Jenna Marie Ortega (tí a bí ní ọjọ́ ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án ọdún 2002) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nínú àwọn fíìmù láti ìgbà èwe rẹ̀, ó sì gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ nínú eré Jane the Virgin (2014–2019). Ó gbajúmọ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó ṣe Harley Diaz nínú eré Disney kan, Stuck in the Middle (2016–2018), ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ Imagen Award fún ipa rẹ̀ nínú fíìmù yìí. Ó tún kópa Ellie Alves nínú fíìmù You ní ọdún 2019 àti nínú fíìmù Yes Day (2021) tí Netflix ṣe.
Jenna Ortega | ||||||||
---|---|---|---|---|---|---|---|---|
Ortega ní ọdún 2022 | ||||||||
Ọjọ́ìbí | Jenna Marie Ortega Oṣù Kẹ̀sán 27, 2002 Coachella Valley, California, U.S. | |||||||
Iṣẹ́ | Actress | |||||||
Ìgbà iṣẹ́ | 2012–ìsinsìnyí | |||||||
| ||||||||
|
Ortega kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fíìmù bi The Fallout (2021), Scream àti X (méjèèjì ní ọdún 2022), àti Scream VI ( ní ọdún 2023). Ní ọdún 2022, ó kópa Wednesday Addams nínú fíìmù Netflix tí àpèlé rẹ̀ jẹ́ Wednesday, èyí sì mú kí wọ́n yàn fún àwọn tí ó le gba àmì-ẹ̀yẹ Golden Globe àti Screen Actors Guild Awards.
Wọ́n bí Jenna Marie Ortega ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gún oṣù kẹsàn-án oṣù 2002,Coachella Valley ní California ni wọ́n bí sí, òun ni ọmọ kẹrin nínú mẹ́fà. Bàbá rẹ̀ wá láti Mexico, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ Mexico àti Puerto Rica.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Jenna Ortega, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.