Ìwọ́ ìtanná tabi ìwọ́ iná ni bi àdìjọ ìtanná se n sàn kiri.
Ẹyọ ìwọ̀n SI fun ìwọ́ iná ni ampere (A), to dọ́gba mọ́ sísàn kiri coulomb kan agbára iná ní ìsẹ́jú àáyá.
Iye ìwọ́ iná (ti a wọ̀n ní ampere) ti o n gba òdeojú (surface) kan kọ já ni iye agbára iná (ti a wọ̀n ní coulombs) ti o n sàn kiri l'òdeojú na láàrin àsìkò kan. Tí Q bá jẹ́ iye agbára iná tó kọ já l'òdeojú na láàrin àsìkò T, nípa bayi àriniye (average) ìwọ́ iná I jẹ́:
Tí a bá jẹ́ kí ìwọ̀n àsìkò T kí ó dín títí títí dé òdo, á nìí ìwọ́ iná ẹ̀kanáà (instantaneous) i(t) gẹ́gẹ́ bi:
Nínú àwọn wáyà onípánù (Agbéiná – electrical conductor) tí wón gba agbára iná láàyè, ogunlọ́gọ̀ àwon atanná (electron) ni wọ́n rìn kiri lọ́fẹ̀ẹ́lófòò (atanná ọ̀fẹ́). Àwọn atanná wọ̀nyí kò sopọ̀ mọ́ átọ́mù kankan.
Òfin Ohm n tọ́kasí ìbásepọ̀ tó wà láàrin ìgbanná (Voltage), ìwọ́ iná ati ìdinà iná (electrical resistance):
nígbàtí,
Àpẹrẹ ìwọ́ iná ti a le fojuri ni mọ̀nàmọ́ná (lightning) ati ìjì ojúòòrùn (solar wind). Bakana iwo ina ti a mọ̀ ni sisan atanna ninu okùn onírin, fun apere awon waya opo ina to n gbe ina lati ibikan de ibo miran ati awon waya kekeke ninu awon ero onina (electronics), ati bi atanna se n san koja ninu adena ina (resistor), sisan kiri ioni (ion) ninu bátìrì (battery) ati sisan kiri iho ninu agbeinadie (semiconductor).
Ìwọ́ iná n pese pápá gbéringbérin (magnetic field). A le wo papa gberigberin bii ọ̀pọ̀ ìlà to yi waya po.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ìwọ́ ìtanná, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.