Ọ̀rúnmìlà

Ọ̀rúnmìlà tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bí i (Ọ̀rúnmìlà, Orúnla, Orúla tàbí Ọ̀rún ló mọ ẹni tí yóó là, ní ilẹ̀ Yorùbá ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Latin America) jẹ́ Òrìṣà.

Ó jẹ́ òrìṣà Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀, àti Alásọṣẹ, ìdí tí òrìṣà yìí fi rí bẹ́ẹ̀ ni wípé ó nímọ̀ t'ó peregedé nípa ọmọnìyàn tí ó sì ń ṣe gbogbo nǹkan rẹ̀ ní ìlànà mímọ́, tí gbogbo ohun t'ó bá sọ kìí ṣaláì ṣẹ.

Ọ̀rúnmìlà
Wisdom, Knowledge, Ifá Divination, Fate, Destiny, Prophecy
Member of Orisha
Other namesỌ̀rúnmìlà or Orunmilá; Orúnla or Orúla or Àgbọnmìrègún
Venerated inYoruba religion, Umbanda, Candomble, Santeria, Haitian Vodou, Folk Catholicism
SymbolIfá divination
RegionNigeria, Benin, Latin America
Ethnic groupYorùbá
ParentsAlayeru and Oroko

Ìtàn Ọ̀rúnmìlà àti Lítíréṣọ̀ àtẹnudẹ́nu tó rọ̀ mọ

Ọ̀rúnmìlà gẹ́gẹ́ bí òrìṣà ìgbà ìwáṣẹ̀ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn òrìṣà tí ó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, tí ó sì ti wà láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé tí ó gbé láàárín àwọn ọmọ ènìyàn gẹgẹ́ bí olùmọ̀ràn tí ó sì tún ń ṣe àkóso tàbí àgbàwí láàárín ènìyàn àti Ẹlẹ́dàá wọn nígbà tí wọ́n bá tọ̀ ọ́ wá láti ṣèbéèrè lórí ohun t'ó bá rú wọn lójú lọ́dọ̀ Babaláwo wọn. Ọ̀rúnmìlà ni ó kọ́kọ́ wá sáyé gẹ́gẹ́ bí Babaláwo àkọ́kọ́ ní àwòrán ènìyàn tí ó sì kọ́ àwọn ẹ̀dá ọmọ ènìyàn ní ifá dídá kí wọ́n lè máa bá a ní gbólóhùn nígbà tí ohun-kóhun kò bá fẹ̀ yé wọn. Ọ̀rúnmìlà ni ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀ jùlọ láàárín àwọn òrìṣà t'ó kù, tí ó sì máa ń sọ́ òkodoro bí kádàrá ẹni bá ti rí nípa sísọ àsọtẹlẹ̀ lórí ayé ẹni náà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń kì í wípé:

" Igbákejì Olódùmarè

àti

"Ẹlẹ́rìí ìpín" (witness of fate). Òun yìí kan náà l'ó ṣagbátẹrù gbígbé Ifá (Ìmọ̀ Elédùmarè) wá sílé ayé. Àwọn olúsìn Ifá l'ọ́kùnrin ni a mọ̀ sí Babaláwo nígbà tí àwọn olùbọfá l'óbìnrin jẹ́ Ìyá nífá (ìyá onifá).

Ọ̀rúnmìlà gẹ́gẹ́ bí

ọlọ́gbọ́n, nìkan ṣoṣo ni ó mọ ipò tí Olódùmarè tó gẹ́gẹ́ bí orí (intuitive knowledge) láàárín àwọn Òrìṣà t'ó kù, nítorí Orí ní í gbeni òrìṣà kì í gbànìyàn.

Awo àti ìjọ́mọ awo

Ẹni t'ó bá jẹ́ Awo nínú àlàkalẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ́ kí ó sì mọ gbogbo Odù Ifá Igba àti Mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (256), tí ó sì gbọ́dọ̀ máa sọ àwọn ìtàn àti ìwúre t'ó bá Odù Ifá kọ̀ọ̀kan mu pẹ̀lú bí ó ṣe rí nígbà tí Ọrúnmìlà kọ́kọ́ wá sáyé gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Elédùà.

