Pete Edochie

Oloye Pete Edochie, MON (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1947) jẹ́ àgbà-ọ̀jẹ̀, gbajúmọ̀ àti ìlúmọ̀ọ́kà òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ ẹ̀yà Ìgbò láti ìpínlẹ̀ Anambra, lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Sinimá àgbéléwò lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Ìgbò ló ti ń kópa. Wọ́n kà á sí àgbà òṣèré sinimá-àgbéléwò tó lẹ́bùn eré sinimá ṣíṣe jùlọ nílẹ̀ adúláwọ̀ Áfíríkà. Èyí hànde látàrí onírúurú àmìn ẹ̀yẹ tí ó ti gbà gẹ́gẹ́ bí òṣèré sinimá àgbéléwò, pàápàá jùlọ àmìn ẹ̀yẹ láti ọwọ́ African Magic àti Africa Film Academy. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akọ̀ṣẹ́mọṣẹ́ olùṣàkóso àti gbajúgbajà agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni, ó di ìlúmọ̀ọ́kà òṣèré lọ́dún 1980 nígbà tí ó kópa gẹ́gẹ́ bí olú-ẹ̀dá ìtàn tí wọ́n pè ní Okonkwo nínú ìwé ìtàn àròsọ kan, Things Fall Apart tí àgbà-ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé, Chinua Achebe kọ, tí wọ́n sọ di eré àgbéléwò orí ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n NTA tó gbajúmọ̀ jùlọ nígbà náà. Gbajúmọ̀ Edochie pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ààrẹ àná, Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ fi dá a lọlá pẹ̀lú àmìn ẹ̀yẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Member of the Order of the Niger, MON lọ́dún 2003. Pete Edochie jẹ́ ọmọ ìjọ àgùdà.

Pete Edochie
Pete Edochie
Ọjọ́ìbíỌjọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1947
Ọmọ orílẹ̀-èdèNaijiria
Iṣẹ́Actor
Notable workFair Game (2006)

Ìgbà èwe rẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n bí Pete Edochie ní Ọjọ́ keje oṣù kẹta ọdún 1947. Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Anambra ni ṣùgbọ́n Zaria, ní ìpínlẹ̀ Kaduna ló ti ṣe kékeré rẹ̀ dàgbà. Ó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ní St. Patrick and James Primary School, Zaria, kí ó tó tẹ̀ síwájú ní St. John's College fún Ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀, lẹ́yìn èyí ló sí orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì fún ìtẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó sìn kàwé gboyè nínú ìmọ̀ ìwé-ìròyìn àti ìgbóhùnsáfẹ̀fẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ó ṣíṣe ní ilé iṣẹ́ ìjọba tó ń rí sí ọkọ̀ ojú-irin kí ó tó dára pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ Nigeria Television Authority, NTA lọ́dún 1967 nígbà tó wà lọ́mọ ogún ọdún. Kò pẹ́ nídìí iṣẹ́ púpọ̀ kí ó tó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ tíátà.

Àtòjọ àwọn sinimá àgbéléwò tó ti kópa

  • Lionheart (2018)
  • Mummy Why (2016)
  • Heavy Battle (2008)
  • Test Your Heart (2008)
  • Greatest Harvest (2007)
  • Secret Pain (2007)
  • Fair Game (2006)
  • Holy Cross (2006)
  • Lacrima (2006)
  • Living with Death (2006) .... Mr. Harrison
  • Passage of Kings (2006)
  • Simple Baby (2006)
  • Zoza (2006)
  • Azima (2005)
  • Baby Girl (2005)
  • End of Money (2005)
  • Living in Tears (2005)
  • Never End (2005)
  • No More War (2005)
  • Ola... the Morning Sun (2005)
  • Price of Ignorance (2005)
  • The Price of Love: Life Is Beautiful (2005)
  • Sacred Tradition (2005)
  • The Tyrant (2005)
  • Across the Niger (2004)
  • Coronation (2004)
  • Dogs Meeting (2004) .... Anacho
  • Dons in Abuja (2004)
  • The Heart of Man (2004)
  • King of the Jungle (2004)
  • Love from Above (2004)
  • My Desire (2004)
  • Negative Influence (2004)
  • The Staff of Odo (2004)
  • St. Michael (2004)
  • Above Death: In God We Trust (2003)
  • Arrows (2003)
  • Billionaire Club (2003)
  • Egg of Life (2003)
  • Honey (2003)
  • Love & Politics (2003)
  • Miserable Wealth (2003)
  • The Omega (2003)
  • Onunaeyi: Seeds of Bondage (2003)
  • Rejected Son (2003)
  • Selfish Desire (2003)
  • Super Love (2003)
  • Tears in the Sun (2003)
  • Tunnel of Love (2003)
  • When God Says Yes (2003)
  • Battle Line (2002)
  • My Love (2002)
  • Tears & Sorrows (2002)
  • Greedy Genius (2001)
  • Holy Ghost Fire (2001)
  • Terrible Sin (2001)
  • Oduduwa (2000)
  • Set-Up (2000)
  • Chain Reaction (1999)
  • Lost Kingdom (1999)
  • Narrow Escape (1999)
  • Living in Darkness (1999)
  • Rituals (1997)
  • Things Fall Apart (1987), TV series
  • Last Ofalla
  • Lion throne
  • Lion of Africa
  • Igodo
  • Evil men
  • Monkey chop banana
  • Idemili
  • 50 days with Christ
  • The Egg

Àwọn Ìtọ́kasí

Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

CETEP City UniversityKòréà ÀríwáShehu Abdul RahmanMarc FleurbaeyDélé Mọ́mọ́dùMasẹdóníà ÀríwáÍsráẹ́lìÁrktìkìÁljẹ́brà onígbọrọZincNobel PrizeỌ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá)Kọ̀mpútàLebanon18946 MassarÈdè PólándìFile Transfer ProtocolLere PaimoISO 31-10ÀwùjọChika OduahWikipediaPolonium.tcOlusegun Olutoyin AgangaMalek JaziriFàdákàolómiRuth KadiriOlúṣẹ́gun Ọbásanjọ́Èdè HébérùÌjàmbá ìtúká ẹ̀búté Bèírùtù ọdún 2020Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan Brítánì Olókìkí àti Írẹ́lándìÀsìkòÌwọòrùn ÁsíàOṣù KejìÀwọn Ìpínlẹ̀ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà2 SeptemberISO 3166MemphisGúúsù Amẹ́ríkà15 NovemberAustrálíàJ. K. AmalouÀwọn Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ NàìjíríàÀjàkáyé-àrùn èrànkòrónà ọdún 2019-2020Necmettin ErbakanBostonBill ClintonISO 128Emmanuel AmunikeÈdè BùlgáríàApágúúsù ÁfríkàIlú-ọba Ọ̀yọ́James CagneyRwandaEzra OlubiÌlú KuwaitiNàìjíríàFrank SinatraBama, NàìjíríàChristopher ColumbusWaterGregor MendelLev Bùlgáríà🡆 More