Ata rodo (Látìnì: Capsicum chinense) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ewébẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì nínú ohun èlò ìsebẹ̀ jákè-jádò orílẹ̀ àgbáyé.
Oríṣiríṣi ata rodo ni ó wà ní wà pàá pàá jùlọ ní àwọn ọjà ilẹ̀ Nàìjíríà.
Ata rodo ni ó ní àwọn èròjà aṣara lóore Fítàmì bii : (C, A, B6 àti folate), ó tún ní èròjà (lycopeine àti capsaicin). Àwọn èròjà yí ni wọ́n wúlò fún mímu ìrora kúrò fúni, tí ó sì ma ń jẹ́ kí kẹ̀lẹ̀bẹ̀ ó dúrò ní ihò tàbí káà imú àti káà ọ̀fun. Ata rodo tun ń ṣèkúnlápá fún àwọn ọmọ ogun ara kí wọ́n lè lagbara si. Ti ta ata rodo ni ó tun ma ń jẹ́ kí ẹ̀fọ́rí oun kàtá ó fi àgbàọ́ ara sílẹ̀, kódà tó fi mọ́ àìsàn arọmọléegun, àti àwọn àìsàn mìíràn.
Ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ko fi bẹ́ẹ̀ sí ónjẹ kan tí a lè sè láì sí ata rodo.A lè lọ̀ọ́ mọ́ àwọn èròjà ọbẹ̀ tókù, a lè lọ̀ó lásán kí á fi ṣe kurumbúsú, a lè jẹ́ lásán a sì lè fi se ohun k lohun tó bá wùwá.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Ata rodo, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.