Ìjọba Ìbílẹ̀ jẹ́ ìpele ìjọba ẹlẹ́kẹta àti irúfẹ́ ìjọba tí ó jẹ́ ti àwa-ara-wa lẹ́sẹ̀ kùkú ti ó wà ní abẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lábẹ́ ìlànà ìṣèlú àwa-ara-wa.
Ìjọba ìbílẹ̀ ma ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ òfin àti àlàkalẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè bí àwọn aṣòfin (legistlatives) àti àwọn amòfin (Judiciary) ṣe gbe kalẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. Nínú ìlànà étò Ìjọba Àpapọ̀ (Federal State), ìjọba ìbílẹ̀ ló sába ma ń wà ní ipò kẹta nínú étò ìṣèlú.
Ẹ̀wẹ̀ àgbékalẹ̀ étò Ìjọba ìbílẹ̀ yàtọ̀ síra wọn ní orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní agbáyé.
Ìpínsísọ̀rí ìjọba lábẹ́ ìjọba apapọ̀ (Federal Government) lábẹ́ ìjọba àwa-ara-wa (Democrcy), ṣe pàtàkì. Ìlànà ìṣèlú lábẹ́ ìjọba Àpapọ̀ pín sí ọ̀nà Mèta.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ìjọba Ìbílẹ̀, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.