Litireso tabi iṣẹ́ọnàmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà
OHUN TÍ LÍTÍRÉṢỌ̀ JẸ́
Eléyìí náà kò ṣàì ní orírun tirẹ̀ láti inú èdè Látìn “LITERE” Èyí ni àwọn gẹ́ẹ́sì yá wọ inú èdè wọn tí wọ́n ń pè ni lete rature” Ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ máa ń yípadà láti ọ̀dọ̀ ẹ̀yà ènìyàn kan sí èkejì láti ìgbà dé ìgbà. Lítíréṣọ̀ kò dúró sójú kan. Babalọlá (1986), ṣàpèjúwe lítíréṣọ̀ pé:
“Àkójọpọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè kan tàbí òmíràn tó jásí ewì, ìtàn àlọ́, ìyànjú, eré onítàn, ìròyìn àti eré akọ́nilọ́gbọ́n lórí ìtàgé”
Tí a bá wo òde òní, ìtumọ̀ tí a fún lítíréṣọ̀ tún yàtọ̀, fún àpẹẹrẹ a máa ń ṣàkíyèsí ìlò èdè tí wọ́n fi kọ ìwé kan yàtọ̀ sí èyí, a tún ka lítíréṣọ̀ kùn iṣẹ́ òǹkọ̀wé alátinúdá tàbí iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìlò ojú inú gẹ́gẹ́ bí ewì, ìtàn àròkọ àti eré oníṣe. A ó sì rí i pe awẹ́ tàbí ẹ̀yà lítíréṣọ̀ tí a mẹ̀nubà wọ̀nyí kó púpọ̀ nínú ìmọ̀ ìgbé ẹ̀dá láwújọ (folklore) mọ́ ara, yálà, a kọ, ọ́ sílẹ̀, a rò ó sọ tàbí a ṣe é léré yàtọ̀ fún àwọn àkọọ́ lẹ̀ iṣẹ́ ọwọ́. Lítírésọ̀ tún jẹ́ irúfẹ́ àkọọ́lẹ̀ tó ní àbùdá ẹ̀mí gígùn, ó máa ń fi ìṣẹ̀ṣe àti àṣà àgbáríjọ àwọn èèyàn kan hàn. Àwọn míràn tó tún sọ̀rọ̀ lórí lítíréṣọ̀ ni àwọn ọmọ lẹ́yìn Mark: Àwọn Marxist (1977) yìí gbà pé:
“Scrutiny of the literature could not be realize without the society”
Èyí ni pé:
“Lítíréṣọ̀ kò lè ṣe é dá yẹ̀wò láìwo àwùjọ tí a kọ ọ́ fún”
Kí òǹkọ̀wé kan tó lè se iṣẹ́ rẹ̀ ní àṣeyanjú, irúfẹ́ oǹkọ̀wé náà gbọ́dọ̀ ni àtinúdá àtinúdá yìí pẹ̀lú ohun gan-an tí ó ń ṣelẹ̀ láwùjọ ni yóò wá sọ di ọ̀kan nínú iṣẹ́ rẹ̀. Lara àwọn tí ó ṣiṣẹ́ lórí ìlànà Marx yìí ni: Trosky ara Russia, Lucas àti Goldmann. Daviguand (1960) ni tíọ́rì sọ pé
“Literature enumerate the future thought of an individual (Human being)
Èyí ni pé:
“Lítíréṣọ̀ wà fún láti máa so èrò ọkàn ènìyàn jáde nípa ọjọ́ iwájú”
Nípa yíyẹ lítíréṣọ̀ wò, à ní láti wo ẹ̀hun ìpìlẹ̀ ìtumọ̀, èyí ni wíwo gbogbo nǹkan tí ó wà láwùjọ yẹn olápapọ̀ láì dá ọ̀kan sí.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Lítíréṣọ̀, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.