Naira Marley tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gangan ń jẹ́ Azeez Fáṣọlá, tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù karùn-ún ọdún 1994 (9th May 1994) jẹ́ gbajúmọ̀ olórin àti oǹpilẹ̀kọ̀wé-orin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Òun ní Ààrẹ ẹgbẹ́ olólùfẹ́ àgàbàgebè rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní "Marlians".
Naira Marley | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Azeez Fashola 9 Oṣù Kàrún 1994 Agege, Lagos State, Nigeria |
Iṣẹ́ |
|
Musical career | |
Irú orin |
|
Instruments | Vocals |
Years active | 2014–present |
Labels | Marlian Records |
Associated acts |
|
Wọ́n bí Naira Marley ní ìlú Agége ní Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Nígbà tí ó wà lọ́mọdún mọ́kànlá ní o dèrò ìlú òyìnbó, ní Peckam, lápá gúúsù London, lórílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Porlock Hall kí ó tó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Walworth School, níbi tí ó ti gbàwé ẹ̀rí General Certificate of Secondary Education. Naira Marley kàwé gbàwé ẹ̀rí tí ó ga jùlọ nínú ìmọ̀ okoòwò ní ilé-ẹ̀kọ́ Harris Academy ní ìlú Peckam Peckham. Ó tún kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ òfin okoòwò ní ilé-ẹ̀kọ́ giga Crossways College tí wọ́n ń pè ní Christ the King Sixth Form College .
Ọdún | Àmìn-ẹ̀yẹ | Abala | Olùgbàmìn ẹ̀yẹ | Àbájáde | Ìtọ́kasí |
---|---|---|---|---|---|
2020 | Soundcity MVP Awards | Ààyò àwọn olùwòran | "Soapy" | Gbàá | |
Orin tó dára jù lọ́dún | Wọ́n pèé | ||||
Orin tàkasúfèé tó dára jù | Naira Marley | Wọ́n pèé | |||
2019 | City People Music Awards | Olórin-kùnrin tó dára jù lọ́dún náà | Wọ́n pèé | ||
Orin àdúgbò tó dára jù | "Soapy" | Wọ́n pèé |
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Naira Marley, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.