93 Days

93 Days jẹ́ fíìmù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jáde ní ọdún 2016.

Ó jé fíìmù ajẹmọ́-ìṣẹ̀lẹ̀-tó-le, èyí tí Steve Gukas darí. Fíìmù náà sọ ìtàn àrùn Ebola tó wáyé ní ọdún 2014 ní Nàìjíríà àti bí àọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ṣe kojú rẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé-ìwòsàn kan ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Lára àwọn òṣèré tó kópa nínú rẹ̀ ni Bimbo Akintola, Danny Glover àti Bimbo Manuel, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Native FilmWorks, Michel Angelo Production àti Bolanle Austen-Peters Production.

93 Days
AdaríSteve Gukas
Olùgbékalẹ̀
Steve Gukas
Òǹkọ̀wéPaul S. Rowlston
Àwọn òṣèré
OrinGeorge Kallis
Ìyàwòrán sinimáYinka Edward
OlóòtúAntonio Rui Ribeiro
Déètì àgbéjáde
  • 16 Oṣù Kẹ̀sán 2016 (2016-09-16)
Àkókò118 minutes
Orílẹ̀-èdèNigeria
ÈdèEnglish

Wọ́n fi fíìmù 93 Days yìí sọrí Ameyo Adadevoh, tó jẹ́ oníṣègùn Nàìjíríà kan tó kó ipa rẹpẹtẹ nínú bíborí àrùn Ebola ní Nàìjíríà.

Àhunpọ̀ ìtàn

Ní 20 July 2014, Patrick Sawyer, tó jẹ́ ọmọ Liberia tó tan mọ́ ìlú America dé sí ìpínlẹ̀ Èkó, ní Nàìjíríà. Ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbe lọ sí First Consultants Medical Center, lẹ́yìn àìsàn rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn oníṣègùn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ìyẹn, Dr. Ameyo Adadevoh, ń rò ó pé ó ti ní àrùn Ebola, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sawyer ní òun ò ní àrùn náà. Oníṣègùn náà pinnu láti tì í mọ́ yàrá kan pẹ̀lú ìbójútó àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ìwòsàn náà.

Ní ọ̀sàn ọjọ́ kejì, èsì àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe jáde, wọ́n sì ri pe Sawyer tí kó àrùn Ebola. Ìròyìn yìí jáde síta, ó sì jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó máa kó àrùn náà ní Èkó, èyí sì mú kí àwọn ilé-iṣẹ́ ìròyìn bẹ̀rẹ̀ sí ní kéde rẹ̀. Nàìjíríà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbáradì fún ìtànká àrùn náà.

Dr. Adadevoh pàdé Dr. Wasiu Gbadamosi, tó ń ṣàmójútó Yaba infectious facility, àti Dr. David Brett-Major láti World Health Organization. Ó ṣàkíyèsi pé Yasu facility ò ní àwọn irinṣẹ́ tó pé ye láti fi kojú àrùn náà. Ní July 25, àwọn oníṣègùn náà ṣàkíyèsi pé Sawyer ti kú. The First Consultants Medical Center sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wá ojútùú sí ìṣòro yìí, àti láti dáàbò bo àọn òṣị̀ṣẹ́ wọn.

Ìtàn náà dá lórí ìfarajìn tọkùnrin-tobìnrin tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀, láti ri dájú pé wọ́n borí àrùn náà, kí ó tó di àjàkálẹ̀ àrùn.

Àwọn akópa

Àwọn ìtọ́kasí

Tags:

Bimbo AkintolaBimbo ManuelDanny GloverNàìjíríàSteve GukasÌpínlẹ̀ Èkó

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Lagos State Fire ServiceYuan T. LeeLuther VandrossList of countriesCôte d'IvoireOrin-ìyìn Orílẹ̀-èdè Gúúsù ÁfríkàKàmbódíàJames Clerk MaxwellJoan CusackÌpínlẹ̀ ÁbíáWálé Adébáyọ̀Mr MacaroniÈdè PọtogíÌpínlẹ̀ Ọ̀yọ́KàsínòPakístànKim BasingerKelechi IheanachoÌnáwóAdebukola OladipupoJohn Lewis29 OctoberGuernseyOpen Amẹ́ríkà 2012 − Àwọn Obìnrin ẸnìkanÀríwá Amẹ́ríkàNarendra ModiEniola AjaoÀwọn ọmọ PólàndìMahmud Hasan DeobandiIPhoneSidi BoushakiGeorge Maxwell RichardsỌ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá)Tina TurnerR.cvGregory AgboneniGeneral Exchange FormatHerbert C. BrownNellymoser Asao CodecMáàdámidófòHoward Martin TeminÀsà oge ṣíṣẹ́ ní ilè yorùbáOlu JacobsIlẹ̀ YorùbáOdò DánúbìNúmérì preferredHiggs boson2009Àkójọ àwọn àmìọ̀rọ̀ ìpè tẹlifónù orílẹ̀-èdèFamily on FireSILKIpinle Benue28 AprilÀṣà YorùbáMicrolophus quadrivittatusÀjàkálẹ̀ àrùn Covid-19 ní Sàó Tòmẹ̀ àti PrincipeỌjọ́Mengistu Haile MariamDavid MarkÌtàn ilẹ̀ NàìjíríàIslàmabad7 JulyEmeka IkeSáúdí ArábíàKievList of sovereign states🡆 More