Eyín jẹ́ ẹ̀yà ara kan tí ó le koko tí kìí rọ̀ tí ó ma ń hù jáde láti inú erìgì nínú ẹnu tí a ma ń lò láti jẹun tàbí fọ́ egungun.
Gbogbo eranko tí ó ní egungun lẹ́yìn tí wọ́n sì ma ń rún ónjẹ lẹ́nu ni wọ́n ma ní eyín. Nígbà tí pupọ̀ nínú wọn ma ń fi eyin ṣọdẹ tàbí dáàbò bo ara wọn lọwọ́ ewu. Àwọn onímọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé eyín kìí ṣe egungun rárá bí ó ti wulẹ̀ kí ó mọ, amọ́ eyín jẹ́ àkójọ pọ̀ àwọn tíṣù kan tí wọ́n ń pè ní ectoderm ni wọ́n para pọ̀ di eyín.
Irisi eyin ni ara gbogbo eranko elegungun ma n jora won, bi o tile je wipe iyato ma n wa nibi tito jo won.Eyin gbogbo awon eranko elegungun saba ma n fese mule sinsin, bakan naa ni o ma n ri lara awon eja ati awon ooni. Amo, lara awon eja kan ti won n pe ni teleost ita egungun enu won ni eyin won ma n hu si, lara awon alangba inu apa kan ori egungun enu won ni eyin won ma wa.
Lara awon eja oni kerekere bi eja saaki, eyin won sopo mo ligaments ti o nipon to si sopo mo kerekere arungbon won.
Híhù eyín láàrín àwọn ẹranko elégungun ma ń sábà jẹ́ bá ká ń náà, àmọ́ ìyàtọ̀ ma ń wà láàrín ipò àti bí wọ́n ṣe ń hù láàrín ẹranko sí ẹranko. Kìí ṣe àwọn ẹranko nikan ni ó ma ń hu eyín, àwọn ẹja àti ẹran inú omi náà ma ń hu eyín. . Eyín kìí sábà hu nínú ẹnu nikan gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ́yà ẹranko kan ṣe ma hu ti wọn. Híhù eyín láàrín àwọn ẹja sábà ma ń wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹnu wọn, nígbà tí ti àwọn kan so mọ́ ẹ̀gbẹ́ erìgì wọn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Eyín, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.