Anandibai Gopalrao Joshi (tí wọ́n bí ní 31 March 1865 tó sì kú ní 26 February 1887) jẹ́ dọ́kítàbìnrin àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ India.
Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó wá láti Bombay presidency ti ìlú India láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ètò ìṣẹ̀gùn ti ìgbàlódé ní United States. Orúkọ mìíràn tí wọ́n máa ń pè é ni Anandibai Joshi àti Anandi Gopal Joshi (níbi tí Gopal jẹ́ àgékúrú orúkọ ọkọ rẹ̀, ìyẹn Gopalrao.
Orúkọ àbísọ rẹ̀ ni Yamuna, inú ìdílé Marathi Chitpavan Brahmin ni wọ́n sì bí Joshi sí. Gẹ́gẹ́ bí àṣà ìlú wọn, àwọn òbí rẹ̀ fún fọ́kọ nígbà tó wà ní ọmọdún mẹ́sàn-án. Gopalrao Joshi, tó jẹ́ opókùnrin, tó sì fi ogún ọdún jù ú lọ ni wọ́n fẹ́ ẹ fún. Lẹ́yìn ìgbéyàwó rẹ̀, ọkọ rẹ̀ sọ orúkọ rẹ̀ di 'Anandi'. Gopalrao Joshi ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé ní Kalyan. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé e lọ Alibag, kí ó ṣẹ̀ tó wá lọ Kolhapoor (Kolhapur). Ó jẹ́ aláròjinlẹ̀ onítẹ̀síwájú, tí ó sì fọwọ́ sí kí obìnrin kàwé.
Ní ọmọdún mẹ́rìnlá, Anandibai bímọ ọkùnrin, àmọ́ ọmọ náà lo ọjọ́ mẹ́wàá péré nítorí àìrítọ̀ọ́jú ìwòsàn tó péye. Èyí sì ló yí ayé Anandi padà, tó sì fún un ní ìwúrí láti di oníṣègùn. Kò pé ní ọkọ rẹ̀ fi sí ilé-ẹ̀kọ́, kí wọ́n tó wá kó lọ Calcutta. Ibẹ̀ ló ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ èdè Sanskrit àti èdè Gẹ̀ẹ́sì.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Anandi Gopal Joshi, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.