Apá kan nínú Ìlànà ìgbaniwọlé gẹ́gẹ́ bí ọmọ awo ni wípé, ọmọ awo gbọ́dọ̀ jẹ̀ ọkùnrin, nìgbà tí apá kejì wípé wọ́n lè gba obìnrin náà gẹ́gẹ́ bí ọmọ Awo. Gbólóhùn "Awo" jẹ́ fún àkọ àti abo tí ó bá ń kọ́ṣẹ Ifá dídá. Àwọn àríwísí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nípa ìṣakọ tàbí ìṣabo nínú ọmọ awo Ifá ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn oríṣìiríṣìi tí a gbọ́ nípa Ifá fúnra rẹ̀. Ní Latin America àti àwọn apá ibòmíràn ní West Africa, ohun tí a mọ̀ ni wípé Ọkùnrin nìkan l'ó lè jẹ Àràbà Ọ̀rúnmìlà, nígbà tí àwọn apá ibìkan ní West Africa bákan náà sọ wípé ipò yìí náà tọ́ sí àwọn obìnrin pẹ̀lú. Àwọn olúsìn Ifá gbàgbọ́ nínú ẹ̀mí takọ-tabo nítorí wípé akọ ń ṣẹ̀mí nítorí abo; bákan náà ni abo ń ṣẹ̀mi nítorí akọ ni. Fún ìdí èyí, kálukú wọn l'ó lẹ́tọ̀ọ́ sí jíjoyè nínú ẹgbẹ́ awo.

Gbogbo ẹsẹ̀ Ifá pátá ni ó ń kọ́ni nípa ìwà. Ìwà tí à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí, ni ó rọ̀ yíká òfin ẹ̀sìn náà, ni ó sì tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìṣe ẹ̀dá láwùjọ àti níbi gbogbo, tí Olódùmarè gan-an yọ́nú sí.

Ẹ tún lè wò

Ọ̀rúnmìlà  Èbúté Traditional African religion

Àwọn ìtọ́ka sì

Àwọn ìwé àmúlọ́

  • Chief S. Solagbade Popoola & Fakunle Oyesanya, Ikunle Abiyamo: The ASE of Motherhood 2007. ISBN 978-0-9810013-0-2
  • Chief S. Solagbade Popoola Library, INC Ifa Dida Volume One (EjiOgbe - Orangun Meji) ISBN 978-0-9810013-1-9
  • Chief S. Solagbade Popoola Library, INC Ifa Dida Volume Two (OgbeYeku - OgbeFun) ISBN 978-1-926538-12-9
  • Chief S. Solagbade Popoola Library, INC Ifa Dida Volume Three (OyekuOgbe - OyekuFun) ISBN 978-1-926538-24-2
  • James J. Kulevich, "The Odu of Lucumi: Information on all 256 Odu Ifa"
  • Ayele Fa'seguntunde' Kumari, Iyanifa:Women of Wisdom ISBN 978-1500492892

Tags:

Ọ̀rúnmìlà Ìtàn àti Lítíréṣọ̀ àtẹnudẹ́nu tó rọ̀ mọỌ̀rúnmìlà Awo àti ìjọ́mọ awoỌ̀rúnmìlà Ẹ tún lè wòỌ̀rúnmìlà Àwọn ìtọ́ka sìỌ̀rúnmìlà Àwọn ìwé àmúlọ́Ọ̀rúnmìlàAmẹ́ríkà LátìnìNàìjíríàÒrìsà

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Ògún LákáayéLinda IkejiSpéìn2537 GilmoreAnton ChekhovJeremy BenthamMẹ́ksíkòOrílẹ̀ èdè America25 Oṣù Kẹta12 Oṣù KẹtaSunny OfeheWikimediaPonnaGoogleAdekunle GoldJosé María BocanegraMàláwì13 October2001Àrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola67085 OppenheimerÀsà ilà kíkọ ní ilé YorùbáNaoto KanÀṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ YorùbáÌwé Ẹ̀sẹ́kíẹ̀lìLouis 14k ilẹ̀ FránsìKelly Rowland2023Nathaniel BasseyÈdè PólándìGerald FordÒrìṣà Egúngún2021Ōkuma ShigenobuKeizō ObuchiNATOTelluriumTwitterÈdèPlatoEwìÈdè EsperantoJacqueline Kennedy OnassisÌṣekúpa Abraham LincolnÌladò Suez4 March2324 Janice2024Ohun ìgboroBẹ́ljíọ̀mIfáOlómìnira Nagorno-KarabakhÒrò àyálò YorùbáÈdè Swati9 DecemberÀwọn Ẹ̀ka-èdè YorùbáCreative CommonsNorwegian language4 Oṣù KẹtaHawaiiWiki Commons10 March13 DecemberPólándìAustrálíà🡆 More