Osita Iheme, MFR tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù kejì ọdún 1982 (February 20, 1982) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí "Pawpaw" látàrí ipa tó kó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn Pawpaw nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń Aki na Ukwa pẹ̀lú Chinedu Ikedieze. Òun ni olùdásílẹ̀ Inspired Movement Africa, èyí tí ó dá sílẹ̀ láti ṣe móríyá fún àwọn màjèsín àti ọ̀dọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Áfíríkà lápapọ̀.
Osita Iheme MFR | |
---|---|
Iheme at the 2014 Africa Magic Viewers Choice Awards | |
Ọjọ́ìbí | Oṣù Kejì 20, 1982 Mbaitoli, Imo, Nigeria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Ẹ̀kọ́ | ìjìnlẹ̀ kọ̀m̀pútà,Lagos State University |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Lagos State University |
Iṣẹ́ | Actor |
Lọ́dún 1988, Iheme gba àmì ẹ̀yẹ Lifetime Achievement Award, èyí tí African Movie Academy Awards fún un. Wọ́n kà á sí ọ̀kan nínú àwọn òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó gbajúmọ̀ jùlọ.
Lọ́dún 2011, ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan fún un ní àmì ìdálọ́lá ọmọ ẹgbẹ́ ọlọ́lá Order of the Federal Republic (MFR).
Ó jẹ́ ọmọ bíbí Mbaitoli ní ìpínlẹ̀ Ímò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n ìpínlẹ̀ Abia ló gbé dàgbà, ó sìn kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírì nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kọ̀m̀pútà ní ifáfitì Lagos State University.
|
|
|
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Osita Iheme, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.