Tẹlifóònù

Tẹlifóònù ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀-jíjìnnà kan tó úngba àwọn olùṣeúnkan méjì tàbí púpọ̀ ní àyè láti sọ̀rọ̀ sí ara wọn tààrà nígbà tí wọ́n bá jìnnà sí ara wọn.

Tẹlifóònù únsiṣẹ́ nípa yíyí ohùn, àgàgà ohùn ènìyàn, sí àwọn àmì ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ-oníná tí wọ́n ṣe é gbé pẹ̀lú wáyà, àti àwọn ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ míràn, lọ sí orí tẹlifóònù míràn tí yíò ṣe àtúngbéjáde ohùn náà fún ẹni tó úngbọ́ọ nìbòmíràn. Ìtumọ̀ tẹlifóònù jáde láti Gíríkì: τῆλε (tẹli, ọ̀ọ́kán) àti φωνή (fóònù, ohùn), lápapọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí ohùn ọ̀ọ́kán (distant voice). A tún le pèé lásán ní fóònù.

Tẹlifóònù
Ẹ̀rọ tẹlifóònù

Ní ọdún 1876, Alexander Graham Bell ló kọ́kọ́ gba ìwé àṣẹ ìdọ́gbọ́n ní Amẹ́ríkà fún ẹ̀rọ kan tó gbé ohùn ènìyàn jáde kedere. Ẹ̀rọ yìí gba àtúnṣe lọ́wọ́ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn míràn, nítorí bẹ́ẹ̀ ó di ohun ìlò dandan fún ìkòwò, ìjọba, àti àwọn agbolé.

Ẹ̀rọ tẹlifóònù ní gbohùngbohùn kan (ẹ̀rọ ìfiránṣẹ́', transmitter) láti fi sọ̀rọ̀ àti ẹ̀rọ ìgbọ́ràn (ẹ̀rọ olùgbà, receiver) láti fi gbé ohùn jáde. Bákannáà, tẹlifóònù tún ní ago tó ún polongo ìpè tẹlifóònù tó únbọ̀, ó tún ní ẹ̀rọ ayíwọ́ tàbí bọ́tìnì láti fi tẹ nọ́mbà tẹlifóònù fún ìpè tẹlifóònù míràn. Ẹ̀rọ ìgbọ́ràn àti ẹ̀rọ ìfiránṣẹ́ wà papọ̀ nínú tẹlifóònù kannáà tí a gbé sí etí àti ẹnu nígbà tí a bá ún sọ̀rọ̀. Ẹ̀rọ ìfiránṣẹ́ ún yí ohùn sí àmi ẹ̀rọ-oníná tó únjẹ́ fífi ránṣẹ́ látorí ìsopọ̀mọ́ra tẹlifóònù sí tẹlifóònù tó úngba ìpè, níbi tó ti únyí àmì náà sí ohùn tó ṣe é gbọ́ létí pẹ̀lu ẹ̀rọ ìgbọ́ràn tàbí nígbà míràn pẹ̀lú ẹ̀rọ asọ̀rọ̀pariwo. Àwọn tẹlifóònù jẹ́ àwọn ẹ̀rọ duplex, tó túmọ́si pé wọ́n ún gba ìgbéránṣẹ́ lọ àti bọ̀ ní ẹ̀kannáà.

Àwọn ìtọ́kasí

Tags:

TelecommunicationÈdè Gíríkì

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

8 DecemberKárbọ̀nùOgun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejìEmilio EstradaRamesses 7kOmiCreative CommonsÌjọba àìlólóríCorine OnyangoMoses Bliss (akọrin)WikimediaEsther Oluremi ObasanjoÀjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ní ilẹ̀ Nàìjíríà27 JuneAgbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ BarutenIyipada oju-ọjọ ni South AfricaÈdè Yorùbá9815 Mariakirch10650 HoutmanHeinrich RohrerDọ́là àwọn Erékùṣù Káímàn7 May29 JuneJapanFàájì FMEsther Onyenezide1126 OteroÁntígúàÌwé Hábákkúkù20 AprilTurkey67085 OppenheimerOrúkọ YorùbáRoque Sáenz PeñaFile Transfer ProtocolÌbálòpọ̀Marco PoloRafeal Pereira Da SilvaÌtàn ilẹ̀ Sẹ̀nẹ̀gàl2024Karl-August Fagerholm3016 MeuseMonicazation22 FebruaryTobias Michael Carel AsserMọ́rísì.рфItoro Umoh ColemanJuan Esteban PederneraLouis St. LaurentÀwọn orin ilẹ̀ YorùbáVladimir LeninÌdíje Wimbledon 1979 − Àwọn Obìnrin ẸnìkanChannels TVGbenga AdefayeSTS-95Cape TownÀwọn ará Jẹ́mánìMarcel ProustUrho KekkonenPaul Kehinde12766 Paschen.bbÀsìá ilẹ̀ Bárbádọ̀sAlfonso López Michelsen🡆 More