Pornhub

Pornhub jẹ́ ìtàkùn orí ẹ̀rọ-ayélujára fún fọ́nrán ìwòkuwò lóríṣiríṣi, èyí tó jẹ́ tí ìlú Canada.

Ọkàn lára àwọn ìtàkùn ayélujára náà tó gbajúmọ̀ ni ti eré-ìdárayá àwọn àgbàlagbà, ti Aylo. Títí di Oṣù Kejìlá 2023, Pornhub jẹ́ ìtàkùn ayélujára ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá tí àwọn ènìyàn ń wò jù lọ ní àgbáyé. Òun sì ni ẹlẹ́ẹ̀kejì tí àwọn àgbàlagbà máa ń wò jù lọ, lẹ́yìn XVideos. Ìtakùn yìí gba àwọn àlejò láàyè láti wo fọ́nrán ìwòkuwò lóríṣiríṣi láti oríṣiríṣi ìpele. Ó sì tún gbani láàyè láti fi fọ́nrán tirẹ̀ sí orí ìtakùn náà, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti bá òfin wọn mu. Wọ́n sì tún máa ń ṣe ìgbà àmì-ẹ̀yẹ lọ́dọọdún. Ní oṣù kejìlá, ọdún 2020, lẹ́yìn tí The New York Times tú àṣírí àwọn kan tí wọ́n ń nípìn-ín nínú ìfipábánilò àti ìṣenibáṣubàṣu, àwọn ẹ̀rọ ìsanwó bíi Mastercard àti Visa yọ ọwọ́ wọn kúrò nínú gbogbo nǹkan tó jẹ́ ti Pornhub. Èyí sì mú kí Pornhub yọ àwọn fọ́nrán tí ò bá òfin wọn mu, èyí sì mú kí àwọn fọ́nrán náà díkù láti mílíọ̀nù mẹ́tàlá (13 million) wọ mílíọ̀nù mẹ́rin (4 million). Ètò kan ní ọdún 2023, tí wọ́n pè ní Money Shot: The Pornhub Story, ṣàfihàn ìdojúkọ wọn àti àríwísí àwọn tó ń ṣe àwọn fọ́nrán ìwòkuwò yìí.

Pornhub
Pornhub-logo.svg
RegistrationOptional
Available language(s)English, German, French, Spanish, Italian, Portuguese, Polish, Russian, Japanese, Dutch, Czech, Simplified Chinese
Current statusOnline

Ìtàn

Wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ Pornhub ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún, ọdún 2007, láti ọwọ́ Matt Keezer, gẹ́gẹ́ bíi ìtàkùn ayélujára láàrin ilé-iṣẹ́ Interhub. Ní oṣù kẹta ọdún 2010, Fabian Thylmann ra ilé-iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bíi àfikún sí Manwin conglomerate (tí ó ti wá di Aylo báyìí). Ní ọdún 2013, Thylmann ta ìpín rẹ̀ fún Feras Antoon àti David Tassillo, tó ṣiṣẹ́ títí wọ ọdún 2022, gẹ́gẹ́ bíi CEO àti COO.

Látàrí ìgbìyànjú láti ṣe ìdásílẹ̀ fọ́nrán tó pé dáadáa, ilé-iṣẹ́ náà ṣe ìdásílẹ̀ ètò kan tí wọ́n pè ní "Pornhub Select" ní oṣù kẹwàá ọdún 2013. Pornhub tún ṣe ìdásílẹ̀ ètò kan ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹwàá ọdún 2013, tí wọ́n pè ní "PornIQ", èyí tó ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti ṣàtòjọ oríṣiríṣi fọ́nrán fún àwọn òǹwòran ní ìbámu pẹ̀lú àwọn fọ́nrán tí wọ́n ti wò sẹ́yìn àti àsìkò tí wọ́n ń wo àwọn fọ́nrán náà.

Ní ọdún 2009, ìtàkùn ayélujára ti àwọn fọ́nrán ìwòkuwò mẹ́ta tó tóbi jù lọ, ìyẹn RedTube, YouPorn àti Pornhub ní tó àlejò mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún (100 million).

Ní oṣù kẹfà ọdún 2015, Pornhub ṣe ìkéde pé wọ́n máa ṣàgbéjáde fíìmù àgbéléwò tó dá lórí ìwòkuwò tí wọ́n sì máa pè ní Sexplorations. Èròǹgbà wọn ni láti bẹ̀rẹ̀ ìyafọ́nrán fíìmù náà ní ọdún 2016, tí wọ́n sì máa gbọ́ gbogbo owó tí wọ́n nílò, àmọ́ wọ́n máa tọrọ $3.4 million láti ọwọ́ IndieGogo crowdfunders. Tí wọ́n bá rí owó náà gbà, fíìmù náà máa jáde ní ọdún 2016.

Ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì ọdún 2016, Pornhub ṣe ìdásílẹ̀ ètò onítẹ́tẹ́ lórí ẹ̀rọ-ayélujára èyí tí Betsoft, Endorphina àti 1x2 gaming jẹ́ onígbọ̀ọ́wọ́ rẹ̀. Ní oṣù kẹwàá ọdún 2017, igbá kejì Ààrẹ, ìyẹn Corey Price ṣe ìkéde pé Pornhub máa lo ìmọ̀-ẹ̀rọ láti ṣàwárí fọ́nrán lórí ẹ̀rọ náà tí ó sì máa fúnni ní ìròyìn nípa fọ́nrán àti àwọn ọ̀ṣèré inú fọ́nrán náà.

Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2018, ìtàkùn Pornhub bẹ̀rẹ̀ sí ní gba crypto currency gẹ́gẹ́ bíi ọkàn lára àwọn ọ̀nà láti san owó.

Ní oṣù kejìlá ọdún 2020, lẹ́yìn ìròyìn kan ní The New York Times láti ọwọ́ Nicholas Kristof mú kí Mastercard àti Visa yọ Ọwọ́ wọn cut their services to Pornhub. Pornhub then removed all videos by unverified users.

Àwọn ìtọ́kasí

Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Clarion ChukwuraAgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ MatazuÒrìṣà EgúngúnÌjẹ̀bú-ÒdeÀwọn ọmọ Áfíríkà Amẹ́ríkàBọ́lá ÌgèISO 15686Alice BradyISO/IEC 7816AbrahamuChristiane Chabi-KaoTivISBNBordeaux.niISO/IEC 2022ISO 217ISO 31-0Rosa LuxemburgAtlantaOṣù KọkànláISO 31-5Isaac Babalola AkinyeleÀjọ Ìlera ÀgbáyéJean-Jacques RousseauÌgbéyàwóXHTMLG8United Nations Development ProgrammeT.kpÀsìá ilẹ̀ SingaporeOÀwọn Ìdíje Òlímpíkì Ìgbà Oru 2024ÌbàdànPetra Cetkovská18 JuneÀwọn Òpó Márùún ÌmàleISOAgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ EwekoroISO/IEC 27000-series.mwJazzISO/IEC 18014GuernseyOnitshaISO 1413ISO 31-13Jean Baptiste PerrinLISO 26000ISO/IEC 8859-6Fidio ereVladimir PutinWhirlpool (cryptography)Ìlu FrankfọrtìÀrokòISO 31-2Bimbo AdemoyeISO 128Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́Mons pubis🡆 More