Àṣà Ìkíni Ní Àwùjọ Yorùbá

Gbajúgbajà àṣà Yorùbá Ìkíni jẹ́.

Ní àwùjọ Yorùbá, ó jẹ́ àṣà àwọn ènìyàn àwùjọ náà láti máa kí ara wọn ní gbogbo àwọn àkókò tí wọ́n bá bá ara wọn. Yorùbá gbàgbọ́ pé ìkínni jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ènìyàn lè gbà láti fi ọmọlúàbí rẹ̀ hàn.

Ní àwùjọ Yorùbá, bí ọmọ bá jí ní àárọ̀, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ kí àwọn òbí tàbí àwọn àgbàlagbà láàárọ̀. Bí ó bá jẹ́ pé ọkùnrin ni, irú ọmọkùnrin bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ dọ̀bálẹ̀ kí àwọn òbí tàbí àwọn àgbàlagbà. Tí ó bá jẹ́ pé ọmọbìnrin ni, ìkúnlẹ̀ ni yóò fi kí àwọn òbí àti àwọn àgbàlagbà tí ó bá fẹ́ kí.

Ohun mìíràn tí ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ ni pé kò pọn dandan fún ọmọdé láti kọ́kọ́ kí àgbàlagbà. Bí ó bá jẹ́ pé àgbàlagbà ni ó kọ́kọ́ rí ọmọdé, àgbàlagbà pẹ̀lú lè kí ọmọdé, tí irú ọmọdé bẹ́ẹ̀ yóò sì fi àpọ́nlé tó yẹ fi ìdáhùn sí kíkí náà.

Oríṣiríṣi ìkíni ni ó wà ní àwùjọ Yorùbá. Ìdí nìyìí tí Yorùbá fi máà ń sọ pé ìkínni ìgbà òjò yàtọ̀ sí ti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Lára àwọn ọ̀nà tí a lè pín ìkínni sí ní àwùjọ Yorùbá ni;

  1. Ìkínni Àkókò
  2. Ìkíni Ìgbà
  3. Ìkíni Iṣẹ́

ÌKÍNI ÀKÓKÒ:

Yorùbá ní àwọn ìkíni fún àwọn àkókò kọ̀ọ̀kan. Lára àwọn èyí tí ó wọ́pọ̀ jùlọ àwọn wọ̀nyìí;

  1. Àárọ̀: - Ẹ kú àárọ̀ o
  2. Ọ̀sán: - Ẹ káàsán o
  3. Ìrọ̀lẹ́: - Ẹ kú ìrọ̀lẹ́ o
  4. Alẹ́: - Ẹ káalẹ́ o

ÌKÍNI ÌGBÀ:

Ìkíni ìgbà náà jẹ́ ọkan lára àwọn ọ̀wọ́ tí a lè pín ìkíni sí ní àwùjọ Yorùbá. Ìgbà kọ̀ọ̀kan ni ó ní ìkínni tirẹ̀. Bí àpẹẹrẹ:

  1. Ìgbà Òtútù: - A kú Òtútù o
  2. Ìgbà Ọyẹ́: - A kú Ọyẹ́ o
  3. Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn: - A kú Ẹ̀ẹ̀rùn o
  4. Ìgbà Ooru: - A kú ooru o
  5. Ìgbà Òjò: - A kú òjò o

ÌKÍNI IṢẸ́ -

Yorùbá ní ìkíni kọ̀ọ̀kan fún iṣẹ́ ní àwùjọ náà. Èyí já sí pé ó ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí à ń gbà láti kí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ Yorùbá àti bí a ṣe ń kí àwọn tí wọn ń ṣe wọ́n nìyìí;

  1. Onídìrí: - Òòyà á yà o
  2. Atukọ̀: Ọkọ̀ á rèfó o
  3. Ọdẹ: - Àrìnpa ògún
  4. Àgbẹ̀: - Àroko bọ́du dé o
  5. Akọ̀pẹ: - Igbà á rọ̀ o
  6. Babaláwo: - Abọrúbọyè o
  7. Alágbẹ̀dẹ - Àrọyè o
  8. Oníṣòwò:Àpamọ́wọ́ owó o. Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ

Adeoye, C. L. (1979) Àṣà Àti Ìṣe Yorùbá. Ibadan: Oxford University Press.

Tags:

Àṣà Ìkíni Ní Àwùjọ Yorùbá ÌKÍNI ÀKÓKÒ:Àṣà Ìkíni Ní Àwùjọ Yorùbá ÌKÍNI ÌGBÀ:Àṣà Ìkíni Ní Àwùjọ Yorùbá ÌKÍNI IṢẸ́ -Àṣà Ìkíni Ní Àwùjọ Yorùbá ÌWÉ ÌTỌ́KASÍÀṣà Ìkíni Ní Àwùjọ YorùbáÀṣà YorùbáÌran YorùbáỌmọlúàbí

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Richard NixonHawaii2009IyánNọ́rwèyISO 7002AtlantaCliff Robertson.gaNancy ChartonMársìAminu Ado BayeroVictoria University of ManchesterÈdè PólándìKọ́nsónántì èdè YorùbáÌlaòrùn ÁfríkàÀwùjọWeb browserÀgbékalẹ̀ Ẹ̀kọ́ZuluÀsà ilà kíkọ ní ilé YorùbáLev BùlgáríàOrílẹ̀-èdè67085 OppenheimerLítíréṣọ̀United NationsOmanNigerian People's PartyJay-Jay OkochaÀsìá ilẹ̀ UkréìnYemojaÀṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ YorùbáFàdákàolómiSantos AcostaJames CagneyÒjòBeninÒrìṣà EgúngúnAdeniran OgunsanyaOgunDolby DigitalSílíkọ́nù2 JuneMùsùlùmíTẹlifísànÈdè EsperantoÀsìá ilẹ̀ KánádàỌ̀yọ́túnjíEmmanuel AmunikeBanky WWiki23 AprilAbraham LincolnPólàndìMicrosoft WindowsLos Angeles.aqFilipínìJúpítérì.lrIndonésíàIvor Agyeman-DuahÌpínlẹ̀ Ọ̀ṣunAma Ata AidooChinedu IkediezeVictoria, Ṣèíhẹ́lẹ́sìGúúsù Amẹ́ríkàLadi KwaliYemen🡆 More