Abdulrazak Gurnah

Abdulrazak Gurnah FRSL (tí a bí ní ogúnjọ́ oṣù kejìlá ọdún 1948) jẹ onkọ̀wé nofẹli àti ọ̀mọ̀wé ọmọ orílẹ̀ èdè Tanzania tí o fi ìlú gẹ̀ẹ́sì (United Kingdom) ṣe ibùgbé tí ó sì ní íwé àṣẹ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ìlú Gẹ̀ẹ́sì.

A bí i ní ni Sultanate ti Zanzibar ó sì gbéra lo sí ìlú geesi ní odun 1960 gege bi i asa asala fun emi ara eni ní àkókò rògbòdìyàn ní ìlú Zanzibar . Lára àwon iwe re ti o ti ko ni Párádísè (1994), èyí tí ó jé asayan fun ebun Booker ati Whitbread  ; Desertion (2005); ati By the Sea (2001), eyi ti won ti koko se asayan re fun Booker ti won si tun se asayan re fun ebun iwe ti i iwe iroyin Los Angeles Los Angeles Times Book Prize .

Abdulrazak Gurnah
Abdulrazak Gurnah

Gurnah ni o gba ami eye ti

Nobel Prize ni Litireso ni ọdun 2021 “fun aibikita ati irẹwẹsi aanu rẹ ti awọn ipa ti ijọba amunisin ati awọn ayanmọ ti asasala ni agbegbe gulf laarin awọn aṣa ati awọn continenti”. O jẹ Ọjọgbọn ti o peregede julo ninu imo Geesi ati awon Litireso fun ti postcolonial ni ile-eko giga Yunifasiti ti Kent.

Ibere Igbesi aye re ati ẹkọ

A bi Abdulrazak Gurnah ni ogunjo osu kejìlá odún 1948 ni Sultanate ti Zanzibar, eyiti o jẹ apakan ti Tanzania loni. O kuro ni erekusu nígbà tí ó di omo odún méjìdínlógún lehin ìgbàtí won gba ìjoba lowo gbajúmo Lárúbáwá tí ó n se ìjoba ní àkókò rògbòdìyàn tí ó bé síle ni Zanzibar Iyika, Ni odún 1968 ni Gurnah dé sí ile Geesi gegebi i asáàsálà. Èyà Lárúbáwá ni Gurnah je tí bàbá àti àbúrò bàbá re je onísòwò tí wọ́n ṣí wá láti Yemen . Gegebi Gurnah ti sọ wípé, "Mo wá sí ile Geesi nigbati awọn ọrọ wọnyi, gẹgẹbi olùwábi ààbò, ko jẹ bakanna - awọn opo ènìyàn n tiraka tí won si n sare kuro ní awon Ìpínle oníjàgídíjàgan."

O kọkọ kọ ẹkọ ni Ile-ẹkọ giga Christ Church, Canterbury, ile- eko tí o je wípé ilé-eko giga Yunifasiti ilu London ni o ma n fun awon akeko ti o ba jade nibe ni iwe-eri ní àkókò náà. Leyin èyín ni ó lo sí ilé-ìwé gíga Yunifásítì ti Kent, níbití ó ti gba oyé ìjìnle ti ojogbon (PhD) pelu ìwé afowoko re ti akole re je


Criteria in the Criticism of West African Fiction, ni ọdun 1982.

Iṣẹ-ṣiṣe

Láti odún 1980 sí odún 1983 Gurnah se ise olúkoni ní ilé-eko gíga Yunifásítì Bayero tí ó wà ní Kano ní orile-ede Nàìjíríà. Leyinna ni o di ojogbon ninu eko Geesi àti Litiraso fun postcoloial ni ilé-eko gíga Yunifásítì ti kent, níbití ó ti se ise olùko títí ó fi feyinti ní odún 2017; ni bayi i ojogbon agba ninu eko Geesi ati awon Litiraso

postcolonial ni ile-eko giga Yunifásítì yi ni i se..

