Steve Gukas

Steve Gukas jẹ́ ẹni tó ń ṣe fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà olùdarí fíìmù àti àṣagbátẹrù fíìmù tó gbàgbọ́ pé àwọn fíìmù tí à ń gbé jáde gbọdọ̀ rí ojútùú sí àwọn ìṣẹ̀lẹ́ inú àwùjọ.

Steve Gukas
Ọjọ́ìbíNigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Filmmaker, Film director
Gbajúmọ̀ fún93 Days (2016) •
A Place in the Stars (2014)

Ètò èkọ́ rẹ̀

Gukas kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Television Production ní NTA TV College ní Jos. Ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa Theatre Arts ní University of Jos àti nípa Film production ní London Film School, United Kingdom.

Iṣẹ́ tó yàn láàyò

Ó fìgbà kan jẹ́ olùdarí ọ̀kan lára àwọn ilé-iṣẹ́ rédíò ní Nàìjíríà, ìyẹn WE FM.

Ní ọdún 2002, ó darí fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Keeping Faith". Ní ọdún 2007, ó ṣàgbéjáde fíìmù "Namibia: The Struggle for Liberation", èyí tí òṣèrẹ́kùnrin ilẹ̀ America kan kópa nínú rẹ̀, ìyẹn Danny Glover; fíìmù yìí jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́.

Ní ọdún 2014, wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù kan tó jẹ́ darí, tó sì ṣagbátẹrù, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́, "A Place in the Stars" . Lára àwọn akópa fíìmù náà ni Segun Arinze, Dejumo Lewis, Matilda Obaseki, Gideon Okeke, Yemi Blaq àti Femi Branch. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 2015, fíìmù náà gba amì-ẹ̀yẹ Africa Magic Viewers Choice Awards (AMVCA), gẹ́gẹ́ bí i fíìmù tó dára jù lọ.

Ní ọdún 2016, ó darí fíìmù kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "93 Days", tó dá lórí oníṣègùn ilẹ̀ Nàìjíríà kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dr. Stella Ameyo Adadevoh, tó ṣiṣẹ́ takuntakun láti kojú àrùn Ebola tó bẹ̀ sílẹ̀ sí Nàìjíríà ní ọdún 2014. Lára àwọn akópa fíìmù náà ni Bimbo Akintola, Danny Glover, Seun Ajayi, Keppy Ekpeyong àti Bimbo Manuel.

Òun náà ló ṣàgbéjáde fíìmù "Keeping The Faith" àti "Mr. Johnson".

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

Ọdún Àkọ́lé Ipa Notes
2019 Living in Bondage: Breaking Free co-producer
2016 93 Days director
2014 A Place in the Stars director •

co-producer

2007 Namibia: The Struggle for Liberation producer
2002 Keeping Faith director

Àwọn ìtọ́kasí

Tags:

Steve Gukas Ètò èkọ́ rẹ̀Steve Gukas Iṣẹ́ tó yàn láàyòSteve Gukas Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀Steve Gukas Àwọn ìtọ́kasíSteve GukasNàìjíríà

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Gúúsù Áfríkà12 NovemberDimitrios GounarisÌnáwóHannah Idowu Dideolu AwolowoWiki CommonsSubrahmanyan ChandrasekharÌpínlẹ̀ ÒgùnHattie McDanielẸ̀yà ara ìfọ̀Maria BraimohPakístànCountry code top-level domainH. D. Deve GowdaPort HarcourtWarsawEwébẹ̀Windows Media AudioNew JerseyÉmile DurkheimÀwọn ọmọ ÍgbòNPolitician30 May.giEgyptMargaret RutherfordGírámà YorùbáArgẹntínàOrin-ìyìn Orílẹ̀-èdè Gúúsù ÁfríkàÌwéìròyìnLos AngelesTaiye SelasiAnna TatishviliAderonke ApataEmiliano FigueroaÀsìá ilẹ̀ Hàítì20 JulyÌgbéyàwóHarry BelafonteQẸ̀yà ara ÈnìyanSpéìnKady TraoréSidi Boushaki7 MayGOwo siseOgunKunle AfolayanLuther Vandross29 OctoberBelinda KandaÙsbẹ̀kìstánÌwo Orí ilẹ̀ ÁfríkàEuroSneh GuptaChaka KhanÀṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ YorùbáETrentonKiev2 MaySístẹ́mù ajọfọ̀nàkò jẹ́ọ́gráfìHerbert MacaulayC7998 GoncziArabDahir Riyale KahinMáàdámidófòÀwọn orin ilẹ̀ Yorùbá🡆 More