Eto Eko Ni Orile-Ede Naijiria

Àdàkọ:Infobox Education Ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ó wà ní abẹ̀ ̀akóso aj̀ọ tí ó ń rísí ètò-èkó ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti a mọ sí Federal Ministry of Education.

Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń ṣe ìmúṣẹ àgbékalẹ̀ ìlànà ètò-ẹ̀kó tí ìjọba ìpínlẹ̀ wọn bá gbé kalẹ̀ fún lílò ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ àti ti gbogbo-gbòò . Ìlànà ìkọ́ni ní orílè-èdè Nàìjíríà pín sí ọ̀nà mẹ́ta. Àkọ́kọ́ ni ilé-ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmin, èkejì ni ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ẹ̀kẹta ni ilé-ẹ̀kọ́ girama, nígbà tí ẹ̀kẹrin jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ àgbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìjọba ni ó ń ṣ'àkóso ètò ẹ̀kọ́, àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba gbogbo ni wọn kò fi bẹ́ẹ̀ dúró ṣinṣin láti ìgbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti gba òmìnira kúrò lọ́wọ̀ àwọn gẹ̀ẹ́sì bìrìtìkó, síbẹ̀, ètò ẹ̀kọ́ kárí-ayé tí ò gúnmọ́ kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ìgbà náà wá. Oríṣiríṣi ìyàtọ̀ ni ó wà nìnú ìlànà àtẹ ètò-ẹ̀kọ́, tí owó níná sì ètò ẹ̀kọ́ náà sì tún ń ṣ'àkóóbá fun pẹ̀lú. Lọwọlọwọ bayi, orilẹ-eded Naigiria ni o ni awọn ọmọ ti wọn ko si ni ile-ẹkọ julọ ni orile agbaye. Oríṣi ilé-ẹ̀kọ́ méjì ni ó wà ní orìlẹ̀-èdè Nàìjíríà, àkọ́kọ́ ni ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba, èkejì ni ilé ẹ̀kọ́ aládàáni Ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n ma ń fi èdè gẹ̀ẹ́sì ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, ní ọgbọ̀nọjọ́ oṣù kọkànlá ọdún 2022 ni mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, ọ̀gbẹ́ni Adamu Adamu kéde wípe ìjọba ń gbèrò láti dẹ́kun lílo èdè gẹ̀ẹ́sì fún ìgbèkọ́ ní àwọn ilé-èkọ́ aĺakọ̀ọ́bẹ̀rẹ ̀gbogbo kí wọ́n sì fi èdè abínibí tí wón bá ń ṣàmúlò rẹ̀ ní agbègbè tí ilé-ẹ̀kọ́ náà bá wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjírìà.

