Àyàn

Ayan (Drummer)

Iṣẹ́ Àyàn

Iṣẹ́ ìlù lílú ni a n pe ni ìṣẹ́ àyàn, àwọn ti o n sẹ iṣẹ yii ni a n pe ni “Aláyàn tàbí ‘Àyàn’. Iṣe àtìrandíran ni èyi, nitori iṣẹ afilọmọlọwọ ni. Gbogbo ọmọ ti Onílù bá bí sí ìdi Àyàn Agalú ni o ni láti kọ ìlù lílù, paapaa akọbi onílù. Dandan ni ki àkọ́bí onílù kọ iṣẹ ìlù, ko si maa ṣe e nitori àwọn onìlu ko fẹ ki iṣẹ́ náà parun.

Yàtọ̀ si àwọn ti a bì ni ìdile onìlu tabi awọn o ọmọde ti a mu wọ agbo ifa, Ọbàtálá, Eégún tàbí Ṣàngó ti wọn si n ti pa bẹ́ẹ̀ mọ oriṣiiriṣii ìlù wọn a maa n rì awọn to ti ìdílé miíran wa láti kọ ìlù lìlú lọwọ awọn onìlu. Àwọn Yorùbá bọ wọn ni “àtọmọde dé ibi orò ń wò fínní-fínní, àtàgbà dé ibi orò ń wò ranran” Òwe yìi tọka si i pe ko si ohun ti a fi ọmọdé kọ ti a si dàgbà sínú rẹ̀ ti a ko ni le se dáadáa.

Láti kékeré làwọn Yorùbá ti n kọ orìṣiiriṣi ìlù lìlú. Nígba ti ọmọde ba ti to ọmọ ọdún mẹ́wàá sí méjìlá ni yóò ti máa bá baba rẹ ti o jẹ onílù lọ òde aré. Láti kékeré yìí wá ni yóò ti máa foju àti ọkàn si bi a ti n lu ìlù. Àwọn ọmọdékùnrin tí ń bẹ nínú agbo àwọn tí ń bọ̀ Ọbàtálá yóò máa fojú síi bi a ti ń lu ìgbìn, àwọn tí n bẹ lágbo àwọn onífá yóò máa kọ bi a ti ńlu Ìpèsè. Ọ̀nà kan náà yii làwọn tí ń bẹ lágbo àwọn Eléégún àti onísàngó ń gbà kọ́ bi a ti ńlu Bàtá. Àwọn ọmọdé mìíran máa ń gbé tó ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀dógún lẹ́nu iṣẹ́ ìlù kíkọ́ yìí.

Tags:

Ayan (Drummer)

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

.suISO/IEEE 11073MaxiCodeOduwacoinÀṣàISO/IEC 8859-16Mons pubisỌbàtáláISO 259ISO 3166-3Abẹ́òkútaISO 9529C++LjubljanaISO/IEC 8859.niTripolitáníàISO 11170ECMAScriptMultibusISO 14644-8.rsGadoliniumISO 7002ISO/IEC 8859-15ISO 11992ISO 233ISO 10303ÀlgéríàIsaac Babalola AkinyeleNọ́rwèyISO 15189ISO/IEC 8859-8Ikot EkpeneNashvilleISO 3977ISO 14644-3ISO 2709ISO 25178Whirlpool (cryptography)ISO/IEC 27001Òrò àyálò YorùbáISO 15926 WIPMáìlì.hrIṣẹ́ Àgbẹ̀ ní NàìjíríàRafael UrdanetaISO 10303-21GánàIslàmabad.ecISO 13407ISO 10006Adeniran Ogunsanya College of EducationFrederik Willem de KlerkISO 19092-1Àmì ọ̀pá àṣẹ ilẹ̀ PuntlandBaghdadIṣẹ́ ọnàISO 10962Èdè JapaníHTMLOpenDocumentEzra OlubiTwitterISO 3166NàìjíríàÌtànShoe sizeBurkina Faso🡆 More