Àwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá

Orin jẹ́ àṣà pàtàkì nínú àṣà Yorùbá.

Oríṣiríṣi orin ni àwọn Yorùbá máa ń kọ fún oríṣiríṣi nǹkan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀. Yòóbá a máa kọrin kẹ́dùn, wọn á máa kọrin ṣayẹyẹ, wọ́n máa ń kọrin ṣe ìkìlọ̀, bẹ́ẹ̀ wọ́n sìn máa ń kọrin bú ènìyàn. Yorùbá a máa forin rẹ ọmọ lẹ́kún, wọn á máa forin ki oríkì ẹni, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Orin nínú ọdún ìbílẹ̀

Èrò àti ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa àjọ̀dún ìbílẹ̀

Àjọ̀dún ìbílẹ̀ jẹ́ mọ́ bíbọ òrìṣà kan tí àwọn olùsìn rẹ̀ fi ń wájú mọ́ra tàbí láti fi bẹ̀bẹ̀ tàbí san ẹ̀jẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí wà fún ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àjọ̀dún ìbílẹ̀ tún lè wà fún ìrántí aṣááju tàbí akọni kan, bóyá tí ó tẹ ìlú kan dó, tàbí tí ó jagun kan láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tá tàbí lọ́wọ́ ibi tàbí ìjàǹbá kan, tàbí tí ó ṣe ohun mánigbàgbé kan tí wọn fi ń ránti rẹ̀ tàbí tí wọ́n fi ń ṣọpẹ́ fún un, tí wọ́n sì tí ipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di òrìṣà tí wọn yóò máa bọ, tí wọn yóò sì máa ṣe ẹ̀yẹ fún lọ́dọọdún tàbí lóòrèkóòrè. ...

Agbalogbabo lori orin Yoruba

Iwulo orin Yoruba

Orin Yoruba

Àgbálọgbábọ̀ lori orin

Ìwúlò orin Yorùbá

Orin jẹ ọ̀nà kan pàtàkì tí ẹní tí ó kọrín fí ń gbé èrè-ọkàn rẹ̀ jáde lórí ohun tí ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, yálà nípa ọ̀rọ̀ ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn tàbí nípa ọ̀rọ̀ kan láwùjọ.

Ọ̀kọrin lè fi orin mú iwúrí àti ìdùnu bá ara rẹ̀ tàbí ẹlòmìíràn. Gẹ́gẹ́ bí alóre láwùjọ, ọ̀kọrin tàbí òṣèré lè fi orin gbé ẹ̀dùn ọkàn èrò àwùjọ síta, èyí tí ìba máa fún ni ni ìnira tàbí ìtẹ̀mọ́lẹ̀ tàbí ìbánujẹ́ abẹ́nu, yálà láti ọwọ́ ìjọba tàbí àwọn aláṣẹ kan. Orin lè wá fún lílò ara-ẹni tàbí tí àwùjọ lápapọ̀. Orin lè mú ní sapá ṣe ohun tí ó dàbí ẹní ṣòroó ṣe fún ní nígbà mìíràn. ...

Orin apala

Apala

Orin Àpàlà

Ìfáàrà

Orin àpàlà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin Yorùbá ti wọ́n jẹ́ gbájúmọ̀ ni agbègbè ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Ọ̀yọ̀, Ọ̀sun àti Ìgbóminà. Orin ayẹyẹ ni orin àpàlà, orin ìgbàlóde ni pẹ̀lú. Orin àpàlà kò ní nǹkan án se pẹ̀lú ẹ̀sìn, òrìsà tàbí ìbọ kan tí a mọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá. Orin ìgbàfẹ́ ni orin àpàlà....

Orin Fújì

Ìfáàrà

Orin ìgbàlódé ni orin Fújì. Orin tó gbalágboko ni pẹ̀lú. Àwọn ohun díẹ̀ péréte ni a ó ṣọ̀rọ̀ lé lorí nínú orin yìí. A ó fi ẹnu ba ohun èlò orin Fújì, àwọn ọ̀kọrin Fújì ìṣàkóso àti kókó tí Fújì ń dálé lórí. ...

Orin Sákárà

Ìfáàrà

Ẹ̀dá ìtàn méjì ní a gbọ́ tí ó rọ̀ mọ́ bí eré Sákárà ṣe bẹ̀rẹ̀. Ọkan ní pé ni ìlú Ìlọrin ní Sákárà tí bẹ̀rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn Mùsúlùmí kan, kí a to mú un wá sí Ìbàdàn lásìkò Baálẹ̀ Sítú tí ó jẹ́ Olúbàdàn láàrin ọdún 1914 sí 1925. Ẹ̀dà ìtàn kejì ní pé eré kerekérè ni ó pilẹ̀ eré Sakárà láti ọwọ́ Abúdù, tí ó jẹ́ ọmọ Yorùbá kan tí ó ń ṣe àtìpó ní ìlú Bídàá ní ìpínlẹ̀ Náíjà. ...

Orin Àgan

Àwọn orin kán wà ni ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ń kù lọ. Wọ́n ti fi ìgbà kan kári ilẹ̀ Yorùbá rí. Ní àsìkò yìí ìlú kọ̀ọ̀kan ní a ti ń rí wọn. Wọn ò tilẹ̀ kárí ẹkù kan mọ́. Irúfẹ́ àwọn orin náà fara pẹ́ òrìṣà kan pàtó. Ìlú tí ẹ̀sìn òkèrè bá ti gba ẹ̀ṣìn ìbílẹ̀ lọ́wọ́ wọn, dandan ni kí irú orin bẹ́ẹ̀ kú pẹ̀lú ẹ̀sìn tí wọ́n gbé jù sílẹ̀....