Eto Eko Ni Orile-Ede Naijiria
Students at a public school in Kwara State

Ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀

Eto Eko Ni Orile-Ede Naijiria 
Nigeria Primary School Enrolment by state in 2013

Ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí ọmọ bá ti pé ọdún márùnún fún àwọn èwe ọmọ orílẹ̀-èdè Nàijírià. Akẹ́kọ̀ọ́ yóò lo ọdún mẹ́fà nì ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọn yóò sì gba ìwé-ẹ̀rí moṣe tán álákọ̀ọ́kọ́. Akẹ́kọ̀ọ́ yóò ̀ti kọ́ nípa àwọn ìmọ̀ bíi ẹ̀kọ́ ìṣirò, èdè, èkọ́ ẹ̀sìn, èkọ́ ọ̀gbìn, ẹ̀kọ́ ìtọ́jú ara, ilé àti àwùjọ, àti ìkan nínú àwọn ède tí ó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ile-ekọ aladani naa ma n kọ awọn akẹkọọ wọn ni awọn imọ bii: Computer Science, Faranse ati ẹkọ imọ ọnà. O di dandan ki awọn akẹkọọ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ó ṣe ìdánwò àpapọ̀ gbogbo gbòò tí wọ́n ń pè ní Common Entrance Examination kí wọ́n lè pegedé láti wọ ilé-ẹ̀kọ́ girama ti ìjọba àpapọ̀ tàbí ti ìjọba ìpínl̀ẹ tí ó fi mó ilé-ẹ̀kọ́ girama aládani. Ṣáájú ọdún 1976, ìlànà ètò ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Nìàjíríà ni ó wà ní ìbámu bí àwọn amúnisìn gẹ̀ẹ́sì ṣe gbe kalẹ̀ lásìkò wọn. Ní ọdún 1967 ni wọ́n dá ìlànà ètò ẹ̀kọ́ Universal Primary Education sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Oríṣiríṣi ìpènijà ni ìlànà ètò ẹ̀kọ́ yí kojú, lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n ṣe àtúngbéyẹ̀wò rẹ̀ ní ọdún 1981 àti ọdún 1990 Wọ́n tún dá ìlànà ètò ẹ̀kọ́ Universal Basic Education (UBE) kalẹ̀ ní ọdún 1999 ìlànà ètò ẹ́kọ́ tí ó rọ́pò èyí tí wọ́n ṣ'àgbèyẹ̀wò rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ''Universal Primary Education'', èyí ni wọ́n gbé kalẹ̀ pẹ̀lú èrò ẃipé kí ó ṣúgbàá ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àwọn èwe fún ọdún mẹ́sànán àkọ́kọ́ Ìlànà ètò ẹ̀kọ́ UBE yí ni wọ́n pín sí ọ̀nà méjì, àkẹ́kọ̀ọ́ èwe yóò lo ọdún mẹ́fà àkọ̀kọ́ nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, nígbà tí wọ́n yóò lo ọdún mẹ́ta t'ókù ní ìpele àkọ́kọ́ ní ilè-ẹ̀kọ́ girama , èyí yóò sì jẹ́ kí ẹ̀kọ́ wọn ó dán mọ́ràn fùn ọdùn mẹ́sànàn gbáko pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń yí láti iyàrá ìgbẹ̀kọ́ kan sí òmíràn fún ọdún mẹ́sànán. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà si nínú ẹ̀kọ́ wọn ni àwọn olùkọ́ yóò ma ṣe àgbéyẹ̀wò ìmọ̀ wọn nípele sí ìpele. Ìlànà ètò ẹ̀kọ́ yí ni ó ń pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ pátá. Àjọ Universal Basic Education Commission, UBEC, ni ó ń ṣe agbátẹrù àti àbójútó fún ìlànà ètò ẹ̀kọ́ náà. Fúndí èyí, wọ́n júwe ìlànà ètò ẹ̀kọ́ UBE gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tó àwọn èwe sí ìmò àti ẹ̀kọ́ lábẹ́ òfin UBEC , ẹsẹ̀ kẹẹ̀ẹ́dógún.

Àwọn ìtókasí

Tags:

Federal Ministry of EducationNàìjíríàOwóỌmọ

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Pópù Celestine 3kIyipada oju-ọjọ ni AmẹrikaToyotaApáìwọ̀òrùn EuropeJohn WayneSwídìnWilly BrandtOrin hip hopPópù Alexander 7kFrédéric ChopinGeorge CarlinMájẹ̀mú TitunNeroUsherOwe YorubaMona BarthelSebastián PiñeraKate Winslet22 OctoberSukarnoBob MarleyÀàrẹ ilẹ̀ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkàJoseph StalinCentral Intelligence AgencyYunyOrílẹ̀-èdè Olómìnira Sófìẹ̀tì Sósíálístì ti Ukraine28 MarchIndonésíàLọndọnuBeyoncé KnowlesAfrican AmericanJesse Jackson, Jr.Àkójọ àwọn Gómìnà Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltàAkanlo-edeISBNFrench PolynesiaDẹ́nmárkìPete EdochieLos Angeles LakersWoody AllenDavid CameronAngela MerkelÌwà ÀjẹbánuLúksẹ́mbọ̀rg21 LutetiaAlbert EinsteinÀjọ tí ó ń mójú tó ońjẹ àti oògùn ti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkàNorth AmericaRoséPataki oruko ninu ede YorubaWiki CommonsDonald TrumpAlan TuringPakístànẸ̀bùn PulitzerDram ArméníàÌwọòrùn ÁfíríkàDalasiNiels BohrÀwọn Ìdíje Òlímpíkì Ìgbà Oru 1924Collectivity of Saint MartinBobriskyHawaiiÀwọn ọmọ Áfíríkà Amẹ́ríkàÀmì ọ̀pá àṣẹ ilẹ̀ IndonésíàSocratesIlẹ̀ ọbalúayéÀṣà Ìsọmọlórúkọ Nílẹ̀ YorùbáRárà🡆 More