Iyán: Iyan je onje okele ti ama n fi isu gun pelu obe adidun ti ibile nje

Iyán jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá tó gbajúmọ̀ jùlọ.

Iṣu funfun ló dára jù fún iyán gúngún. A lè fi iyán jẹ ọbẹ̀ ẹ̀fọ́, ẹ̀gúsí tàbí ilá. Gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n tí máa ń jẹ iyán ṣùgbọ́n iyán jíjẹ wọ́pọ̀ jùlọ láàárín àwọn Ìjẹ̀ṣà, Òndó àti Èkìtì.

Iyán: Tún Wò, Àwọn èròjà iyán gúngún, Bí a ṣe lè gúnyán
Iyán àti ọbẹ̀ ẹ̀fọ́

Tún Wò

Àwọn èròjà iyán gúngún

Iṣu ni ọba èròjà tí wọ́n máa ń fi gúnyán. Lẹ́yìn iṣu, a nílò odó, ó orí-odó àti omi.

Bí a ṣe lè gúnyán

  • A yóò bẹ iṣu
  • A yóò fọ iṣu náà tónítóní
  • À yóò dáná láti se iṣu
  • A yóò bu omi ní ìwọ̀nba tí ó lè se iṣu náà jiná sínú ìkòkò tàbí apẹ tí a fẹ́ fi se iṣu náà
  • A yóò kó iṣu tí a ti fọ̀ ní àfọ̀mọ́ sínú ìkòkò tí a gbé kaná
  • A yóò se iṣu náà títí yóò fi jiná dáradára.
  • Lẹ́yìn tí iṣu bá ti jiná, a yóò wà á sínú odó tí a ti fọ̀ kalẹ̀.
  • A yóò wá fi omorí odó fi gún un títí yóò fi lẹ̀ dáadáa.
  • A yóò wá kọ ọ́ sínú abọ́ tàbí àwo tó mọ́ tónítóní fún jíjẹ.

Àwọn ọbẹ̀ tí a fi lè jẹ iyán

Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, "Iyán loúnjẹ, ọ̀kà logùn, àìrí rárá là ń jẹ̀kọ" Yorùbá gbádùn iyán púpọ̀, oríṣiríṣi ọbẹ̀ ni wọ́n fi ń jẹ iyán. Àwọn ni;

  • Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́
  • Ọbẹ̀ ègúsí
  • Ọbẹ̀ àpọ̀n
  • Ọbẹ̀ ata díndín
  • Ọbẹ̀ ilá abbl.

Àwọn Ìtọ́kasí

Tags:

Iyán Tún WòIyán Àwọn èròjà iyán gúngúnIyán Bí a ṣe lè gúnyánIyán Àwọn ọbẹ̀ tí a fi lè jẹ iyánIyán Àwọn Ìtọ́kasíIyánÌjẹ̀ṣàÒndóỌbẹ̀

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

29 FebruaryISO/IEC 27007David Samanez OcampoFemi GbajabiamilaNigerian People's PartyÀwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìdánilóró September 11, 2001Ìṣọ̀kan ÁfríkàÈṣùÀwọn Ìdíje Òlímpíkì Ìgbà Oru 1988C++WikisourceMọfọ́lọ́jì èdè YorùbáÌwo Orí ilẹ̀ ÁfríkàISO 14644Ilẹ̀ọbalúayé Rómù ApáìlàoòrùnAdeniran OgunsanyaB.B. KingMongolia (country)Àkójọ àwọn orílẹ̀-èdèPerúStockholmFenesuelaTitun Mẹ́ksíkòMonacoẸ̀sìn IslamÌwé ÌfihànEpoISO 9984Gbogbo Ìpawó Orílẹ̀-èdèÌpínlẹ̀ Ọ̀ṣunAtlantaAvicennaOgedengbe of IlesaÈdè LátìnìRichard NixonIveta BenešováNorwayMicrosoftISO 4MadonnaKikan Jesu mo igi agbelebuEmilio AguinaldoISO 6523Francisco Diez CansecoZagrebÀwọn Ìpínlẹ̀ Aṣọ̀kan ilẹ̀ Amẹ́ríkàMa Ying-jeouPalẹstínìRené DescartesMọ́remí ÁjàṣoroÀmì ọ̀pá àṣẹ ilẹ̀ IndonésíàBrasilNẹ́dálándìNeil ArmstrongÌfitónilétíFiennaJanusz WojciechowskiYorùbáÀjákálẹ̀ àrùn káàkiriayé èrànkòrónà ọdún 2019 2020Halle BerryISO 15686InternetOlikoye Ransome-KutiOjúewé Àkọ́kọ́Audu OgbehÀrùn kòkòrò àìlèfojúrí afàìsàn Ebola🡆 More