Ọ̀rọ̀ orúko ni ọ̀rọ̀kọrọ̀ nínú gbólóhùn èdè Yorùbá tí ó jẹ́ orúkọ tàbí tí ó ń tọ́ka sí orúkọ ènìyàn, ẹranko, ìlu, nǹkan (ẹlẹ́mìí tàbí aláìlẹ́mìí, nǹkan afòyemọ̀, nǹkan aṣeékà, aláiseéka ) ọ̀rọ̀ orúkọ ni olùwà fún àbọ̀ .
*Bọ́lá, Shadè, Adé wálé - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Ènìyàn *Ewúrẹ́, Ajá, - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Ẹranko *Òkúta, Tábìlì, ìwé,- Ọ̀rọ̀-Orúkọ Nǹkan Aláìlẹ́mìí *ènìyàn, ẹranko - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Nǹkan Ẹlẹ́mìí *Ìfẹ́,ìbànújẹ́ - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Afòyemọ̀ *Èkùrọ́ tábìlì - Ọ̀rọ̀-Orúkọ aṣeékà *Omi, ìrẹsì - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Àìṣeékà.
Bọ́lá wọ aṣọ.
Ewúré ni mo pa.
Ipò méjì pàtàkì ni ọ̀rọ̀ orúkọ lè wà lédè Yorùbá. Ó lè wà nípò olùwà tàbí nípò àbọ̀.
Ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá lè wà ní ipò olùwà. Bí àpẹẹrẹ; Bọ́lá lọ jẹun.
Ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá lè wà nípò àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ; Ṣadé ra bàtà.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ọ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá), which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.