Àdàkọ:Ọdún 2022, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọjọ́ Sátidé nínú kalẹ́ndà Gregori, ọdún 2022 ni ó ṣáájú ọdun 2023, òun sì ni ó ló tẹ̀lé ọdún 2021.
•Ọjọ́ ìkejì oṣù kíní (January 2): Abdalla Hamdok kọ̀wé iṣẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mínísítà àgbà fún orílẹ̀-èdè Sudan lẹ́yìn ìwọ́de ńlá.
•Ní ọjó keje oṣù Kínní (January 7): Iye àwọn tí ó ti ní àrùn covid-19 kojá ọ̀ọ́dúnrúnr mílíọ́nù.
•Ní ọjọ́ kẹwá oṣù Kínní (January 10): Fún ìgbà àkókò, àwọn Dókítá rí Ọkàn Ẹlẹ́dẹ̀ gbé sínú ènìyàn, ó sì yè. Eléyìí ṣẹlẹ̀ ní Baltimore, Maryland ni orílè-èdè Amerika.
•Ní ọjọ́ kẹtalélógún oṣù kínní (January 23): wọ́n fipá ggbàjọba lọ́wọ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Bùrkínà Fasò Roch Kaboré, wọ́n sọ wípé ìdí tí àwọn fi gba ìjọba náà ni bí ààrẹ náà ṣe kùnà láti panọ́ làásìgbò kọ̀ọ̀kan tí àwọn igun ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí kan ń dá sílẹ̀ wà lára ìdí tí wọ́n fi yọ ọ́ kúrò nìpò.
•Ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kíní (Jan 28): Iye abẹ́rẹ́ àjẹsára àrùn covid-19 tí àwọn ènìyàn ti lò lágbàáyé ti lé ní bílíọ́nù mẹ́wá .
•Ní ọjọ́ kọkandínlọ́gbọ̀n oṣù kínní (Jan 29): Wọ́n dìbò yan ààrẹ orílẹ̀-èdèItaly, Sergio Mattarela fún sáà kejì ìjọba.
•Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì (26 Feb): Orílẹ̀-èdè Rọ́síà bẹ̀rẹ̀ sí ń kógun ja orílẹ̀-èdè Ukraine.
•Ní ọjọ́ keje oṣù kẹta (March 7): Iye àwọn tí o ti kú nítorí aàrùn Covid-19 lé ni mílíọ́nù mẹ́fà (6 million).
•Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin (April 13): Iye àwon ti o ti ní aàrùn covid-19 lé ni Ẹẹdẹgbẹta millionu.
•Ní ọjọ́ l3rìndínlógún oṣù kẹrin(April 24): Apá kejì ìdìbò orílè-èdè Faransé bẹ̀rẹ̀, ààrẹ Emmanuel Macron sì jáwé olúborí láti ṣe sáà kejì tí olùdíje kejì, Marine Le Pen sì fìdí èémí .
•Ní ọjọ́ kẹfà oṣù karùn ún (6 May): Àjakálẹ̀ aàrùn Monkey Pox gbòde: Aàrùn Monkey Pox nẹ̀rẹ̀ sí ń tàn kálẹ̀, ijọ́ tí wọ́n sì rí ẹni àkọ́kọ́ tí ó ní àrùn yí ní ìlú London, orílè-èdè United Kingdom.
•Ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù karùn ún (9 May): Mínísítà àgbà orílẹ̀-èdè Sri Lanka, Mahinda Rajapaksa kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ìwọ́de lòdì sí àkóso rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mínísítà Ranil Wickremesinghe ṣe bọ́ sí ipò náà lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí Mahinda kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀.
• Ojó keedogun osù karun(May 15): A yan Ààre orílè-èdè Somalia télèrí, Hassan Sheikh Mohamud fún sáà kejì ìjoba rè, ààre Mohamed Abdullahi Mohamed sì fìdíremi.
• Ojo karun ti osù kefa(June 5): Okere jù eyan adota kú sí didun adá oloro to selè ní ìlú Owo, ipinle Ondo, Nàìjirià.
