Mobolaji Iyabode Akiode (tí wọ́n bí ní May 12, 1982) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí sí ilẹ̀ America tó fìgbà kan jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n fún Nàìjíríà.
Ìlú New Jersey ni wọ́n bí i sí, ẹbí rè sì kọ lọ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lẹ́yìn náà. Akiode padà sí United States nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́sàn-án, ìlú Maplewood, New Jersey ni wọ́n sì ti tọ dàgbà. Oríṣiríṣị ìpènijà ló ní nítorí ìwọ̀ gíga rẹ̀, àmọ́ ó pegedé nínú eré-ìdárayá, ó sì mú Columbia High School wọ 1998 state championship kí ó tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 1999. Akiode gba ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ láti gba bọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ní Fordham University. Ní Fordham yìí, Akiode gba àmì-ẹ̀yẹ all-conference honors ní ọdún àgbà rẹ̀, ó sì jẹ́ agbábọ̀ọ̀lù kẹjọ ti Fordham láti ní ìkọsílẹ̀ 1,000 points àti àtúnṣe 500 lásìkò yìí. Ó sì tún gba tryout pẹ̀lú WNBA's Detroit Shock lẹ́yìn iṣẹ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé.
Akiode kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣirò ní Gabelli School of business, ní Fordham University, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ọdún 2004. Ó gba oyè Masters of Business Administration láti New York University Stern School of Business ní ọdún 2014.
Akiode gba ètò ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ láti gbá bọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ní Fordham University. Ní Fordham yìí, Akiode gba àmì-ẹ̀yẹ all-conference honors ní ọdún àgbà rẹ̀, ó sì jẹ́ agbábọ̀ọ̀lù kẹjọ ti Fordham láti ní ìkọsílẹ̀ 1,000 points àti àtúnṣe 500 lásìkò yìí. Ó sì tún gba tryout pẹ̀lú WNBA's Detroit Shock lẹ́yìn iṣẹ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé. Wọ́n gbà á wọ inú Fordhams University basketball Hall of fame ní ọdún 2014.
Orísun
GP | Games played | GS | Games started | MPG | Minutes per game |
FG% | Field goal percentage | 3P% | 3-point field goal percentage | FT% | Free throw percentage |
RPG | Rebounds per game | APG | Assists per game | SPG | Steals per game |
BPG | Blocks per game | PPG | Points per game | Bold | Career high |
Ọdún | Ẹgbẹ́ | GP | Pọ́íǹtì | FG% | 3P% | FT% | RPG | APG | SPG | BPG | PPG |
---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|---|
1999-00 | Forham | 27 | 162 | 42.5% | 0.0% | 60.3% | 5.0 | 0.8 | 1.0 | 0.8 | 6.0 |
2000-01 | Forham | 26 | 233 | 45.5% | 0.0% | 72.4% | 5.5 | 1.1 | 0.8 | 0.6 | 9.0 |
2001-02 | Forham | 29 | 277 | 39.0% | 32.4% | 71.6% | 4.0 | 1.2 | 1.3 | 0.3 | 9.6 |
2002-03 | Forham | 30 | 495 | 40.1% | 30.6% | 77.0% | 5.4 | 1.9 | 1.4 | 0.5 | 16.5 |
Career | 112 | 1167 | 41.1% | 30.4% | 71.9% | 4.9 | 1.3 | 1.2 | 0.5 | 10.4 |
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Mobolaji Akiode, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.