Botilẹjẹpe awọn alariwisi se atewogba awon ìwé nofeli ti Gurnah ko daradara, sibe awon nofeli yi ko fibee ta daradara àti wípé won ko se ate jade awon nofeli yi ni ibòmíràn àfi i ìlú Geesi nìkan. Lẹhin tí won ti fun ni ẹbun Nobel fun Litireso ni ọdun 2021, awọn olutewe jade ati awọn olutaja iwe tiraka lati le ba a dogba pelu igbega ti o de ba bibeere fun awon iwe re. O je wípé leyin ti won kede ebun Nobel yi ni Gurnah gba awon ipe lati odo awon atewe jade lati orile-ede Amerika lori nofeli re Afterlives; Awọn iwe Riverhead ngbero lati gbe e jade ni osu kejo odun 2022. Riverhead tun gba awọn ẹtọ lori By the Sea and Desertion, eyi ti i se meji ninu awon ise Gurnah ti won ti jade lo fun tite jade.

kikọ

Pelu iṣẹ rẹ gege bi oluko ni ile-ẹkọ giga Gurnah jẹ onkọwe ati eni o ma nko nofeli lorisirisi. O ti ko ọpọlọpọ awọn itan kukuru, awọn arosọ ati awọn nofeli mewaa.

Nigba ti ede akọkọ rẹ jẹ Swahili, ede Gẹẹsi ni o nlo gẹgẹbi ede ti o ma fi nko awo iwe re. Sibẹsibẹ Gurnah lo die ninu awọn ede bi i Swahili, Arabic ati German ninu pupọ awọn iwe rẹ ti o ti ko. O so wipe oun ni lati pada so fun awon atewejade lati tesiwaju ise yii ati wipe won yio fe lati pe ki awon itokasi ati awon gbolohun oro lori ede Swahili ati Larubawa je ami italisi tabi Anglicize ninu awon iwe re. Gurnah ti ṣofintoto awọn iṣe ninu iwe atẹjade Ilu Gẹẹsi ati Amẹrika ti o fẹ lati “jẹ ki alejò dabi ajeji” nipa siṣamisi awọn ofin ati awọn gbolohun “ajeji” pẹlu awọn italics tabi nipa fifi wọn sinu iwe-itumọ. Gẹgẹbi omowe, Hamid Dabashi se awon akosile pe Gurnah "jẹ pataki si ọna ti iriri awon ara ile Asia ati awon ti nsi kiri ni ile Afirika ati ni ilu okere ni ilọsiwaju ati iyipada ede Gẹẹsi ati iwe-Litiraso. . .. ti won si npe awon onkowe bi i Gurnah diasporic, exxilic, tabi eyikeyi iru ọrọ alọlọ-ara-ẹni ti o fi otitọ pamọ pe Gẹẹsi jẹ abinibi fun u paapaa ṣaaju ki o to lo si orile-ede alawo funfun (England. Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti gbé e wá sílé fún un.”

Tags:

Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kanTànsáníàÌjídìde ZanzibarẸ̀bùn Booker

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Àṣà YorùbáBùlgáríà.nlAbdullahi Ibrahim (ológun)George Walker BushÀsìkòTegucigalpaWalter Rudolf HessGboyega OyetolaISBNPúẹ́rtò RíkòỌ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá)21 OctoberOwe YorubaNikita KhrushchevLeadEwìISO/IEC 27000-seriesZheng HeR. KellyỌ̀rúnmìlàC++Olaitan Ibrahim8 OctoberRobert HofstadterYemojaAbẹ́òkútaHermann Hesse26 MayÒgún LákáayéMwambutsa 4k Bangiriceng ilẹ̀ BùrúndìIlà kíkọ nílẹ̀ Yorùbá67085 OppenheimerUttarakhandNigerian People's PartyBadagryASCIIÌhìnrere LúkùÒrìṣà AgẹmọArizona1 AugustJohn Carew Eccles.gyMichael JordanOṣéáníàAdunni AdeMiguel Primo de Rivera, 2nd Marquis of EstellaLogicKùwéìtìYukréìnDVÀṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ YorùbáEre idaraya24 JuneDick CheneyWinston Churchill7 NovemberỌjọ́ Àbámẹ́taOregonJohn LewisVP3AlaskaStockholm5 MayKylian MbappéRalph Bunche🡆 More