Aisha Yusufu (tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejìlá ọdún 1973 ní Ipinle Kano) jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ ọ́ ọmọ ènìyàn, ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti alábàṣiṣẹ́pọ̀ ẹgbẹ́ tí ó ń polongo fún ìdápadà àwọn ọmọ obìnrin wa (Bring Back Our Girls Movement), èyí tí í ṣe ẹgbẹ́ alágbàwí tí ó ń pe Ìjọba sí àkíyèsi lórí í àwọn ọmọbìnrin tí ó lé ní igba láti ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdìrì ti Chibok ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí àwọn ẹgbẹ́ oníjàgídíjàgan Boko Haram jí gbé ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹrin ọdún 2014.
Yesufu wà lára àwọn obìnrin tí wọ́n ń fi ẹ̀rónú hàn ní ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èyí tí ó wà ní Abuja, Olú-ìlú Nàìjíríà, ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹrin, ọdún 2014.
Aisha Yesufu | |
---|---|
Aisha Yesufu leading the EndSARS Protest in Abuja, on October 10, 2020. | |
Ọjọ́ìbí | Aisha Yesufu Oṣù Kejìlá 12, 1973 Kano State |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Bayero University Kano |
Iṣẹ́ | Socio-political activist, microbiologist, businesswoman |
Gbajúmọ̀ fún | Bring Back Our Girls, End SARS |
Àwọn ọmọ | 2 |
Yesufu tún wà lára àwọn tí ó léwájú nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń pè fún fífòpin sí SARS (END SARS), èyí tí ó ń pe àkíyèsi si àṣejù tí ẹ̀yà kan nínú iṣé ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ń pè ní Special Anti Robery Squad (SARS) ń ṣe. Yesufu sọ wípé òun kò ní fi ìjà kíkéde ìfòpin sí àwọn ọlọ́pàá SARS ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sílẹ̀ fún àwọn ọmọ òun.
Ipinle Kano, níbi tí wọ́n bí Yesufu sí ná à ni wọ́n tí tọ ọ dàgbà. Yesufu ní ìrírí lórí i ìṣòro tí ó wà nínú n kí ènìyàn jẹ́ ọmọbìnrin ní àyíká tí kò fibẹ́rẹ̀ sí ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ tí ó sọ, ó wípé "Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, ń kò ní àwọn ọmọbìnrin kankan ní ọ̀rẹ́ nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n ti gbé níyàwó, ṣùgbọ́n nítorí mo fẹ́ ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo ṣe kúrò ní agbègbè tí kò lajú." Aisha Yusufu tún sọ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ọmọ tí àwọn ẹlẹgbẹ́ òun bí ti fẹ́rẹ̀ tún má a bí ọmọ nígbàtí òun ṣe ìgbéyàwó ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún.
Yesufu àti ọkọ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aliu, ẹni tí ó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú rẹ ní ọdún 1966, ni wọ́n bí ọmọ méjì tí orúkọ wọn ń jẹ́ Amir àti Aliyah.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Aisha Yesufu, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.