Nathaniel Bassey

Àdàkọ:EngvarB

Pastor Nathaniel Bassey
Ọjọ́ìbíLagos, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Gospel musician
Notable work#HallelujahChallenge
Websitenathanielbassey.net

Nathaniel Bassey Ig-Nathaniel Bassey.ogg (Listen) jẹ́ olórin Nàìjíríà, olùdarí ìjọ, a-fọn-fèrè àti a-kọ-orin ẹ̀mí tí ó gbajú-gbajà fún àwọn orin rẹ̀ "Imela", "Oníṣẹ́ Ìyanu" àti "Ọlọ́wọ́gbọgbọrọ." Ó ń lọ The Redeemed Christian Church Of God, ó sì ń darí ìjọ The Oasis, Èkó, Ìjọ àwọn ọ̀dọ́ ti RCCG Kings Court ní VI,

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́.

Wọ́n bí Bassey ní Èkó, Nàìjíríà ní 1981. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa international relations and politics ní University of Lagos kí ó tó lọ sí London láti lọ kọ́ nípa ìṣèlú lẹ́yìn náà. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin ní ilé-ẹ̀kọ́ ìgbà ẹ̀rùn Middlesex University.

Iṣẹ́ orin

Nathaniel bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ rẹ̀ ní Ilé-ìjọsìn níbi tí ó ti dara pọ̀ mọ́ Rhodes Orchestra tí ó sì fun fèrè tírọ́ḿpẹ̀tì fún ọdún méjì. A-fọn-fèrè tírọ́ḿpẹ̀tì lásán ni tẹ́lẹ̀ títí di ìgbà tí ó ṣe àtinúdá orin níbi ìkíni sí Stella Obasanjo, ìyàwó olóògbé Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Olusegun Obasanjo. Ní 2018, Bassey jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oníṣẹ́-ọnà tí ó wà lókè ní àpéjọpọ̀ àwọn Kìrìsìtẹ́ẹ́nì Nàìjíríà - The Experience. Àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ Elohim ni wọ́n ṣe àgbàsílẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì sọ ọ́ di odindi ní Cape Town, South Africa ní ọdún 2008. Wọ́n ti ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i iṣẹ́ ẹ̀mí àti àràmàndà pẹ̀lú orin tí ó gbájú gbajà jù nínú rẹ̀, "someone's knocking at the door," orin tí ó ń lọ lẹ́sọ̀lẹ́sọ̀ tí àwọn ènìyàn sì ń nífẹ̀ẹ́ sí lọ́wọ́lọ́wọ́ nílé àti lókè òkun.

Nathaniel bẹ̀rẹ̀ #HallelujahChallenge ní June 2017, níbi tí òun àti àwọn onígbàgbọ́ mìíràn ti máa ń sin Ọlọ́run fún wákàtí kan, láti 12:00 am sí 1:00 am. Ó máa ń ṣe àfihàn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní ojú ìran Instagram, ó sì máa ń pe àwọn mìíràn láti dara pọ̀ mọ. Ní ó kéré sí oṣù kan, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ní ó pọ̀ ju ìwò 600,000 lọ. #HallelujahChallenge fún 2020 ni wọ́n ṣe láti 4 sí 24 February. Ní 2021, wọ́n ṣe challenge náà láti 1 sí 21 February.

Àwọn àwo tí ó ti ṣàgbéjáde rẹ̀

  • Someone's at the Door (2010)
  • The Son of God (& Imela) (2014)
  • This God is too Good (2016)
  • Revival Flames (2017)
  • Jesus: The Resurrection & the Life (2018)
  • The King is Coming (2019)
  • Hallelujah Again (Revelation 19:3) (2021)
  • Names of God (2022)

Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

KòkòròTuedon MorganDick Cheneyaue27DysprosiumLogicGrover ClevelandLeadHypertextASCIIJohn Carew EcclesItan Ijapa ati AjaLucie ŠafářováPotsdam12 DecemberÀrún èrànkòrónà ọdún 2019Niger (country)BitcoinGúúsù-Ìlàòrùn ÁsíàMarie LuvMarseilleSaint PetersburgOṣù Kínní 10Pataki oruko ninu ede YorubaPriscilla AbeyÀjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní ilẹ̀ NàìjíríàRita DominicAlfred NobelRita Williams(9981) 1995 BS3Orílẹ̀-èdè Olómìnira àwọn Ará ilẹ̀ ṢáínàÌpínlẹ̀ ÍmòPeter FatomilolaJulian ApostatAlifabeeti OduduwaMohamed ElBaradeiDodaFiẹtnámÀmì ọ̀pá àṣẹ ilẹ̀ Nọ́rwèyDVKalẹdóníà TuntunÀsà Ìgbéyàwó ní ilè YorùbáEukaryaOrílẹ̀ èdè AmericaWiki CommonsUSAMarcel ProustAdó-ÈkìtìCórdoba NikarágúàOgun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejìÀṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ YorùbáOṣù KínníAbẹ́òkútaChristian BaleNeanderthalISO 13406-2Mike EzuruonyeBaskin-RobbinsÌpínlẹ̀ ÒgùnGeorge Clinton (Igbákejì Ààrẹ)Ìpínlẹ̀ ÈkóEsther OnyenezideEukaryoteÀkójọ àwọn orílẹ̀-èdè Europe🡆 More