Orin Wéré

Ìfáàrà

Ìtara àti ìtaníjí nínú ẹ̀sìn Mùsùlùmí ni a gbọ́ pé ìpilẹ̀ṣẹ̀ eré ajíwéré, nígbà tí àwọn olúfọkànsìn kan máa ń lọ káàkiri àdúgbò ní ìdájí láti jí àwọn Mùsúlùmí lati kírun àárọ̀. Èyí ni aáyan láti má jẹ́ kí àwọn ènìyàn sùn gbàgbera, kí wọn sì jí wéré láti ṣàdúrà òórọ̀....

Orin Jùjú

Àwọn ohun èlò eré Jùjú

Nígbà ti eré Jùjú bẹ̀rẹ̀, àwọn ohun èlò tí àwọn òṣèré n lò ni: báńjò, ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, samba àti ‘jùjú’ (àsìkò). Nígbà tí wọn kò lo gìtá alápòótí mọ ní wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí lo báńjò. Àwọn ohun-èlò ìbílẹ́ tí wọ́n tún mú wọ inú eré Jùjú ni gágan, sákárà tàbí orùn ìṣà, gudugudu, agogo, àgídigbo tàbí móló. Àwọn ohun-èlò ìgbàlódé tí a mú wọ́nú eré Jùjú ní gìtá, ọ̀pọ̀ ìlú alásopọ̀ tí ẹnìkanṣoṣo máa ń lù, bóńgò, kóńgà, ẹ̀rọ gbohùngbohùn, míkísà, búsítà, àkọ́díọ̀nù àti dùùrù àfẹnufọn, nígbà kan rí. ...


Orin nínú ọdún ìbílẹ̀

Èrò àti ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa àjọ̀dún ìbílẹ̀

Àjọ̀dún ìbílẹ̀ jẹ́ mọ́ bíbọ òrìṣà kan tí àwọn olùsìn rẹ̀ fi ń wájú mọ́ra tàbí láti fi bẹ̀bẹ̀ tàbí san ẹ̀jẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí wà fún ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àjọ̀dún ìbílẹ̀ tún lè wà fún ìrántí aṣááju tàbí akọni kan, bóyá tí ó tẹ ìlú kan dó, tàbí tí ó jagun kan láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tá tàbí lọ́wọ́ ibi tàbí ìjàǹbá kan, tàbí tí ó ṣe ohun mánigbàgbé kan tí wọn fi ń ránti rẹ̀ tàbí tí wọ́n fi ń ṣọpẹ́ fún un, tí wọ́n sì tí ipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di òrìṣà tí wọn yóò máa bọ, tí wọn yóò sì máa ṣe ẹ̀yẹ fún lọ́dọọdún tàbí lóòrèkóòrè. ...

Iwe ti a yewo

Àwọn Ìtọ́kasí

Tags:

Àwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin nínú ọdún ìbílẹ̀Àwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Èrò àti ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa àjọ̀dún ìbílẹ̀Àwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Àgbálọgbábọ̀ lori orinÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Ìwúlò orin YorùbáÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin ÀpàlàÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin FújìÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin SákáràÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin ÀganÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin WéréÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin JùjúÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Àwọn ohun èlò eré JùjúÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Orin nínú ọdún ìbílẹ̀Àwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Èrò àti ìgbàgbọ́ Yorùbá nípa àjọ̀dún ìbílẹ̀Àwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Iwe ti a yewoÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá Àwọn Ìtọ́kasíÀwọn Orin Ilẹ̀ Yorùbá

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Apá MonoISO 2GoogleAnastasio BustamanteMandraka DamMose BìlísìLimaLionel JospinEwìÌdíje Wimbledon 1977 − Àwọn Obìnrin ẸnìkanÌdílé AugustaÀsìá ilẹ̀ Bẹ̀rmúdà2 DecemberCorine OnyangoGómìnà8 DecemberIyipada oju-ọjọ ni South AfricaÌpínlẹ̀ Ọ̀yọ́Okey BakassiCarl Johan Thyselius29 JuneFernando SerranoOnome ebiMenachem BeginFile Transfer ProtocolRafael NúñezRuth NeggaMoses Bliss (akọrin)WikiNumerian13 OctoberJuan Esteban PederneraÀwọn èdè Índíà-EuropeKentuckyIlẹ̀ọba Aṣọ̀kanTsung-Dao LeeInternetLAkanlo-edeAdolf HitlerAisha AbdulraheemJames IrwinEre idarayaJapanGbenga AdefayeISO 3166-1Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ní àwọn Erékùṣù KánárìLẹ́tà gbẹ̀fẹ̀Odò DánúbìSanusi Lamido SanusiLoquatEmperor JunnaÀrokòEpisteli Kejì sí àwọn ará Kọ́ríntìÀwọn Erékùṣù ChathamOwe YorubaLahoreRwandaÌwé Àṣẹ Aṣàlàyé Ọ̀fẹ́ GNURobert S. MullikenEuroEsther Onyenezide10 August3471 AmelinVieno Johannes SukselainenDọ́là àwọn Erékùṣù KáímànJim Courier🡆 More