Èdè Lárúbáwá

Èdè Lárúbáwá tabi ede Araabu Ara èdè Sẹ̀mítíìkì ni èdè Àrábíìkì (Arabic (Èdè Lárúbááwá)).

Àwọn tí ó ń sọ ọ́ tó mílíọ̀nù lọ́nà igba gẹ́gẹ́ bí èdè abíníbí ní àríwá Aáfíríkà àti ìlà-oòrùn-gúsù Eésíà (Asia). Àìmoye ènìyàn tí a kò lè fi ojú da iye wọn ni ó ń sọ èdè yìí gẹ́gẹ́ bí èdè kejì, ìyẹn èdè àkọ́kún-tẹni ní pàtàkì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀sìn Mùsùlùmú ti gbilẹ̀. Àwọn tí ó lọ ṣe àtìpó ní pàtàkì ní ilẹ̀ faransé náà máa ń sọ èdè yìí. Ibi tí àwọn tí ó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí ju ni Algeria, Egypt, Iraq, Morocco, Saudi Arabia, Sudan, Syria, Tunisia àti Yeman. Àwọn ẹ̀ka-èdè rẹ kan wà tí ó jẹ́ ti apá ìwọ̀-oòrùn tí àwọn kan sì jẹ́ ti ìlà-oòrùn. Èdè tí a fi kọ kọ̀ráànù sílẹ̀ ni a ń pè ní ‘Classical’ tàbí ‘Literary Arabic’. Èdè mímọ́ ni gbogbo mùsùlùmú àgbáyé tí ó tó ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ní àgbáyé (1, 100 million) nínú ètò ìkànìyàn 1995 ni ó mọ èdè ‘Classical Arabic’ yìí. Olórí ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá wà tí ó sún mọ́ èyí tí wọ́n fi kọ Kọ̀ráànù. Eléyìí ni wọ́n fi ń kọ nǹkan sílẹ̀. Òun náà ni wọ́n sì máa ń lo dípò àwọn ẹ̀ka-èdè Lárúbáwá. Púpọ̀ nínú àwọn tí ó ń sọ ẹ̀ka-èdè lárúbáwá yìí ni wọ́n kò gbọ́ ara wọn ní àgbóyé. Méjìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn álúfábẹ́ẹ̀tì èdè Lárúbááwá. Apé ọ̀tún ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé wá sí apá òsù Yàtọ̀ sí álúfásẹ́ẹ̀tì ti Rómáànù, ti Lárúbáwá ni àwọn ènìyàn tún ń lò jù ní àgbáyé. A ti rí àpẹẹrẹ pé láti nǹkan bíi sẹ́ńtérì kẹ́ta ni a ti ń fi èdè Lárúbáwá kọ nǹkan sílẹ̀. Nígbà tí ẹ̀sìn mu`sùlùmí dé ní sẹ́ńtúrì kéje ni òkọsílẹ̀ èdè yìí wá gbájúgbajà. Wọ́n tún wá jí sí ètò ìkọsílè èdè yìí gan-an ní séńtúrì kọ́kàndínlógún nígbà tí ìkọsílẹ̀ èdè yìí ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará. Ìwọ̀-oòrùn Úróòpù. Ní pele-ń-pele ni èdè yìí pín sí (ìyẹn ni pé eléyìí tí olówó ń sọ lè yàtọ̀ sí ti tálíkà tàbí kí ó jẹ́ pé eléyìí tí obìnrin ń lò lè yàtọ̀ sí ti ọkùnrin).

Èdè Lárúbáwá
العربية al-ʿarabīyah
Èdè Lárúbáwá
Ìpè/alˌʕaraˈbiːja/
Sísọ níPrimarily in the Arab states of the Middle East and North Africa;
liturgical language of Islam.
Ìye àwọn afisọ̀rọ̀Approx. 280 million native speakers and 250 million non-native speakers
Èdè ìbátan
Afro-Asiatic
  • Semitic
    • West Semitic
      • Central Semitic
        • Arabic
          • Èdè Lárúbáwá
Sístẹ́mù ìkọArabic alphabet, Syriac alphabet (Garshuni), Bengali script [1] [2]
Lílò bíi oníbiṣẹ́
Èdè oníbiṣẹ́ níOfficial language of 25 countries, the third most after English and French
Àkóso lọ́wọ́Algeria: Supreme Council of the Arabic language in Algeria

Egypt: Academy of the Arabic Language in Cairo
Iraq: Iraqi Academy of Sciences
Jordan: Jordan Academy of Arabic
Libya: Academy of the Arabic Language in Jamahiriya
Morocco: Academy of the Arabic Language in Rabat
Sudan: Academy of the Arabic Language in Khartum
Syria: Arab Academy of Damascus (the oldest)

Tunisia: Beit Al-Hikma Foundation
Àwọn àmìọ̀rọ̀ èdè
ISO 639-1ar
ISO 639-2ara
ISO 639-3ara – Arabic (generic)
(see varieties of Arabic for the individual codes)
Èdè Lárúbáwá

Àwọn Ìtọ́kasí

Tags:

AlgeriaEgyptIraqMoroccoSaudi ArabiaSudanSyriaTunisiaÁsíà

🔥 Trending searches on Wiki Yorùbá:

Elizabeth AdekogbeOtukpoOdò ỌyaIrinNàúrùEbenezer ObeyLiverpoolISO 3166-1Èdè FaranséOṣù KàrúnHans FischerSístẹ́mù ajọfọ̀nàkò jẹ́ọ́gráfìSTS-1LaoziOwe YorubaHarriet TubmanRọ́síàMọ́remí ÁjàṣoroBáháráìnìMaryam YahayaUTCKoreaOhun ìgboro.auTaiwanÀsìá ilẹ̀ Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kanTokyoMọ́skò17928 NeuwirthÀwòrán kíkùnWikipẹ́díà l'édè YorùbáSíríàMùsùlùmíGuineaAkọ ibàỌ́ksíjìnKàlẹ́ndà GregoryPólándìCalabarEthiopiaNajib Tun RazakHendrik LorentzMùhọ́mádùBangladẹ́shìItan Ijapa ati AjaGámbíàPópù Fransisi 1kFọ́tòyíyàWarsawÈdè HíndìÈdè ṢáínàBob HawkeÀṣà YorùbáGerman languageÀjọ Ìlera ÀgbáyéAbdulsalami AbubakarEku EdeworOnímọ̀ ìsirò🡆 More