Fẹ́mi Gbàjàbíàmílà tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 1962 (June 25, 1962) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèlú, Agbẹjọ́rò àti Agbẹnusọ Ilé-Ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú, All Progressives Congress tí ó ń ṣojú ìjọba ìbílẹ̀ Sùúrùlérè ni ìpínlẹ̀ Èkó láti ọdun 2019
Rt. Hon. Femi Abdulhakim Gbajabiamila | |
---|---|
Femi Gbajabiamila | |
Speaker of the House of Representatives of Nigeria | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga June 2019 | |
Asíwájú | Yakubu Dogara |
House Leader of the House of Representatives of Nigeria | |
In office June 2015 – June 2019 | |
Asíwájú | Ogor Okuweh |
Minority Leader of the House of Representatives of Nigeria | |
In office June 2011 – June 2015 | |
Arọ́pò | Ogor Okuweh |
Minority Leader of the House of Representatives of Nigeria | |
In office June 2007 – June 2011 | |
Asíwájú | Ahmed Salik |
Member of the House of Representatives of Nigeria | |
In office 2003–2007 | |
Asíwájú | yakubu Dogara |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kẹfà 1962 Lagos State, Nigeria |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressive Congress (APC) |
Residence | Lagos |
Alma mater | University of Lagos |
Occupation | Legislature |
Website | http://femigbajabiamila.com |
A bí Olufemi "Femi" Hakeem Gbajabiamila ní 25 June 1962 sí ìdílé Mr àti Mrs Lateef Gbajabiamila àti Olufunke Gbajabiamila ni Ìpínlè Èkó, Nàìjíríà. Ó lọ ilé ìwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ti Mainland fún àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti Igbobi College ní ọdún 1973, níbi tí ó ti parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó tún padà lọ King's William's College ni Isle Of Man, orílè-èdè United Kingdom fún ìwé-ẹ̀rí A-Level rẹ̀. Wọ́n gbà sí Yunifásítì Ìlú Èkó, Nàìjíríà. níbí tí ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ nínú ìmò òfin(LL.B) pẹ̀lú ẹ̀yẹ ní ọdún 1983, a sì pé é láti wá ṣiṣẹ́ òfin(call to bar) ní ọdún 1984.
Ó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ni ilé-ìṣẹ́ agbẹjọ́rò Bentley Edu &Co., ní ìpínlè Eko, kí ó tó dá ilé-iṣẹ́ agbẹjọ́rò kan, Femi Gbaja & Co. kalẹ̀.
A yan Gbajabiamila sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ọdún 2003, ó sì ń ṣe aṣojú Surulere I ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Gbajabiamila máa ń sọ̀rọ̀ lòdì sí bí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ṣe máa ń yí láti ẹgbẹ́ òṣèlú kan sí òmíràn.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Femi Gbajabiamila, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.