Pataki Oruko Ninu Ede Yoruba

PATAKI ORUKO NINU EDE YORUBA.

   Awon Yoruba ka oruko si pupopupo. Eranje l' o je fun won lati maa ro itumo oruko ti won ba gbo tabi ti won ba n lo. Oruko, ti eniyan tabi oja tabi ilu tabi adugbo ba n je, kun fun itumo pataki ti awon eniyan maa n ranti nigbakuugba. Ti isedale awon Yoruba la n wi yi o, ki i se ti aye d'aye oyinbo ti ede Geesi n so opolopo omo Yoruba di alaimokan nipa asa atayebaye ile wa. Eyin e yara wo awon oruko wonyi, oruko eniyan: Ayodele, Morenike, Ogundipe, Omiyale. Oruko abiso ni awon oruko wonyi, nipa won la si n powe pe; "ile l'a a wo  k'a too s'omo loruko".   Orisi oruko miran wa ti Yoruba n so omo won, eyi ni awon oruko amutorunwa to je pe itumo won dalori irufe ohun to sele nigba ti omo wa ninu oyun tabi nigba tomo naa jade lati inu iya a re. Bi apeere: Tayewo (eyi to saaju ninu awon ibeji); Ajayi (omo to doju dele nigba ti a bii gan-an); Ojo (omo to. we iwo morun nigba ti a bii); Jimoon (omo ti a bi lojo jimoon) ati bee bee lo.    Orisi oruko keta ni awon oriki soki ja si gan-an, sugbon o wopo ka paala laarin oruko gidi ati oriki. Idi eyi ni pe oro ajuwe ni oriki soki, oro t'o juwe iwa ati ise ati ara oloriki naa. Bi apeere: Akunyun-un (alakitiyan eniyan), Abeke (obinrin daradara ti a tile n be na ka too ke e), Ajeibon (ode atamatase). 

Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Iranian rialOrúkọ ìdíléIlẹ̀gẹ̀ẹ́sìÌpínlẹ̀ ÒgùnỌdẹẸlẹ́ẹ̀mín22 MayÒrò àyálò YorùbáIodineAdekunle GoldNáíráBangladẹ́shìBerneMackenzie BowellRepublican Party (United States)JerseyJulian ApostatTógòAṣọ ÀdìrẹỌjọ́ 25 Oṣù KẹrinISO/IEC 27000-seriesOṣù Kẹ̀sánWiki CommonsEsther OyemaUniform Resource LocatorPópù Alexander 2kSỌ̀rànmíyànAfghanístàn21 AugustOṣù KejeAuguste Beernaert.ncOrúkọ YorùbáVladimir Putin5 AugustEzra OlubiÈdè TháíIkọ́Tope AlabiÈdè FaranséDiamond JacksonCaliforniaIbadan Peoples Party (IPP)Maria NajjumaMary Akor12 DecemberGulf Pẹ́rsíàSikiru Ayinde BarristerOsorkonRKalẹdóníà TuntunNarendra Modi2 MayPópù Gregory 7kÀṣà Ìsọmọlórúkọ Nílẹ̀ YorùbáÒṣèlúAjah, LagosMẹ́rkúríù (pálánẹ́tì)3 NovemberYemojaÀgbáyéTiranaSantos AcostaAnatole FranceBárbádọ̀sVictoria University of Manchester19 AugustÀsà oge ṣíṣẹ́ ní ilè yorùbá🡆 More