Ìṣèlú

Ìṣèlú tabi òṣèlú ni igbese bi awon idipo eniyan kan se n sepinnu.

Oro yi je mimulo si iwuwa ninu awon ìjọba abele.

Ìṣèlú
Òsèlú


ÌSÈLÚ NILE YORUBA

Ní àwùjọ Yorùbá, á ní àwọn ọ̀nà ìsèlú tiwa tí ó dá wa yàtọ̀ sí ẹ̀yà tàbí ìran mìíràn. Kí àwọn Òyìnbó tó dé ní àwa Yorùbá ti ni ètò ìsèlú tiwa tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀. Tí ó sì wà láàárin ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Yàtọ̀ sí tí àwọn ẹ̀yà bí i ti ìgbò tí ó jẹ́ wí pé àjọrò ni wọn n fi ìjọba tiwọn ṣe (acephalous) tàbí ti Hausa níbi tí àsẹ pípa wà lọ́wọ́ ẹnìkan (centralization).

Ètò òsèlú Yorùbá bẹ̀rẹ̀ láti inú ilé. Eyi si fi ipá tí àwọn òbí ń kò nínú ilé ṣe ìpìlẹ̀ ètò òsèlú wa. Yorùbá bọ̀ wọn ní, “ilé là á tí kó èsọ́ ròdé”. Baba tí ó jẹ́ olórí ilé ni ó jẹ́ olùdarí àkọ́kọ́ nínú ètò ìsèlú wa. Gbogbo ẹ̀kọ́ tó yẹ fún ọmọ láti inú ilé ni yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. Bí i àwọn ẹ̀kọ́ ọmọlúàbí. Tí èdèàiyèdè bá sẹlẹ̀ nínú ile, bàbá ni yóò kọ́kọ́ parí rẹ̀. tí kò bá rí i yanjú ni yóò tó gbé e lọ sí ọ̀dọ̀ mọ́gàjí agbo-ilé. Agbo-ilé ni ìdílé bíi mẹ́rin lọ sókè tó wà papọ̀ ni ojú kan náà. Wọn kó ilé wọn papọ̀ ní ààrin kan náà. Tí mógàjí bá mọ̀ ọ́n tì, ó di ọdọ olóyè àdúgbò. Olóyè yìí ni ó wà lórí àdúgbò. Àdúgbò ni àwọn agbo-ilé oríṣìíríṣìí tí ó wà papọ̀ ní ojúkan. A tún máa ń rí àwọn Baálè ìletò pàápàá tí wọ́n jẹ́ asojú fún ọba ìlú ní agbègbè wọn. Àwọn ni ọ̀pá ìsàkóso abúlé yìí wà ní ọwọ́ wọn. Ẹjọ́ tí wọn kò bá rí ojúùtú sí ni wọ́n máa ń gbé lọ sí ọdọ ọba ìlú. Ọba ni ó lágbára ju nínú àkàsọ̀ ìsàkóso ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn Yorùbá ka àwọn Ọba wọn sí òrìṣa Ìdí nìyí tí wọn fí máa ń sọ pé:

  • Igba Irúmọlẹ̀ ojùkòtúu
  • Igba Irúmọlẹ̀ ojùkòsì

Ọ̀kan tí ó lé nínú rẹ̀ tí ó fi jẹ́ òkànlénú tàbí ọ̀kàn-lé-ní-rinwó (401), àwọn ọba ni. Wọn a ní.

KÁBÌYÈSÍ ALÁṢẸ. ÈKEJÌ ÒRÌṢÀ

Ọba yìí ní àwọn ìjòyè tí wọn jọ ń ṣèlú. Ẹjọ́ tí ọba bá dá ni òpin. Ààfin ọba ni ilé ẹjọ́ tó ga jù. Ọba a máa dájọ́ ikú. Ọba si le è gbẹ́sẹ̀ lé ìyàwó tàbí ohun ìní ẹlòmíì. Wọ́n a ní: Ọba kì í mùjẹ̀ Ìyì ni ọba ń fi orí bíbẹ́ ṣe.

A rí àwọn olóyè bí ìwàrèfà, ní òyọ́ ni a ti ń pè wọ́n ní Ọ̀yọ́-mèsì. Ìjòyè mẹ́fà tàbí méje ni wọn. Àwọn ni afọbajẹ. A rí àwọn ìjòyè àdúgbò tàbí abúlé pàápàá tí ó máa ń bá ọba ṣe àpérò tàbí láti jábọ̀ ìlọsíwájú agbègbè wọn fún un.

A tún ń àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó ń dáàbò bo ọba àti ìlú. Àwọn ni wọn ń kojú ogun. Àwọn ni o n lọ gba isakọlẹ fọ́ba. A tún ní àwọn onífá, Babaláwo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ètò òsèlú wa tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ yìí ni ó mú kí ó sòro fún àwọn òyìnbọ́ láti gàba tààrà lórí wa (Indirect rule). Àwọn ọba àti ìjòyè wa náà ni wọn ń lò láti ṣèjọba lórí wa. Ó pẹ̀ díẹ̀ kí wọ́n tó rí wa wọ.


Tags:

Ìjọba

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

SARS-CoV-2FísíksìOsama bin LadenÌjọ KátólìkìÁsíàLeon CooperẸlẹ́sìn KrístìAl SharptonÈdè Rọ́síàDiocletianOgun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejìSáyẹ́nsì1363 HerbertaTessalonikaOwe YorubaIlẹ̀ọba Aṣọ̀kan Brítánì Olókìkí àti Írẹ́lándìṢìkágòGuayaquilÀàlàKrómíọ̀mùÌladò Panamá11 May1 NovemberBùrúndìEpisteli Jòhánù KejìAustralopithecinesMuscatỌ̀rọ̀ ìṣeAyéGani FawehinmiAbubakar Audu13 SeptemberÀwọn Ùsbẹ̀kMardy FishLimaLuxembourgHirohito1033 SimonaDomain Name SystemErékùṣù Brítánì OlókìkíOṣù Kínní 12Bíbélì Mímọ́MauritaniaEre idarayaÌjàmbá ìtúká ẹ̀búté Bèírùtù ọdún 2020Apple Inc.FránsìÀwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyànAmsterdamDiamond JacksonOṣù Kínní 10EarthKonrad AdenauerNapoleon 3kÒgbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀Àṣà YorùbáOnome ebiMàláwìNọ́mbà tóṣòroAntelientomon6 MarchFrançois AragoỌjọ́bọ̀Iṣẹ́ ọnà🡆 More