Kunle Afolayan (tí wọ́n bí ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 1974) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, olóòtú àti olùdarí sinimá-àgbéléwò ọmọ bíbí Yorùbá, ní Ìgbómìnà láti ìpínlẹ̀ Kwara lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Bàbá rẹ̀ ni gbajúgbajà òṣèré sinimá àgbéléwò nígbà kan rí, ṣùgbọ́n tí ó ti di olóògbé, Adeyemi Afolayan, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Ade Love
Kunle Afolayan | |
---|---|
Kunle Afolayan at the 2014 Africa Magic Viewers Choice Awards | |
Ọjọ́ìbí | 30 Oṣù Kẹ̀sán 1974 Ebute Metta, Lagos State, Nàìjíríà |
Ibùgbé | Magodo, Ikeja, Lagos State, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ |
|
Olólùfẹ́ | Tolu Afolayan |
Àwọn ọmọ | 4 |
Parent(s) | Ade Love - father |
Àwọn olùbátan |
|
Kúnlé jẹ́ ọmọ bíbí Ìgbómìnà pọ́ńbélé láti ìpínlẹ̀ Kwara gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú. Gbajúgbajà òṣèré sinimá àgbéléwò àná ni bàbá rẹ̀ Ade Love. Kúnlé kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìsúná ọ̀rọ̀-ajé. Ó ṣiṣẹ́ nílé ìfowópamọ́ fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó dára pọ̀ mọ́ ìṣe sinimá àgbéléwò ṣíṣe lọ́dún 2015. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ń kópa ní ìwọ̀nba kí ó tó di àkókò yìí. Kúnlé máa ń kópa nínú sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni sinimá-àgbéléwò tí ó ti kópa tó ṣòódó. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sìn ni àmìn ẹ̀yẹ tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí eléré tíátà.
Year | Award | Category | Film | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2019 | Best of Nollywood Awards | Director of the Year | Diamond in the Sky | Wọ́n pèé | |
2021 | Net Honours | Most Searched Actor | Wọ́n pèé | ||
2023 | Africa Magic Viewers' Choice Awards | Best Indigenous Language – Yoruba | Anikulapo | Gbàá | |
Best Movie West Africa | Yàán | ||||
Best Overall Movie | Gbàá | ||||
Best Director | Yàán |
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Kunle Afolayan, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.