Blanche Bilongo (tí a bí ní 26 Oṣù Kínní, Ọdún 1974) jẹ́ òṣèrébìnrin, ònkọ̀tàn, àti olóòtú ọmọ orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù.
Blanche Bilongo | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oṣù Kínní 26, 1974 Monatélé |
Orílẹ̀-èdè | Cameroonian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Yaoundé II |
Iṣẹ́ | Actress, screenwriter, presenter, film editor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2000-present |
Bilongo wá láti agbègbè-ààrin ti orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù. Ó lọ sí ilé-ìwé Johnson College ní ìlú Yaoundé níbi tí ó ti ṣe àwọn eré ijó. Ní ọdún 1987, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ sí àwọn àtúnyẹ̀wò ẹgbẹ́ ìṣeré orí ìtàgé ti André Bang tí wọ́n pe orúkọ wọn ní Les Pagayeurs. Níbè ló ti há àwọn ọ̀rọ̀ tó wà fún akópa olú-ẹ̀dá-ìtàn sórí. Ní ọjọ́ kan tí wọ́n ṣàfẹ́rí akópa olú-ẹ̀dá-ìtàn náà, Bilongo rọ́pò rẹ̀ láti kó ipa náà, èyí tí ó fun ní ànfàní láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà.
Bilongo kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu fíìmù Tiga, L'Héritage ní ọdún 2000. Ní ọdún 2005, Bilongo kópa gẹ́gẹ́ bi Sabine nínu eré tẹlifíṣònù N'taphil. Bákan náà ní ọdún 2007, ó kópa gẹ́gẹ́ bi Pam nínu eré Hélène Patricia Ebah kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Blessures Inguérissables. Ó di olóòtú fún ìkànnì tẹlifíṣọ̀nù CRTV ní ọdún 2009.
Ní ọdún 2019, Bilongo ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ orin àdákọ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ n jẹ́ "Le temps de Dieu". Ó kọ orin náà ní èdè Beti fún ìyá rẹ̀ tí ó ti di olóògbé. Ní ọdún 2020, ó kópa gẹ́gẹ́ bi Marie Young nínu eré aláwàdà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Coup de Foudre à Yaoundé.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Blanche Bilongo, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.