Ẹ̀sìn Búddà

BUDDHISM (Ẹ̀SÌN BUDDA)

ÌBÍ BUDDA

Ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀ fi han wí pé a bi Budda si ìdílé Ọba ni Orílé-èdè “Lumbini, Nepal ní Teria” lẹba “Himalayas”. Nítorí náà, àwọn àwòràwọ̀ wí pé ní ìlú “Kalinga” èyí tí o ti di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ ní ìlú “India” ni a gbé bí i.

O jẹ́ ọmọ ẹbí “Sakays”. Orùkọ bàbá rẹ ni “Suddhodana”. A bí Budda nínú ìdílé Ọba. Orúkọ ìyá rẹ ni “Maya”.

Kò si ẹni ti o mọ àkọsílẹ̀ ọjọ́ ibi rẹ̀ pàtó tàbí ti o ni àkọsílẹ̀ rẹ̀. Olúkúlùkù kan ńsọ àwọn ọjọ́ ti wọn rò pe o le jẹ́ ni nítorí kò si àkọsílẹ̀ kan pàtó ti a le tọka sí. Àwọn oǹpìtàn kan ní a bi i ni ọdun “623 tàbí 624 BCE”. Kò pé kò jiìnà yíì ni àwọn ẹlésìn kan sọ wí pé ọjọ ibii rẹ̀ títí di ọjọ́ ti o gbé lórí eèpẹ̀ jé ni aarin ọdún 567 si 487 BCE” .

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n wí pé a bí ì ni Ọdún 420 sí 502 BCE” ki a ma fi ọ̀pá pọ̀lọ̀pọlọ pa ejò, kò sí ìdánilójú ọjọ́ ibii rẹ̀ àti ọjọ́ ti ó lò láyé.

Àwọn ohun ti a ri nínú àkọsílẹ̀ ti o ṣe pàtàkì ni pé a bi i ni ọ̀nà ìyanu. Lẹ́hìn ìbí rẹ̀, o dìde dúró ó gbé àwọn ìgbésè nínú èyí tí o kede ara rẹ̀ wí pé òun yoo jẹ́ ìjòyè ayé. O wí pé èyí ni yoo jẹ́ ìgbà ti òun yoo padà wá sáyé gbẹ̀hìn.

Orúkọ ti àwọn obi rẹ́ sọ o ni “Siddhartha Gautama”. “Siddhartha” . Eyi túmọ̀ sí “ẹni ti o ti kẹ́sẹ járí ṣùgbọ́n “Gautama” ni orúkọ ìdílé tí a bí i si. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọn má n pe e ni “Sakayamuni”, itumọ̀ èyí tí ń jẹ́ amòye nínú “Sakyas”.

ÌBÈRÈ PẸ̀PẸ̀ AYÉ RẸ̀

“Sakyamuni” jẹ́ ẹni ti a tọ́ lọ́nà ẹ̀sìn “Hindu”, èrò àwọn òbí rẹ̀ ni ki o jẹ́ arópò Bàbá rẹ̀ lẹ́hìn ìgbà tí ó bá gbẹ́sẹ̀. Wọ́n ro wí pé yoo lánfààní lati jẹ́ ìlù mọọ́ká Ọba tàbí olórí ẹ̀sìn ńlá kan ti o se jìnmọ̀wò. Àwọn òbí rẹ̀ tọ́ọ ni ọna ọlá àti ọlà kí ohun ti o wá se l’áyé lé rọrùn fún-un àti ki o le gbé ìgbé ayé ẹ̀sìn wọn.

Ní ìgbà tí o di ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni o gbé ìyàwó, orúkọ́ ìyàwó rẹ̀ a má jẹ́ “Yasodhara”, Nígbà tí o pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ́n ni ìyàwó rẹ̀ bi ọmọ ọkùnrin kan fún-un orúkọ rẹ̀ a ma jẹ́ “Rahula”. Lẹ́hìn tí o bi ọmọ yii tán ìtàn fi ye wa wí pé o se ìrìnàjò lori ẹ̀sìn lẹ́ẹ̀mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ ìtàn sọ wí pé ń se ni o ri ìran lẹ́ẹ̀mẹ́rin. Nínú ìrìnàjò rẹ̀ àkókọ́ o ri ọkùnrin arúgbó kan ti o jẹ́ aláilòlùránlọ̀wọ́, ní ìrìnàjò rẹ kejì ó rí ọkùnrín ti àìsàn ti o lágbára juu lọ ń ba a fínra, ní ìrìn àjò rẹ kẹta o ri ìdílé kan ti ìbànújẹ́ bò mọ́lè ti wọn si ńgbé ọkàn nínú wọn ti o se aláìsí lọ si ibojì. Ó ronú jinlẹ̀ lórí ìsòro ti àwọn arúgbó n kójú bi àìsàn àti ikú.

Nínu ìrìn àjò rẹ̀ kẹrin, o ri ẹlésìn kan ti o pè sí ìrònú nípa ohun ti o rí nígbà yii ni ọ̀kan rẹ to rú sókè láti tẹ̀lé ọ̀nà àti le se ìrànlọ́wọ́ nípa ti ẹ̀mí papa fún ìsòro ti o n kojú ọmọ ènìyàn.

