AṢA OGE ṢÍṢE NÍ ILẸ YORÙBÁ
Oge ṣíṣe jẹ́ ọ̀kan nínú àsà ilè Yorùbá tí ó níse pẹ̀lú bí a tí se ń tún ara wà se àti bí a se mú ẹwà ara wà jáde.
Àì mò ànfàní àti iyì tí o wà níbi oge ṣíṣe àti ṣíṣe ẹwà ní Ilè Yorùbá ni ìsọ̀rí ohun ti àwa ọ̀dọ́ ìwòyí ko fi pàtàkì OGE ṢÍṢE.
Ní ayé òde òní tí a bá rí ẹni tí o kò ilà, àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn akẹgbẹ́ re yíò máà fi se yẹ̀yẹ́ nítorí pé wón ri ilà kíkó gẹ́gẹ́bí ohun ayé àtíjó tí kò ye kí a máà rí ni òde òní mò, tàbí tí àbá rí ẹni tí o wo agbádá, dànsíkí, bùbá, ìró àti bùbá tàbí ẹni tí o se àwọn irun bíì ìpàkọ́ ẹlẹ́dẹ̀, kọjúsọ́kọ kẹ̀yìnsálẹ̀, wón a máà wo wón bí ẹni tí kò rí ookan, béè àwọn ohun tí o n bú ẹwà kún àsà àti isé ilè Yorùbá.
Àwọn ti a le lo láti fi se oge
a) Làálì Lílé: Àsà làálì lílé jẹ́ ohun tí àwọn Yorùbá kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Haúsá, nítorípé àwọ̀n ní wón máà le làálì láti ìbèrè pẹ̀pẹ̀. A ní ewé igi tí a mò sí ewé laali, a máà ń kún ewé yíì , ao fi káún si, ao si fisí ibi tí a bá fe le làálì náà si ní ara wa.
b) Tìro Lílé: Tìro nínú tún jẹ́ ohun tí o se pàtàkì nínú ìsaralóge ilè Yorùbá, yàtọ̀ si wípẹ́ a máà n fi tìro se oge, tìro tún dára fún ojú wà, a máà kò ìdọ̀tí kúrò nínú ojú, a si máà jẹ́ kí ojú rína kedere. Àti okùnrin, àti obìnrin ní o lé le tìro sùgbón obìnrin ní ó pọ̀jù nínú àwọn tí o máà le tìro.
d) Ilà Kíkọ: Ilà kíkọ jẹ́ ònà tí àwọn Yorùbá fi ń se oge ní ayé àtíjó, àwọn bàbáńlá wa a máà ko ilà fún ọmọ láti bù ẹwà kún ojú ọmọ náà, wón a sí tún máà ko ilà fún ọmọ láti fi se ìpín láàrin ọmọ wón àti ọmọ èlòmíràn paapaa jùlọ láàrin ẹ̀yà kan sí ìkejì, oríṣiríṣi ilà kíkọ ní o wa, ẹ̀yà oríṣiríṣi sí ni o ní bí wón tí se n ko ilà tiwon, tófi jẹ́ wípẹ́ tí àwọn ènìyàn bá tí rí ilà yi lójú ènìyàn kan, wón tí mò ibi tí ẹni náà tí wá.
e) Etí Lílu: Etí lílu láti fi se oge jẹ́ ohun tí àwọn obìnrin nìkan gbudọ̀ máà se tí okùnrin kòsì gbọdọ̀ kópa nípe, Àwọn obìnrin máà n lu eti won lati fi yeri eti sí, yẹrí etí ti a fi orisirisi iyun ati ilẹ̀kẹ̀ se, tí yíò si máà múwon rẹwà si.
ẹ)Irun dídì: Oríṣiríṣi ara ní àwọn obìnrin Yorùbá máà ń fi irun dá, wón a máà se irun orí wón láti fi se oge, ní ìgbà míràn, wón a máà fi ilẹ̀kẹ̀ si láti gbẹ́ ẹwà wón yo dáradára.
f) Irun Fífá: Nígbàtí àwọn obìnrin bá ń di irun wón, àwọn okùnrin náà a máà fà orí wón, ònà tí o bá wùwón ní wón fi le fà, tí yíò si máà gbẹ́ ẹwà tiwon máà yo gẹ́gẹ́bí okùnrin. Àyàfi àwọn tí a mò sí Ìlárì ọba, tí wón máà n fi díè le nínú orí wón láti fi hàn pé ìlárì niwon.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article Àsà oge ṣíṣẹ́ ní ilè yorùbá, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.