Taiwo Olayemi Elufioye jẹ́ onímọ̀ ògùn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ó si ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ pẹ̀lú ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Ibadan. Ó jẹ́ ìkan láàrin àwọn onímọ̀ ni ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of the Sciences ní Philadelphia.
Taiwo Olayemi Elufioye | |
---|---|
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ilé-ẹ̀kọ́ | University of Ibadan |
Àwọn ẹ̀bùn àyẹ́sí | Elsevier Foundation Awards for Early Career Women Scientists in the Developing World |
Ó gbà owó ńlá láti ọ̀dọ̀ MacArthur Foundation láti lè ṣe oríṣiríṣi àyẹ̀wò lórí àwọn òun ọ̀gbìn tí ó wà ní Nàìjíríà tí ó lè ṣe ìwòsàn fún àwọn àrùn. Ní ọdún 2014, òun pẹ̀lú àwọn obìnrin mẹ́rin jọ gba àmì ẹ̀yẹ Early Career Women Scientist in the Developing World láti ọ̀dọ̀ Elsevier Foundation Awards.
Elufioye gba owó lọ́wọ́ MacArthur Foundation láti ṣiṣẹ́ ìwádìí lórí oríṣiríṣi egbò-igi orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, láti lè ṣàyẹ̀wò àrùn kan, àti láti wá ojútùú si.
NÍ ọdún 2014, Elufioye jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin tí wọ́n gba àmì-ẹ̀yẹ ti Elsevier Foundation Awards for Early Career Women Scientists in the Developing World. Elufioye gba àmì-ẹ̀yẹ fún iṣẹ́ rẹ̀ lórí iṣẹ́ ìwòsàn àwọn egbò-igi ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ dálé lórí àwọn ohun tí wọ́n le fi ṣe ìwòsàn fún àìsàn màléríà, egbò, oyèrírá, ẹ̀tẹ̀ àti àrùn jẹjẹrẹ. Àmì-ẹ̀yẹ ti Elsevier Foundation ni wọ́n fún Yaiwo ní ayẹyẹ American Association for the Advancement of Science (AAAS), lásìkò ìpàdé ọdọọdún wọn ní Chicago, ó sì tún gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbùn àti $5000. Nígbà tó gba àmì-ẹ̀yẹ náà, igbákejì Ààrẹ ti Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, Isaac Adewole, sọ pé àṣeyọrí Elufioye máa jẹ́ ìwúrí fún àwọn obìnrin mìíràn nínú iṣẹ́ sáyẹ́ǹsì, àti pé ó jẹ́ ẹni ẹ̀yẹ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní ilẹ̀ adúláwọ̀ lápaapọ̀.
Wọ́n ti ṣàtẹ̀jáde Elufioye ní African Journal of Biomedical Research, Pharmacognosy Research, the International Journal of Pharmaceutics, àti African Journal of Traditional, Complementary and Alternative Medicines.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Taiwo Olayemi Elufioye, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.