Ó fi aya, ọmọ àti ìgbé ayé ìrọ̀rùn àti ìgbá ayé asáajú àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lati se ìwadi ìyànjú ìsòro ẹ̀dá.

Ní àkókò nàá àwọn ọkùnrin miran a ma kúrò ni ilé lati lọ d’ánìkàn wà nínú igbó tàbí ibití o se kọ́lọ́fín nítorí wọn fẹ́ mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ kan.

WÍWÁ Ọ̀NÀ SI ÌSÒRO TI O N KO Ẹ̀DÁ LÓJÚ

O kọ́kọ́ gbìyànjú lati ronú ohun tí o kó lati ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́ rẹ méjì òtóotọ́, o rò wí pé èyí ni ó se iyebíye.

Ṣùgbọ́n ìrònú yii kò le tẹ̀síwájú lọ títí nítorí náà o yípadà nínú ìrònú náà ki o le dojú kọ àwọn ìsoro náà tí ó ń fẹ́ yanjú èyí, ti o jẹmọ́ ìbímọ, àìsàn ọjọ́ ogbó àti ikú.

Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ti wọn jọ ni èrò kan lorí wíwà ọ̀nà si ìsòro tí o n dojúkọ ènìyàn, ní bẹ́ẹ̀ ni o ti kọ onírúrú ohun bi ki a sé èémi àti bi a ti gba àwẹ̀ léraléra.

Àwọn ohun ti o gbékalẹ̀ fún ara rẹ yìí jẹ́ ohun ti o nira lópọ̀lọpọ̀ nítorí náà o fi sílẹ̀ lai tún tèsíwájú nípa rẹ mọ́, àwọn ti o se fífi íyá jẹ ara ẹni gbíga àwẹ̀ tàbi sìn rẹ̀ “Hendu” kò si ọ̀nà àbáyọ si ìsòro ti o ńfẹ́ ìyanjú nítorí náà o tún pinnu láti se àwárí ọ̀nà míràn láti le tú àwọn ènìyàn sílẹ̀ nínú ìsòro ti o ń dojú kọ wọ́n.

ÀWỌN ÌFOYÈHÀN BUDDA

Ni àsálẹ́ ọjọ́ kan ni “535 BCE” ni ìgbà tí o pé ọmọ ọdún márùndínlógòji O joko lábẹ́ igi ńla kan ti a mọ̀ si igi Bódì. O bẹ̀rẹ̀ si ni ri ìrírí nípa àseyọrí t’ẹ̀mí.

(1)Ní alẹ́ àkókó o rántí ìgbé ayé kí a kú ni ibikan ki a si tún wà ni ibòmíràn gẹ́gẹ́ bi alààyè.

(2)Ni ale ọjị keji o ri bi igbe aye ibi ati ika ti ọpọlọpọ̀ ma n gbe se ma n so ibiti wọn yóò lọ lẹhin iku.

(3)Ni alé ọjọ kẹta o kọ́ wí pé oun ti tèsíwájú kọja ipele biba ẹmi jẹ́ nipa ikorira, ibinu, ongbe, ibẹru àti ijaya o si pinnu wí pé oun ko tún ni wá s’áyé mọ́. O ti ni ifoyehan o si di “Olugbala, enito n gbani àti Olùràpadà”

Lẹ́hìn ìfoyèhàn rẹ̀ yi o gbìyànjú láti jẹ́ ki ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ nípa pipolongo ẹ̀kó rẹ̀ si wọ́n èyí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ si gbàgbọ́ ti wọn si ń tẹlẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Tags:

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

OwóAyéBòlífíàArméníàPDF/AMuhammad ibn Mūsā al-KhwārizmīÀgùàlàISO 3166-1Sáyẹ́nsìRománíàFúnmiláyọ̀ Ransome-Kútì27 AugustMardy FishAudio Video InterleaveLuxembourgNicosiaDar es SalaamNeanderthalJide KosokoMassKọ́ngrẹ́ẹ̀sì Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkàÈrànRichard NixonÀwọn Ìdíje Òlímpíkì Ìgbà Oru 1936Ìṣọ̀kan ÁfríkàÈdè LátìnìÌbínibíÒgún LákáayéUlf von Euler6 MarchAddis Ababa1 AugustÀsìá ilẹ̀ AustríàC24 DecemberÙsbẹ̀kìstánAISO 4217Gaza StripElisabeti Kejì10 AugustInternet Relay ChatÀtòjọ àwọn Ààrẹ ilẹ̀ RùwándàISO 316625 MarchWọlé SóyinkáIlẹ̀ọba Aṣọ̀kanṢìkágòZanzibarBùrúndì9 FebruaryYunifásítì ìlú OxfordAli NuhuOsama bin LadenMadridCôte d'IvoireÀàlàSteve JobsÀwọn Ùsbẹ̀kLuther VandrossAma Ata AidooÈdè FaranséIbi Ọ̀ṣọ́ ÀgbáyéDomain Name System🡆 More