Folashade Tolúlọpẹ́ Ògúnṣọlá ẹni tí wọ́n bí ní ọdún 1958 jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ Medical Microbiology, òun sì ni Alákòóso àgbà fún ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásítì ìlú Èkó lásìkò tí a ń kọ àpilẹ̀kọ yí.
Ó jẹ́ onímọ̀ nípa bí a ń kojú àrùn pàá pàá jùlọ kòkòrò àrùnHIV/AIDs. Ògúnṣọla ti kọ́kọ́ di ipò Alákòóso agbà (Provosti) ti ilé-ẹ̀kọ́ imọ̀ ìṣègùn oyinbo ti (College of Medicine) ti Yunifásitì ìlú Eko mú rí, òun sì ni obìnrin akọ́kọ́ tí o kọ́kó di ipò náà mú. Ó tún wà lára àwọn ígbákejì adarí ti Yunifásitì náà, ipò ti o di mú láàrín ọdún 2017 sí ọdún 2021. A fi si adilemu ipò adari Yunifásitì ìpínlè Èkó ni ojo kerinlelogun osu Kejo(24 August) odun 2020) léyìn igba ti won yo Òjògbón Oluwatoyin Ogundipe ni ipò adari ilé-ìwé náà. Ni ojo keje osu kewa(7 Oct 2022), a yan Ogunshola gégé bi adari ilé-ìwé náà, oun si ni obinrin àkókó ti o di ipò náà mu.
Folasade Ogunsola | |
---|---|
Adarí kẹtàlá Yunifásitì ìlú Èkó | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 12 November 2022 | |
Asíwájú | Oluwatoyin Ogundipe |
Deputy Vice Chancellor (Development Services), University of Lagos | |
In office 2017–2021 | |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Folasade Tolulope Mabogunje 1958 (ọmọ ọdún 65–66) |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Alma mater | College of Medicine, Unilag (Masters in Medical microbiology) College of Medicine, University of Wales, Cardiff (Doctor of Philosophy in Medical microbiology) |
Wọ́n tọ́ Ògúnṣọlá dàgbà nínú ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì ìlú Ibadan níbi tí bàbá rè, Akin Maábògùnjẹ́ ti jẹ́ olùkọ́. Nígba ti ó wà ni omodé, o ma ń ṣe bi àwọn onímò òyìnbó pẹ́lú bí ó ṣe ma ń fi àwọn bèbí ìṣeré ọmọdé ṣeré, tí ó sì ma ń ṣe bí ẹni wípé òun ń ṣe itọ́jú wọn.
Ó lo ilé-ìwé Queen's College, ìpinlè Èkó. Ni arin odún 1974 si odun 1982, o gbà àmì-èye àkókó rè ni Yunifásitì ìlú Ifè ati àmì-èye Master degree rè ní College of Medicine ti yunifásitì ìlú Eko, o si tún tesiwaju láti gba àmì-èye doctorate rè ni Yunifásitì ìlú Wales larin odun 1992 si 1997.
A yan Ogunshola láti se adilemu ipò adari yunifásitì ìpinlè Eko fun ìgbà dí è ni odun 2020 nígbà ti wahala be sile ni ilé-ìwé náà nitori pé awon alaga ilé-ìwé náà yo adari rè. Ó tun wa lára awon ígbákejì adari ilé-ìwé náà, ki o to di pé o di adilemu ipo adari rè.. Kí ó tó dé ipò òkan lara àwon ígbákejì adari ilé-ìwé náà, óun ni provosti ilé-ìwé ìmò òyìnbó(College of Medicine).
Awon iwádí re wa lori bi a ti ún koju àwon àárun ti Virusi fa. Oun ni oludari awadi àjo AIDS Prevention Initiative in Nigeria(APIN) ni Yunifásitì ìlú Eko, oun tun ni alaga àjo Infection Control Committee ti Teaching Hospital ìpinlè Eko(LUTH). Ogunshola tun jé alaga National Association of Colleges of Medicine in Nigeria.
Ni odun 2018, o soro lori ero rè nípa kíkojú aarun ni Nàìjíríà. O ni aini imototo àti ilo ogun Antibiotics ju botiye lo wa lara idi ti ògùn apa àárun o fi ka àwon kokoro to un fa aàrùn mó. O wà lara omo egbé àkókò ti egbé Nigerian Society for Infection control ní odun 1998 o si wa lara àwon omo egbé Global Infection Prevention and Control Network.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Folasade Ogunsola, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.