Oluwatoyosi Ogunseye: Oníwé-Ìròyín

Olúwatóyọ̀sí Ògúnṣẹ̀yẹ tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ akọ̀ròyìn, aṣàtúnkọ àti àyẹ̀wò àkọsílẹ̀, àti adarí iṣẹ́ tó rí sí èdè ti West Africa ní BBC World Service.

Ó jẹ́ aṣàtúnkọ ìwé-ìròyìn The Punch Newspaper nígbà kan rí. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Mandela Washington Fellow.

Oluwatoyosi Ogunseye
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Editor
Journalist
EmployerPunch Newspaper

Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni a bí Ògúnṣẹ̀yẹ sí, sí ẹ̀yà Yorùbá. University of Lagos ni ó ti gboyè Bachelor's degree nínú Biochemistry, lẹ́yìn náà ni ó gboyè Post-graduate diploma nínú Print Journalism ní Nigerian Institute of Journalism. Ní ọdún 2010, ó gboyè masters degree nínú Media and Communications ní Pan-Atlantic University. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní University of Leicester, United Kingdom láti gboyè PhD nínú Politics and International Relations.

Iṣẹ́ tó yàn láàyò

Ògúnṣẹ̀yẹ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ akọ̀ròyìn látìgbà tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún kejì ní University of Lagos tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Biochemistry. Musa Egbemana ló tọ sọ́nà bí wọ́n ṣe ń ṣàkọsílẹ̀ ìròyìn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní University of Lagos tí wọ́n máa ṣàgbéjáde lórí ìwé-ìròyìn The Sun Newspaper nígbà tí Femi Adesina jẹ́ aṣàtúnkọ ìròyìn ní ọdún 2004. Lẹ́yìn náà ni ó lọ sí News Star Newspaper gẹ́gẹ́ bíi senior correspondent ní ọdún 2007. Ní ọdún 2009, ó dára pọ̀ mọ́ The Punch Newspaper gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ aṣàtúnkọ ìròyìn àti ìròyìn lórí òṣèlú títí di ọdún 2012. Tóyọ̀sí ti jẹ́ akọ̀ròyìn láti ọdún 2006 kí ó tó di aṣàtúnkọ ìròyìn. Ó ṣiṣẹ́ fún Sunday Punch gẹ́gẹ́ bíi aṣàtúnkọ ìròyìn àti senior correspondent tó ń ṣiṣẹ́ lórí ìwà ọ̀bàyéjẹ́ nílẹ̀ wa àti lágbàáyé. Tóyọ̀sí ni aṣàtúnkọ ìròyìn àkọ́kọ́ tó jẹ́ obìnrin àti ẹni tó kéré jù lọ ní The Punch Newspaper.

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

Ògúnṣẹ̀yẹ ti gba àmì-ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi tó ń lọ bíi márùn-úndínlọ́gbọ̀n. Díẹ̀ lára àwọn àmì-ẹ̀yẹ náà ni: CNN Multichoice African Journalists of the year ní ọdún 2011 àti 2013, Nigerian Academy of Science Journalists of the year ní ọdún 2013, The Future Awards ní ọdún 2013, Child Friendly Reporter of the year

Àwọn Ìtọ́kasí

Tags:

Oluwatoyosi Ogunseye Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀Oluwatoyosi Ogunseye Iṣẹ́ tó yàn láàyòOluwatoyosi Ogunseye Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀Oluwatoyosi Ogunseye Àwọn Ìtọ́kasíOluwatoyosi OgunseyeThe Punch

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Nàìjíríà10 JulyPakístànLèsóthòNamibia23 AugustEconomicsUttar PradeshIronCleopatraẸ̀sìn IslamDonald TuskEminemAma Ata AidooNecmettin ErbakanMercedes McCambridgeAminu Ado BayeroSobekneferuDiadumenian1168 BrandiaAdolf Hitler22 March7 OctoberIlé-Ifẹ̀YorùbáÀtòjọ àwọn Ààrẹ ilẹ̀ RùwándàAjáÀsà oge ṣíṣẹ́ ní ilè yorùbáNkiru OkosiemeÌmọ̀ Ẹ̀rọPrologSlofákíàÀgbékalẹ̀ Ẹ̀kọ́OkpokoLagos StateYunifásítì Harvard15 November.soIndonésíàẸkùnOgunISO 4217StuttgartBẹ̀lárùsÒrùnDélé Mọ́mọ́dùÀsìkòÀṢÀ ÌKÍNI NÍ ÀWÙJỌ YORÙBÁAbidjan.naOSI modelFaithia BalogunYinusa Ogundipe Arapasowu INew Zealand.egÌgbà EléèédúÀmìọ̀rọ̀ QROṣù KejeTheodor HeussMavin RecordsFestus KeyamoISO 8601🡆 More