Dorothy Malone: Òṣèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè America

Dorothy Malone (tí a bí Mary Dorothy Maloney; ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lọ́gbọ̀n, oṣù kìíní, ọdún 1924 sí ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lógún, oṣù kìíní, ọdún 2018) jẹ́ òṣèré ará Ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan.

Iṣẹ́ ìṣe fíìmù rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1943, àti ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ó ṣe àwọn ipá kékeré, ní pàtàkì jùlọ ní àwọn B-movies, pẹ̀lú èrò láti gba ipa àtìlẹ́yìn ní The Big Sleep (ní ọdún 1946). Lẹ́hìn ọdún mẹ́wàá, ó yí àwòrán rẹ̀ padà, pàápàá lẹ́hìn ipa rẹ̀ ní Written on the Wind (ní ọdún 1956), fún èyítí ó gba Oscar fún Òṣèré Àtìlẹ́yìn tí ó dára jùlọ. Iṣẹ́ rẹ̀ dé ipò gíga rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960, àti pé ó padà ṣe àṣeyọrí pẹ̀lú ipa tẹlifísàn rẹ̀ bíi Constance MacKenzie lórí Peyton Place (ọdún 1964 sí ọdún 1968). Kò fi bẹ́ẹ̀ dángájíá tó ní eré ṣíṣe ní àwọn ọdún ìyóókù, ìkẹhìn ìfarahàn ìbojú ìwòrán ti Malone wáyé ní Basic Instinct ní ọdún 1992.

Dorothy Malone
Dorothy Malone: Òṣèré Ọmọ Orílẹ̀-èdè America
Dorothy Malone in 1963
Ọjọ́ìbíMary Dorothy Maloney
(1924-01-29)Oṣù Kínní 29, 1924
Chicago, Illinois, U.S.
AláìsíJanuary 19, 2018(2018-01-19) (ọmọ ọdún 93)
Dallas, Texas, U.S.
Iléẹ̀kọ́ gígaSouthern Methodist University
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1943–1992
Olólùfẹ́
Jacques Bergerac
(m. 1959; div. 1964)

Robert Tomarkin
(m. 1969; annul. 1969)

Charles Huston Bell
(m. 1971; div. 1973)
Àwọn ọmọ2
Àwọn olùbátanRobert B. Maloney (brother)

Malone kú ní ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lógún, oṣù kìíní, ọdún 2018. Ó ti jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìràwọ̀ tí ó kú kẹhìn láti Golden Age of Hollywood.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀

Wọ́n bí Malone Mary Dorothy Maloney ní ọjọ́ ọ̀kàn-dín-lọ́gbọ̀n, oṣù kìíní, ọdún 1924 ní Chicago, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ márùn-ùn tí Esther Emma “Eloise” Smith bí àti ọkọ rẹ̀ Robert Ignatius Maloney, olùyẹ́wò fún ilé-iṣẹ́ AT&T . Nígbàtí ó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́fà, ìdílé rẹ̀ kó lọ sí Dallas, Texas. Níbẹ̀ ni ó ṣe àpẹẹrẹ fún Neiman Marcus ó sì lọ sí Ursuline Academy of Dallas, Highland Park High School, Hockaday Junior College, ati Fásìtì Southern Methodist tí a mọ̀ sí Southern Methodist University (SMU) lẹ́hìn náà. Lákọ̀ọ́kọ́ ó ronú láti di nọ́ọ́sì. Ní àkókò tí ó ń ṣeré kan ní SMU, síkáótù tálẹ́ńtì kan Eddie Rubin rí i, tí ó tí ń wá láti wá òṣèré ọkùnrin kan.

Ayé Rẹ̀

Malone jẹ́ Dìmókírátì, ó sì ṣe ìpolongo fún Adlai Stevenson ní àkókò ìdìbò ààrẹ ní ọdún 1952. Malone, Roman Catholic kan, ṣe ìgbéyàwó òṣèré Jacques Bergerac ní Oṣù Kẹfà ọjọ́ èjì-dín-lọ́gbọ̀n, ọdún 1959, ní ilé ìjọsìn Kátólìkì kan ní Ilẹ̀ Hong Kong, níbití ó wà lórí ipò fún fíìmù 1960 rẹ̀ "The Last Voyage". Wọ́n ní ọmọbìnrin méjì, Mimi (tí a bí ní ọdún 1960) àti Diane (tí a bí ní ọdún 1962), kí wọ́n tó wá kọ ara wọn sílẹ̀ ní oṣù kejìlá, ọjọ́ kẹjọ, ọdún 1964. Malone lẹ́hìn náà ṣe ìgbéyàwó sí oníṣòwò àti alágbàtà New York kan, Robert Tomarkin ní oṣù kẹrin ọjọ́ kẹta, ọdún 1969, ní Silver Bells Wedding Chapel ní Las Vegas, Nevada. Ìgbéyàwó kejì rẹ̀ ti wá fagile lẹ́hìn tí Malone sọ pé Tomarkin fẹ́ òun nítorí owó rẹ̀.

Malone ṣe ìgbéyàwó sí olórí Dallas motel chain, Charles Huston Bell ní oṣù kẹwàá ọjọ́ kejì, ọdún 1971, wọ́n sì kọ́ ara wọn sílẹ̀ lẹ́hìn ọdún mẹ́ta. Ní nǹkan bí ọdún 1971, Malone gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ láti Southern California lọ sí suburban Dallas, ní Texas, níbití ó ti dàgbà.


Àwọn Ìtọ́ka Sí

Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

KarachiÀjàkáyé-àrùn èrànkòrónà ọdún 2019-2020ISO 3103Orúkọ YorùbáỌbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀.idOgun Abele NigeriaDavid CameronHungaryOgedengbe of IlesaAberdeen2434 BatesonDNA9 OctoberIṣẹ́ẹ̀rọ onítannáKuwaitCyril Norman HinshelwoodRené DescartesDjìbútìTope AlabiBratislavaWikisourceWasiu Alabi PasumaSQL25 MarchFrançois DuvalierOgun Gulf Pẹ́rsíàKọ̀nkọ̀KàsínòPalestineIsraelMongolia (country)SARS-CoV-2TallinnISO 86012655 GuangxiEpoPonna.nuOlikoye Ransome-Kuti.auNàìjíríàHọ́ng KọngThe NetherlandsMargaret ThatcherISO 3166-3FáráòISO/IEC 14443Richard NixonTurkeyKùránìSebastián PiñeraISO 3166-1 alpha-2StockholmSpainZagrebAyo AdesanyaKen Saro-WiwaMandy PatinkinTitun Mẹ́ksíkòÌtàn ilẹ̀ MòrókòISO 31662120 TyumeniaRọ́síàÀmìọ̀rọ̀ ANSI escapeISO 128Faithia BalogunÀtòjọ àwọn orílẹ̀-èdè Olómìnira àgbáyé🡆 More