Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ìgbóhùngbáwòrán Sáfẹ́fẹ́ Tẹlifísàn Ní Nàìjíríà

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbóhùngbáwòrán sáfẹ́fẹ́ lè jẹ́ ìtòpasẹ̀ padà sí ìparí àwọn ọdún 1950 nígbàtí Western Region tẹ́lẹ̀ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìfihàn tẹlifísàn àkọ́kọ́ ti Nàìjíríà.

Ní déédé ọdún 1959 ti sàmì ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésáfẹ́fẹ́ tẹlifísàn ní Nàìjíríà pẹ̀lú Western Nigeria Television gẹ́gẹ́ bí ilé-iṣẹ́ tẹlifísàn àkọ́kọ́ tí a ṣètò ní orílẹ̀-èdè náà.

Ìtàn

Pẹ̀lú ète pípèsè ọ̀nà fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ ẹkùn tí kò ní òṣìṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó péye, Western Region tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ dá ilé iṣẹ́ Western Nigerian Television sílẹ̀. Ní àtẹ̀lé àwọn ipasẹ̀ ti ìjọba Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn, ìjọba Agbègbè Ìlà Oòrùn ṣètò ìgbésáfẹ́fẹ́ tẹlifísàn rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu àkọ́kọ́ ti ìgbéga ètò ẹ̀kọ́ déédé láàrín àṣẹ rẹ̀. Ní báyìí, ètò ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí a sọ ni a ṣẹ̀dá ní ọdún 1960. Ní ọdún méjì nìkan lẹ́hìn ìgbésẹ̀ nípasẹ̀ ìjọba Agbègbè Ìlà Oòrùn, ìjọba Agbègbè Àríwá ṣẹ ìfilọ́lẹ̀ ètò ìgbésáfẹ́fẹ́ tẹlifísàn rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu láti gbé ètò ẹ̀kọ́ láàrín àṣẹ rẹ̀ ga. Wọ́n fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọdún 1962, orúkọ tí a fún ètò tẹlifísàn ni "Radio Television Kaduna". Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà, gbogbo àwọn ètò tẹlifísàn agbègbè meta dúró pẹ̀lú àwọn ibi-àfẹdé wọn ṣùgbọ́n ní ẹ̀yìn àwọn ọdún, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti ṣe ìṣòwò níkẹ̀hín-ìn. Ìgbóhùngbáwòrán sáfẹ́fẹ́ tẹlifísàn ní Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpìlẹ́sẹ̀ ti Alákoso agbègbè ìwọ̀-oòrùn (Western Region) àkọ́kọ́, Olóyè Ọbafẹ́mi Awólówọ̀ tí ní ọjọ́ kọkàn-lé-lọ́gbọ̀n oṣù kẹ́wàá, ọdún 1959 ló ṣe ìgbékalẹ̀ ìgbóhùngbáwòrán sáfẹ́fẹ́ tẹlifísàn ní ìlú Ìbàdàn, tí ó jẹ́ olú agbègbè náà nígbà náà. Pẹ̀lú atagba ọgọ́run márùn-ún wáátì kékeré tí a gbé sórí òkè Mapo nígbà náà, àti omìíràn ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ British Media, 'Overseas Rediffusion Limited '. A tún ṣẹ̀dá 'Western Nigeria Radiovision Service Limited ' pẹ̀lú òjúṣe láti ṣàkoso ìgbóhùngbáwòrán sáfẹ́fẹ́ rédíò àti tẹlifísàn ní agbègbè àwọn ìwọ̀-oòrùn. Nígbà náà a dá ilé-iṣẹ́ tẹlifísàn náà láti tan ìsọfúnni kálẹ̀ àti láti fi dá àwọn òǹwòrán lárayá.


Àwọn Ìtọ́ka Sí

Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

YerevanNew ZealandÁfríkàDesmond TutuJosephine BakerFátímọ̀ ọmọ MùhammédùTúrkìEhoroBósníà àti HẹrjẹgòfínàWallis and FutunaSingidaPópù Jòhánù 4kÀsà ilà kíkọ ní ilé YorùbáBoris JohnsonLinuxIlà kíkọ nílẹ̀ YorùbáSonyÀṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ Yorùbá2001Anna NetrebkoCreative CommonsOṣù KàrúnSally FieldIlẹ̀ọba Aṣọ̀kanDọ́là Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkàWalter ScheelẸ̀sìn IslamAlbáníàHTMLPópù Fransisi 1kOklahomaUSATheodosius 1kMilton FriedmanOhun ìgboroKùránìPeléKelly RowlandOṣéáníàOrílẹ̀-èdè olómìniraFriedrich EngelsToke MakinwaLiza MinnelliGeorges CharpakSt. George's, Grẹ̀nádàÌbálòpọ̀John IsnerJoseph StalinIPhoneTokyoArkansasMàkáùÌwà ÀjẹbánuTokelauKareem Abdul-JabbarKìnìúnPierre NkurunzizaBobriskyBọ́ọ̀lù-alápẹ̀rẹ̀Viktor OrbánValéry Giscard d'EstaingṢìkágòManhattanIndiana PacersVáclav HavelÀwọn BàhámàChinaza UchenduGeorge MarshallẸgbẹ́ Dẹmọkrátíkì (USA)Àkójọ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn agbègbè lóde wọn gẹ́gẹ́ bíi ìpapọ̀ ìtóbiTbilisi🡆 More