Ọdẹ ni orúkọ tí a ń pe àwọn àkàndá ènìyàn kan tí wọ́n yan iṣẹ́ pípa ẹranko ìgbẹ́ ,dídẹ Odò, pípa ẹyẹ oríṣiríṣi lọ́pọ̀ ìgbà.
Ní àwùjọ Yorùbá láyé àtijọ́, Ọdẹ ṣiṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ abiyì láàrín tí ọ̀pọ̀ àwọn Òbí ma ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn ó kọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ àti iṣẹ́ òòjọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ Yorùbá, wípé iṣẹ́ ni oògùn ìṣẹ́, wọ́n ma ń pọọ́n ní dandan fún ara wọn láti ní iṣẹ́ lọ́wọ́. Ọdẹ ṣíṣe tún jẹ́ iṣẹ́ ìdílé àwọn ẹbí kan tí wọ́n si ma ń jẹ́ orúkọ tí ó jọ mọ́ iṣẹ́ yí. Wọn a máa jẹ́ Ọdẹ́jìnmí,Ọdẹ́wálé, Ọdẹ́gbèmí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀wẹ̀, àwọn Ọdẹ náà tún ma ń ṣọ́de òru léte àti dáàbò bo ìlú, ẹ̀mí, àti dúkìá pátá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ògbójú Ọdẹ ni wọ́n ma ń lọ sójú ogun láti dábò bo ìlú wọn.
Lára àwọn ọ̀nà tí iṣẹ́ Ọdẹ pin sí ni:
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ọdẹ, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.