• Ojo kejo osù keje(July 8): Agbenipa kan yin Minisita àgbà orílè-èdè Japan teleri Shinzo Abe pa nígbà ti óun soro si àwon èro ní ìlú Nara.
• Ijó kokanlelogun ti osù Keje(July 21): Àwon asofin orílè-èdè Sri Lanki yan Minisita Àgbà Ranil Wickremesinghe gegebi Ààre orílè-èdè náà léyìn ìgbà tí ààre orílè-èdè náà tele, Gotabaya Rajapaksa kòwé fise sílè tori iwode ifehonuhan ti àwon ará ìlú un se to ri bi nkan se le koko.
• Ijo kerin ti osù Kejo(August 4): Minisita àgbà fún orílè-èdè Peru, eni tí a un pè ní Anibal Torres kòwé fise sílè léyìn òpòlopò iwádí nípa iwa odaran tí wón se nípa Ààre orílè-èdè Peru, eni tí a un pè Pedro Castillo.
• Ijo kesan ti osù Kejo(August 9):
° Idibo gbogboogbo ti orílè-èdè Papa New Guinea: Àwon asofin Papa New Guinea yan James Marape gégé bi asofin agba orílè-èdè Papa New Guinea.
°Idibo gbogboogbo ti orílè-èdè Kenya: A yan William Ruto gégé bi Ààre orílè-èdè Kenya, oun ni ààre karun orílè-èdè Kenya. O fi ídí olùtakò rè, Ralia Odinga remi.
• Ijó kerinla osù Kejo(August 12): Afunrasi odaran kan, tí àún pe ní Hadi Matar gún Salmon Rushdie lobe ní òpòlopò ibi, Salmon Rushdie jé olùkòwé omo orílè-èdè Amerika mó United Kingdom tí a bi ní Orílè-èdè India, wón gbé afunrasi náà, ogbeni Hadi Matar lo ilé-ejó ní ojó kejì.
• Ojó ketadinlogbon ti osù kejo si ojó kokanla ti osù kesan(August 27-Sept 11): Won gbá copu Asia odun 2022 ní orílè-èdè United Arab Emirates, orílè-èdè Sri Lanka ló jáwé olúborí.
• Ojó karun ti osù kesan(Sept 6): A yan Liz Truss gégé bi minisita àgbà fún orílè-èdè United Kingdom.
• Ojo kejo ti osu Kesan(Sept 8) – Charles keta di oba United Kingdom àti orílè-èdè merinla mirán léyìn ìgbà tí Ayaba Elisabeti keji kú.
• Ojo Kerinla si kerindinlogun osu kesan(September 14–16) – Ija wáyé Kyrgyzstan ati Tajikistan lori oro àlà, òpòlopò àwon omo ogun Kyrgyz ati Tajik ni oba isele náà lo.
° Àwon agbebon pa ènìyàn marun ní ìlú Rogoji, Bakura ní ìpínlè Zamfara. Iroyin gbe pé ìyá kan ti àwon vigilante pa omo refers níbí ní kí awon agbebon náà se nkan ti wón se.
° Àwon olè agbebon kan se ìkolù sí moto tó ún gbodo kan, won pa ènìyàn mefa, olopa meji wà lara awon ti wón pa.
* Ojó kejidinlogbon ti osù keta(March 28): Àwon agbebon se ìkolù si oko oju irin kan ti óún lo láti Abuja sí Kaduna.
Àṣekágbá ìdíje ife ẹ̀yẹ agbáyé náà wáyé ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kejìlá ọdún 2022 yí kan náà.
This article uses material from the Wikipedia Yorùbá article 2022, which is released under the Creative Commons Attribution-ShareAlike 3.0 license ("CC BY-SA 3.0"); additional terms may apply (view authors). Gbogbo ohun inú ibí yìí wà lábẹ́ CC BY-SA 4.0 àyàfi tí a bá sọ pé kò rí bẹ̀ẹ̀. Images, videos and audio are available under their respective licenses.
®Wikipedia is a registered trademark of the Wiki Foundation, Inc. Wiki Yorùbá (DUHOCTRUNGQUOC.VN) is an independent company and has no affiliation with Wiki Foundation.