Ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀, tí a mọ̀ láti ìṣẹ̀wá sí yẹ́lò jaki tàbí àjálù pupa, jẹ líle Àkóràn àrùn.
Ní ọ̀pọ̀ ìṣẹlẹ̀, lára aamì ni ibà, òtútù, àìle jẹun, èébì, iṣan dídùn pàápáà ní ẹhìn, àti orí fífọ́. Àwọn aamì sábà maa ń jẹyọ láàrín ọjọ́ márùn ùn. Àwọn ènìyàn kan láàrín ọjọ́ kan tí ara wọṅ ti ń dá, ìbà náà padà wá, inú dídùn maa ń wáyé, àti ẹ̀dọ̀ bíbàjẹ́ bẹ̀rẹ̀ èyí to ń fa àwọ̀ ara pípọ́n. Bí èyí bá wáyé, ewu ṣíṣẹ̀jẹ̀ àti àwọn ìṣoro kídìnrín maa ń pọ̀si.
Àkóràn arùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ ni okùnfà arùn náà èyí tí gígéjẹ abo ẹfọn ń tànká. Ènìyàn nìkan ni o ńkó àrùn yíì, àwọn pírámétì míìràn, àti ọ̀pọ̀ ẹ̀ya ẹ̀fọn míìràn. Ní àwọn ìlú, àwọn ẹ̀fọ́n ẹ̀yà Aedesaegypti ni ó sábà maa ń tàn káàkiri. Àkóràn yíì ni Kokoro RNA ti gẹ́nùsì Flavivirus. Àrùn náà le ṣòro láti sọ yatọ̀ sí àwọn aisàn míìràn, pà́apáà nígbà ìpinlẹ̀ àkọkọ́ bẹ́rẹ̀. Láti jẹ́rì ipò afurasí, àyẹwò ìdánwò ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú polymerase chain reaction ní a nílò.
Ìdábòbò àti ìmọ̀ọ́ṣe àjẹsára lódì sí àrùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ wà, àwọn orílẹ̀-èdè kan sì nílò àwọn àjẹsára fún àwọn arinrìn-ajò. Àwọn ìgbìyànjú míìràn láti dẹ́kun àkóràn ni láti dín pípọ̀si àwọn ẹ̀fọn aṣòkunfà kù. Ní àwọn àgbegbè tí ibà pọ́njú-pọ́ntọ̀ wọ́pọ̀si ti àjẹsára ó sì wọ́pọ̀, ìwádìí kíákíá tí àwọn ìṣẹlẹ̀ àti abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ará ìlú ni ó ṣe pàtàkì láti dẹ́kun àjàkálẹ̀ arùn. Nígbà tí ó bá tiní àkóràn, ìṣàkóso jẹ́ ti aláámì láìsi ìwọ̀n tí ó jáfáfá Kankan lòdì sí àkóràn náà. Lára àwọn tí ó ní àrùn líle, ikú maa ń wáyé lára àwọn ìdajì ènìyàn tí kògba ìtọjú.
Àrùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ ń ṣòkunfà àkoràn 200,000 àti ikú 30,000 lọ́dọọdún, pẹ̀lú bíi ìdá 90% ìṣẹlẹ̀ ní Áfíríkà. Bíi bílíọ́nù ènìyàn ni o ń gbé ní agbègbè àgbayé níbi tí àrùn náà ti wọ́pọ̀. Ó wọ́pọ̀ ní ibi oorùn àwọn agbègbè Gúúsù Amẹ́ríkà àti Áfíríkà, ṣùgbọ́n kìíṣe ní Áṣíà. Láti ọdún àwọn 1980, àwọn nọ́ńbà ìṣẹlẹ̀ àrùn pọ́njú-pọ́ntọ̀ ń pọ̀si. Èyí ń wáyé nítorí àwọn ènìyàn díẹ̀ tí wọ́n ń fún ní àjẹsára, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí o ń gbé ní ìlú, àwọn ènìyàn tí o ńlọ káakiŕi, àti ìyípadà afẹ́fẹ́. Àrùn yíì bẹ̀rẹ̀ ní Áfíríkà, níbi tí o ti tàn dé Gúúsù Amẹ́ríkà nípasẹ̀ òwò ẹrú ní 17 century. Láti 17 century , ọ̀pọ̀ gbòógì àjàkálẹ̀ ti àrùn náà wáyé ní àwọn Amẹ́ríkà, Áfíríkà, àti Yúrópù. Ní àwọn 18 àti 19 century, ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀ ni wọ́n rí bíi èyí tí ó léwu jùlọ àrùn àkóràn. Kòkòrò ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀ ni kòkòrò ènìyàn àkọkọ́ tí a kọ́kọ́ ṣàwarí.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ìbà pọ́njú-pọ́ntọ̀, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.