Raphael Nii Amaa Ollennu (tí a bí ní 21 May 1906, tí ó sì kú ní 22 December 1986) jẹ́ agbẹjẹ́rò àti adájọ́ tó dí adájọ́ àgbà fún Ilé-ẹjọ́ gíga jùlọ ní orílẹ̀-èdè Gánà láti ọdún 1962 sí 1966.
Òun sì ni Ààrẹ ilẹ̀ Ghánà nígbà ìjọba olómìna kejì, láti 7 August 1970 sí 31 August 1970 àti agbọ̀rọ̀sọ ní ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ti ìlú Ghana láti 1969 wọ 1972.
The Right Honourable Nii Amaa Ollennu Àdàkọ:Post-nominals | |
---|---|
Nii Amaa Ollennu | |
President of Ghana Acting Second Republic | |
In office 7 August 1970 – 31 August 1970 | |
Alákóso Àgbà | Dr. K.A. Busia |
Asíwájú | A.A. Afrifa |
Arọ́pò | Edward Akufo-Addo |
Speaker of the Parliament of Ghana Second Republic | |
In office 1 October 1969 – 12 January 1972 | |
Asíwájú | Kofi Asante Ofori-Atta (First Republic) |
Arọ́pò | Jacob Hackenburg Griffiths-Randolph Third Republic |
Justice of the Supreme Court of Ghana | |
In office 1 September 1962 – 1966 | |
Appointed by | Kwame Nkrumah |
Ààrẹ | Kwame Nkrumah |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Accra, Gold Coast | 21 Oṣù Kàrún 1906
Aláìsí | 22 December 1986 | (ọmọ ọdún 80)
Ọmọorílẹ̀-èdè | Ghanaian |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Emily Jiagge Charlotte Amy Sawyerr Nana Afua Frema (Queen-mother of Wenchi) |
Ẹbí |
|
Àwọn ọmọ | Amerley Ollennu (daughter) |
Education |
|
Profession |
|
Wọ́n bí Ollennu sí Labadi, ní ìlú Accra, ní ọdún1906, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn Ga. Àwọn òbi rẹ̀ ni Wilfred Kuma Ollennu àti Salomey Anerkai Mandin Abbey. Ollennu lọ sí ilé-ìwé Salem School ní ìlú Osu . Ó ka ẹ̀kọ́ girama níAccra High School. Lára ẹ̀kọ́ ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ rẹ̀ wá láti Presbyterian Training College ní Akropong, tó wà ní apá Ìlà-Oòrùn orílẹ̀-èdè Ghana, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ pedagogy àti theology. Ó lọ sí England láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ jurisprudence ní Middle Temple, London. Wọ́n sì pè é wọ ilé-ẹjọ́ ní ọdún 1940 lẹ́yìn tó fi oṣù méjìdínlógún kẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún mẹ́ta. Ó jáde pẹ̀lú èsì tó tayọ, èyí sì mu gba ìdánimọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ Queen.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Nii Amaa Ollennu, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.