùn

Àwọn òògùn apakòkòrò ni wọ́n ma n sábà a tọ́ka sí nígbàmíràn gẹ́gẹ́ bi i "Superbus". Ó ṣe é ṣe kí wọ́n tún kó ipa lórí i bí àwọn àrùn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ n kápá lọ́wọ́lọ́wọ́ tún ṣe n fara han. . Fún àpẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ọfee èyí tí agbára ọ̀nà ìwọ̀sàn rẹ kò ṣiṣẹ́ mọ́ jẹ́ ń kan tí ó n kan áwọn onímọ̀ nípa ètò ìlera lóminú.

O fẹ́rẹ̀ to ìdajì millionu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun tí ó jẹ́ ti Multidrug-resistant tuberculosis (MDR-TB) tí ẃn fojúsùn pé o n ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún kaa kiri . Orílẹ̀-èdè China àti ti India ni wọ́n ní òṣùwọ̀n ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ga jùlọ nípa Multoidrug-resistant TB. Àjọ ti o n ri sí ètò ìlera ní àgbáyé sọ wípé ó fẹ́rẹ̀ súnmọ́ 50 million àwọn ènìyàn ní àgbáyé tí wọ́n ti kó àrùn MDR-TB pẹ̀lú 79% àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yí tí àwọn òògùn apakòkòrò bi i mẹ́ta tàbí jù bẹẹ lọ kò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú. Ní ọdún 2005, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ MDR-TS tí ó tó 124 ni wọ́n kéde wọn ní orílẹ̀-èdè America.Extensively drug-resistant tuberculosis (XDR TB) ni wọ́n ṣe ìdánimọ̀ re ní ilẹ̀ Africa ní ọdún 2006, lẹhinna ni wọ́n ṣe àwárí rẹ pe ó wà ní ọ̀kàndínláàdọ́ta (49) orílẹ̀ èdè tí ó fi mọ́ ilẹ̀ America. Àjọ ti o n ri sí ètò ìlera ,World Health Organisation ṣe ìṣirò rẹ pé ìṣẹ̀lẹ̀ XDR-TB tí ó tó 40,000 ni ó n ṣẹlẹ̀ ní ọdún .

Fún bi i ogún ọdún sẹ́yìn, àwọn kòkòrò àrùn tí ó wọ́pọ̀ ni staphylococcus, aureus, seerratia marceseens àti Enterococcus tí ó n fa àtakò si onírúurú òògùn apakòkòrò bi i Vancomycin, àti gbogbo àwọn òògùn apakòkòrò bi i aminoglycosides àti cephalosporins. Àwọn kòkòrò tí ó n gbógun ti àwọn òògùn apakòkòrò jẹ́ ọ̀kan lára ̀awọn ǹ kan tó n fa àwọn àrùn tó ní i ṣe pẹ̀lú ìlera. Ní àfikún, àwọn àrùn ti o n gbógun ti òògùn apakòkòrò bi i methicillin-resistant staphylococcus aureus (MRSA) tí ó jẹ́ wípé wọn gbinlẹ̀ ní ǹ kan bi i ọdún mélò ó kan sẹ́yìn, ń ṣe àkóbá fún ẹni tí ó ti ní ìwòsàn tẹ́lẹ̀.

Àwọn kòkòrò ibà tí ń sọ ẹ̀jẹ̀ di omi

Ibà sẹ̀jẹ̀domi (viral hemorrhagic fever) jẹ́ àwọn àrùn ti o ma n ràn gidigidi tí wọ́n si n ṣe ikúpani. Àwọn àpẹẹrẹ ni Ebola, Lassa, Rift Valley, Marburg ati Bolivan hemorrhagic. Àwọn àrùn yí ní agbára láti pé kí wọ́n di àjàkálẹ̀-àrùn tókárí-ayé. Agbára tí àwọn àrùn yí ni láti tètè tànkálẹ̀ di àjàkálẹ́-àrùn tókárí-ayé kò pọ̀ rárá nítorípé títànkálẹ̀ wọn ma nílò ìfarakanra pẹ̀lú ẹnití ó ti ní àrùn yí tẹ́lẹ̀ sùgbọ́n ẹnití ó ní àrùn yí tẹ́lẹ̀ kò ní àkókò púpọ̀ rárá tí yíò fi jẹ́ aláìsí tàbi ki o dùbúlẹ̀ àìsàn tó lágbára. Ìwọ̀nba àkókò tó wà láàrín ẹnití ó ní àrùn yí àti ìgbàtí àmì àrùn yí ma fi ara hàn ma n fún àwọn dọ́kítà laaye láti le tètè fi ẹni bẹ ẹ pamọ́ kí wọ́n sì di i lọ́wọ́ láti ma ba a gbé àrùn yi lọ sí ibòmíràn.

Kòkòrò zika

Ìbújáde kòkòrò zika bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2005 tí ó sì n tẹ̀síwájú kíkankíkan ní gbogbo ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2016 pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ju 1.5 million lọ jákè jádò àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ju méjìlá lọ ní ìlú America. Àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization ṣe ìkìlọ̀ pé àrùn zika ní agbára láti di àjàkálẹ̀-àrùn tí yíò tàn ká gbogbo àgbáyé tí wọn kó bá tètè dènà rẹ.

Itokasi

Tags:

Àjàkáyé-Àrùn Ìtunmọ̀ àti ÌpeleÀjàkáyé-Àrùn ÌṣàkósoÀjàkáyé-Àrùn Àwọn àjàkálẹ̀-àrùn tọ́kárí-ayé tí ó n ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́Àjàkáyé-Àrùn Àkíyèsi àwọn ìbẹ́sílẹ̀Àjàkáyé-Àrùn Ìkọ́minú nípa ọjọ́ iwájú àwọn kòkòrò àrùnÀjàkáyé-ÀrùnOrílẹ̀-èdèÈnìyàn

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

H. H. AsquithẸ̀bùn NobelEugenio MontaleKuala Lumpur(5813) 1988 VLẸlẹ́ẹ̀mínFyodor DostoyevskyOba Saheed Ademola ElegushiÀmì-ìdámọ̀ kẹ́míkàKlas Pontus ArnoldsonAbubakar Tafawa BalewaOlúṣẹ́gun Ọbásanjọ́Swítsàlandì3 Mayaue27ÌnáwóAṣọ ÀdìrẹLucie ŠafářováSaint PetersburgFúnmiláyọ̀ Ransome-KútìMiles Davis22 MayÌṣíròEukaryaMinnesotaLẹ́tà Àìgbẹ̀fẹ̀Rẹ̀mí ÀlùkòỌ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá)Ọ̀rúnmìlàÀmì ọ̀pá àṣẹ ilẹ̀ ÅlandEhoroTurkeyWinston ChurchillÀwọn ọmọ Áfíríkà Amẹ́ríkàInstagramỌbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀Pópù Gregory 10kUniform Resource LocatorNikita KhrushchevOrílẹ̀-èdè Olómìnira Òṣèlú ilẹ̀ KóngòRita WilliamsÀtòjọ àwọn àjọ̀dún12 DecemberUzbekistanKashim ShettimaRheniumSan FranciscoOrúkọ ìdíléPópù Gregory 7kAssamOnímọ̀ ìsirò201031 JulyAbdullahi Ibrahim (ológun)ẸrankoỌdúnPópù Benedict 6kOlódùmarèRáràRichard WagnerÀṣà Ìsọmọlórúkọ Nílẹ̀ YorùbáIlà kíkọ nílẹ̀ YorùbáOregonFIFA24 JuneTsẹ́kì Olómìnira950 Ahrensa🡆 More