Gentille Assih

Gentille Menguizani Assih (tí wọ́n bí ní 2 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 1979) jẹ́ olùdarí eré àti agbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Tógò.

Gentille Assih
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹrin 2, 1979 (1979-04-02) (ọmọ ọdún 45)
Kpalimé
Orílẹ̀-èdèTogolese
Iṣẹ́Film director, film producer
Ìgbà iṣẹ́2004-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

Wọ́n bí Assih ní ìlú Kpalimé, orílẹ̀-èdè Tógò ní ọdún 1979. Ó fẹ́ràn ṣíṣe iṣẹ́ sinimá láti ìgbà kékeré rẹ̀. Ní ọdún 2001, ó kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ kọ̀mpútà àti fọ́tòyíyà. Ní ọdún 2006, Assih tún kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn-eré kíkọ ní orílẹ̀-èdè Sẹ̀nẹ̀gàl. Nígbà yìí kan náà ni ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga African Institute of Commercial Studies Ní ọdún 2009, Assih gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ ìṣàkóso àwọn òṣìṣẹ́.

Assih ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ kan tó n rísí bíbáraẹnisọ̀rọ̀ fún ọdún méjì ṣáájú kí ó tó dá ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀ tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní “World Films”. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi olùdarí eré ní ọdún 2004 pẹ̀lú ṣíṣe àwọn fíìmù oníṣókí kan tí àkọ́lé wọ́n jẹ́ Le prix du velo àti La vendeuse contaminee. Ní ọdún 2008, ó ṣe adarí eré Itchombi.

Ní ọdún tí ó tẹ̀le, Assih ṣe adarí àti agbéréjáde fún fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Bidenam, l’espoir d’un village ní ìlú Johannesburg, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹgbẹ́ Goethe Institute. Fíìmù náà dá lóri ayé Bidenam, ẹnití ó padà sí abúlé rẹ̀ lẹ́hìn ọdún mẹ́fà tí ó ti wà láárè, tó sì pinnu láti kọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣe ètò ọ̀gbìn ní ìlànà ìbomirin. Àbúrò rẹ̀ obìnrin tí ó lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀-èdè Mòrókò ni ó mú àbá ìtàn eré náà wá. Ní ọdún 2012, Assih ṣe adarí eré ìrírí gígùn kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Le Rite, la Folle et moi.

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

  • 2004: Le prix du velo
  • 2004: La vendeuse contaminee
  • 2008: Itchombi
  • 2009: Bidenam, l’espoir d’un village
  • 2012: Le Rite, la Folle et moi

Àwọn ìtọ́kasí

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

Tags:

Gentille Assih Ìsẹ̀mí rẹ̀Gentille Assih Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀Gentille Assih Àwọn ìtọ́kasíGentille Assih Àwọn ìtakùn ÌjásódeGentille AssihTógò

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Wasiu Alabi PasumaIgbeyawo IpaOrílẹ̀ èdè AmericaÀjọ àwọn Orílẹ̀-èdèÌjàmbá ìtúká ẹ̀búté Bèírùtù ọdún 2020IPv6Sheik Muyideen Àjàní BelloEthiopiaÌpínlẹ̀ ÒgùnÌran YorùbáAfghanístànISBNXÀàrẹ ilẹ̀ Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkàFilipínìÀjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní ilẹ̀ Nàìjíríà28 JuneẸ̀lẹ́ktrọ́nùÀwòrán kíkùnBobriskyOṣù KẹtaNew YorkÀsà Ìgbéyàwó ní ilè YorùbáGbólóhùn YorùbáFísíksìJapanFrancisco León FrancoOrílẹ̀Pierre NkurunzizaR. KellyRichard NixonÒrùnEuropeOduduwaAWẸ̀bùn Nobel nínú Lítíréṣọ̀LọndọnuÈdè Gẹ̀ẹ́sì1490 LimpopoẸ̀sìnJack LemmonLebanonÀmìọ̀rọ̀ QROlódùmarèWeb browserWikimediaDiamond JacksonẸranko afọmúbọ́mọỌbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀Onome ebi🡆 More