Adó Èkìtì jẹ́ ìlú ńlá kan ní apá Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríàtí ó sì jẹ́ olú-Ìlú fún Ìpínlẹ̀ Èkìtì.
Adó Èkìtì Ado Ewi | ||
---|---|---|
| ||
Coordinates: 7°37′16″N 5°13′17″E / 7.62111°N 5.22139°E | ||
Country | Nigeria | |
State | Ìpínlẹ̀ Èkìtì | |
Area | ||
• Total | 293 km2 (113 sq mi) | |
Elevation | 455 m (1,493 ft) | |
Population (2012) | ||
• Total | 424,340 | |
Climate | Aw |
Gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn ti ọdún 2006 ṣe sọ wípé àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní ìlú Adó Èkìtì yálà Yorùbá Èkìtì ni, tàbí ẹ̀yà míràn jẹ́ 308,621, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn Èkìtì látòkè délẹ̀ jẹ́ ọkàn lára ẹ̀yà Yorùbá, amọ́ tí wọ́n tún tan diẹ̀ mọ́ Ẹdó. Edó-Èkìtì tàbí Adó-Èkìtì ni àwọn Yorùbá má ń sábà pe ẹni tí ó bá wá láti Ìpínlẹ̀ Èdo tàbí Adó. Ohun tí ó fàá ni wípé àṣà àti ìṣe wọn wọnú ara wọn bí eegun ti wọnú ẹran..
Ìlú Adó ní ilé-ẹ̀kọ́ ti ìjọba Ìpínlẹ̀ tí wọ́n ń pe ní Yunifásitì Ado Ekiti amọ́ tí wọ́n ti yí padà sí Ekiti State University. Bákan náà ni ilú náà tún ní ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Adáni tí ó ń jẹ́ Afe Babalola University tí ó wà ní ìlú Adó-Èkìtì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ní ilé-ẹ̀kọ́ akọ́ṣẹ́-mọṣẹ́ Pólì tí ó jẹ́ ti ìjọba apápọ̀ tí wọ́n pe ní Federal Polytechnic, Ado-Ekiti, wọ́n sì tún ní ilé-ẹ̀kọ́ ti gbogbonìṣe Pólì ti aládàáni tí wọ́n pè ní Crown polytechnic, Odo, Ado-Ekiti
Lára àwọn obun tí wọ́n fi ń ṣọrọ̀ aje ní ìlú Adó-Èkìtì ni kí á gbohùn sáfẹ́fẹ́, lára àwọn ilé-iṣẹ́ ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ tí ó jẹ́ amóhù-máwòrán ti ìjọba àpapọ̀ Nigerian Television Authority (NTA) ti ó wà ní ìlú Adó-Èkìtì. Bákan náà ni wọ́n tún ní ilé-iṣẹ́ amóhù-máwòrán ti Ìpínlẹ̀ tí wọ́n pe ní Ekiti State Television (BSES). Àwọn ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ti asọ̀rọ̀-mágbèsì náà kò gbẹ́yìn, lára wọn ni:
Oríṣiríṣi ohun ọrọ̀ aje ni ó wà ní ìlú Adó, tí àwọn ènìyàn sì ṣòwò kárà-kátà ohun ọ̀gbìn oríṣiríṣi bíi: ẹ̀gẹ́, iṣu, àwọn nkan oníhóró lóríṣirí, tábà òwú tí wọ́n sì ma ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [citation needed]
Lọ́wọ́ lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ adarí ìbílẹ̀ pàtàkì akọ́kọ́ ní ìlú Adó ni Ọba tàbí Èwí Adó ni Rufus Aladesanmi III tí wọ́n jẹ́ Èwí ti Adó, tí wọ́n tẹ́rí gbadé lẹ́yì Èwí àná, Ọba Samuel Adeyemi George-Adelabu I ní ọdún 1990.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Adó-Èkìtì, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.