Uju Ugoka Ogbodo (tí wọ́n bí ní 24 May 1993) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, fún ẹgbẹ́ La Roche Vendée Basket Club àti Nigerian national team.
Ó gbá bọ́ọ̀lù náà fún ilé-èkọ́ rẹ̀, lábẹ́ ẹgbẹ́ Virginia Tech Hokies women's basketball.
Uju Ugoka taking a foul shot at Virginia Tech in 2013 | |
No. 1 – La Roche Vendée Basket Club | |
---|---|
Position | Point guard |
League | Ligue Féminine de Basketball |
Personal information | |
Born | Oṣù Kàrún 24, 1993 Lagos, Nigeria |
Nationality | Nigerian |
Listed height | 6 ft 1 in (1.85 m) |
Listed weight | 146 lb (66 kg) |
Career information | |
College |
|
NBA draft | 2014 / Undrafted |
Pro playing career | 2014–present |
Career history | |
2014-2015 | Pallacanestro Vigarano |
2015 | First Bank Basketball Club |
2015-2016 | Basket Parma |
2016-2018 | AZS-UMCS Lublin |
2018-present | La Roche Vendée Basket Club |
Ugoka kó lọ sí United States lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ ní Hope for girls basketball camp, èyí tí Mobolaji Akiode dá sílẹ̀. Ó gbá bọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ọlọ́dún kìíní ní Grayson County College, ṣíwájú àkókò kí wọ́n tó mú ìdádúró bá gbígbá bọ́ọ̀lù alájùsáwọ̀n ní ọdún 2011, wọ́n mú u wọ ẹgbẹ́ NJCAA All-America honors. Ó wá lọ sí Gulf Coast State College Commodores ní ọdún kẹta rẹ̀, pẹ̀lú ipò 16.69, 8.79 àti ìránlọ́wọ́ 0.93. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó dára jù ti NJCAA All-America honors. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé e lọ sí Virginia Tech Hokies women's basketball ní ọdún 2012 fún ẹ̀kọ́ ọlọ́dún kékeré àti ọlọ́dún àgbà. Lásìkò tó wà ní ọdún kékeré, ó gba ipò 12.5 àti àtúnṣe 8.5. Ní ọdún àgbà rẹ̀, ó gba ipò 18.4, àtúnṣe 9.6 àti ìrànlọ́wọ́ fún ayò kọ̀ọ̀kan.
Ugoka ṣojú Nàìjíríà ní 2008 FIBA Africa Under-18 Championship for Women níbi tí ó ti gba ipò 3 points àti àtúnṣe 3.
Ugoka ṣojú Nàìjíríà bákan náà 2009 FIBA Africa Championship for Women, níbi tí ó to gba 7 points, àti àtúnṣe 3.2 pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ 0.5 nínú ayò kọ̀ọ̀kan. Ní 2009 FIBA Africa Championship for Women, ó gba 7.4 points, àtúnṣe 5.1 àti ìrànlọ́wọ́ 0.3 nínú ayò kọ̀ọ̀kan. Ugoka tún ṣojú Nigerian national team ní 2016 FIBA World Olympic Qualifying Tournament for Women tó wáyé ní France, ó gba 5 points, àtúnṣe 5 àti ìrànlọ́wọ́ 1 nínú ayò kọ̀ọ̀kan.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Uju Ugoka, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.